ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 May ojú ìwé 5
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Ìgbà Tí Ọrọ̀ Ajé Máa Dẹnu Kọlẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Ìgbà Tí Ọrọ̀ Ajé Máa Dẹnu Kọlẹ̀?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Múra Sílẹ̀ Ní Apá Ìgbẹ̀yìn “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” Yìí
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ fún Rògbòdìyàn Tó Lè Ṣẹlẹ̀?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 May ojú ìwé 5

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Ìgbà Tí Ọrọ̀ Ajé Máa Dẹnu Kọlẹ̀?

Kì í yà wá lẹ́nu nígbà táwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé bá mú kí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀. Kí nìdí? Torí pé apá tó gbẹ̀yìn nínú ètò àwọn nǹkan la wà báyìí, àti pé Bíbélì ti kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé “ọrọ̀ tí kò dáni lójú.” (1Ti 6:17; 2Ti 3:1) Kí la lè kọ́ lára Ọba Jèhóṣáfátì tá a bá fẹ́ múra sílẹ̀ de ìgbà tí ọrọ̀ ajé bá dẹnu kọlẹ̀?

Nígbà táwọn ọ̀tá ń halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run, Jèhóṣáfátì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (2Kr 20:9-12) Ó ṣètò láti dáàbò bo àwọn ìlú náà kí ogun tó bẹ̀rẹ̀, ó kọ́ àwọn odi ìlú, ó sì ṣètò àwọn ibùdó fáwọn ọmọ ogun. (2Kr 17:1, 2, 12, 13) Bíi ti Jèhóṣáfátì, ó yẹ káwa náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì ṣe àwọn nǹkan táá fi hàn pé a múra sílẹ̀ de àkókò tí nǹkan máa nira.

BÁWO LA ṢE LÈ MÚRA SÍLẸ̀ DE ÌGBÀ TÍ ỌRỌ̀ AJÉ MÁA DẸNU KỌLẸ̀?

Múra sílẹ̀ nípa tẹ̀mí: Jẹ́ kí ohun tó o ní tẹ́ ẹ lọ́rùn, kó o sì jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà máa pèsè ohun tó o nílò lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. (Mt 6:26; 1Ti 6:8) Pinnu pé o ò ní ṣe ohun tó máa ta ko àwọn ìlànà Bíbélì torí àtijẹ-àtimu. (Ro 2:21) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí iná tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ṣètò bí wàá ṣe máa ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì. Tọ́jú àwọn ìtẹ̀jáde díẹ̀ tá a tẹ̀ sórí ìwé, tàbí kó o wa àwọn ìtẹ̀jáde tá a máa lò lọ́jọ́ iwájú sórí fóònù rẹ.

Múra sílẹ̀ nípa tara: Máa ṣọ́wó ná, tó o bá sì jẹ gbèsè, tètè wá bó o ṣe máa san án kó tó di pé ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀. (Owe 22:7) Tó bá ṣeé ṣe, ra oúnjẹ àtàwọn ohun kòṣeémánìí míì pa mọ́. O sì tún lè gbin àwọn nǹkan tó ṣeé jẹ sí àyíká ilé rẹ, ìyẹn á jẹ́ kó o lè máa ṣọ́wó ná.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ṢÉ O TI MÚRA SÍLẸ̀ DE ÀJÁLÙ? KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Apá kan nínú fídíò “Ṣé O ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù?” Àwòrán Bíbélì, báàgì pàjáwìrì, fóònù àtàwọn tó ń kọ́lé wà níbẹ̀.
  • Kí la lè ṣe láti múra sílẹ̀ de àjálù?

Apá kan nínú fídíò “Ṣé O ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù?” Àwọn ará tó lọ ṣèrànwọ́ nígbà àjálù ń kọ́lé, wọ́n sì ń kẹ́rù jáde nínú ọkọ̀ akẹ́rù kan.
  • Báwo la ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́?

OHUN TÓ YẸ KÓ O ṢE

Nígbà ìjọsìn ìdílé yín, ẹ jíròrò ohun tó wà nínú Jí! No. 1 2022. Ẹ tún lè jíròrò àwọn ohun míì tẹ́ ẹ lè ṣe láti múra sílẹ̀ de àjálù.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́