Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fìyà Jẹ Wá?
Lẹ́yìn tí ìmìtìtì ilẹ̀ tí ìwọ̀n rẹ̀ tó 9.0 àti àkúnya omi tó ń jẹ́ sùnámì wáyé lórílẹ̀-èdè Japan lóṣù March, ọdún 2011, ọmọ ilẹ̀ Japan kan tó jẹ́ òléwájú olóṣèlú sọ pé, “Èrò mi ni pé, ìyà látọwọ́ Ọlọ́run ni èyí, àmọ́, àánú àwọn tí àjálù náà dé bá ṣe mí gan-an ni.”
Nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Haiti ní January 2010 pa àwọn tó ju ọ̀kẹ́ mọ́kànlá [220,000], ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ oníwàásù orí tẹlifíṣọ̀n sọ pé àjálù yìí wáyé torí pé “àwọn èèyàn ti bá èṣù mulẹ̀” wọ́n sì ní láti “pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
Nígbà tí èèyàn mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79] kú nínú ìkọlùkọgbà tó wáyé nílùú Manila, lórílẹ̀-èdè Philippines, àlùfáà Kátólíìkì kan sọ pé “Ọlọ́run fẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn wa tó ti kú sọ jí ni.” Ìwé ìròyìn kan ní orílẹ̀-èdè náà sọ pé “ìdá mọ́kànlélógún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà ló gbà pé Ọlọ́run ló ń fi ìbínú rẹ̀ hàn tí ilẹ̀ fi ń lanu, tí ìjì líle fi ń jà, tí àwọn àjálù míì” sì ń wáyé léraléra ní orílẹ̀-èdè yìí.
ỌJỌ́ pẹ́ tí àwọn èèyàn ti gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa ń lo àjálù láti fìyà jẹ àwọn èèyàn búburú. Lọ́dún 1755, lẹ́yìn tí nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ta [60,000] kú nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀, iná àti sùnámì wáyé nílùú Lisbon, lórílẹ̀-èdè Portugal, ọ̀gbẹ́ni Voltaire tó jẹ́ gbajúmọ̀ onímọ̀ ọgbọ́n orí béèrè pé: “Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ìlú Lisbon pọ̀ ju ti ìlú Paris lọ ni, níbi tó jẹ́ pé ìbàjẹ́ ni wọ́n fi ń ṣayọ̀?” Àìmọye èèyàn ló ń ṣe kàyéfì pé, ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run máa ń lo àjálù láti fìyà jẹ àwọn èèyàn? Àmúwá Ọlọ́run ni wọ́n ń pe irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.
Lójú gbogbo ohun tá a ti ń sọ bọ̀ yìí, ó yẹ ká béèrè pé: Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run ń lo àwọn àjálù láti fi jẹ àwọn èèyàn níyà? Ṣé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àjálù tó wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí jẹ́ ìyà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?
Nígbà tí àwọn èèyàn bá ń dá Ọlọ́run lẹ́bi nítorí àjálù tó wáyé, wọ́n máa ń yára tọ́ka sí Bíbélì níbi tí Ọlọ́run ti fi àjálù pa àwọn èèyàn kan run. (Jẹ́nẹ́sísì 7:17-22; 18:20; 19:24, 25; Númérì 16:31-35) Àmọ́, àyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí fi hàn pé, àwọn nǹkan pàtàkì mẹ́ta tó ṣáájú àwọn àjálù náà mú kí wọ́n yàtọ̀. Ohun àkọ́kọ́ ni pé, ìkìlọ̀ wà ṣáájú kí àwọn àjálù náà tó wáyé. Ohun kejì ni pé, àwọn èèyàn búburú nìkan ni àwọn àjálù náà pa, kò dà bí àjálù tó ń wáyé lóde òní tó jẹ́ pé, èèyàn rere àti èèyàn búburú ló máa ń pa. Àwọn aṣebi tí kò yí pa dà tàbí àwọn tí kò gba ìkìlọ̀ nìkan ni wọ́n pa run. Ohun kẹta ni pe, Ọlọ́run ṣe ọ̀nà tí àwọn aláìmọwọ́ mẹsẹ̀ yóò gbà yè bọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 7:1, 23; 19:15-17; Númérì 16:23-27.
Kò sí ẹ̀rí pé Ọlọ́run ló fa àìmọye àjálù tó ti ṣe ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́ṣẹ́ lónìí. Nígbà náà, kí ló fà á tí irú àjálù bẹ́ẹ̀ fi ń pọ sí i? Báwo la ṣe lè fara dà wọ́n? Ǹjẹ́ àkókò kan ń bọ̀ nígbà tí kò ní sí àjálù mọ́? Wàá rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó kàn.