ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w23 February ojú ìwé 14-19
  • “Ẹ Máa Ronú Bó Ṣe Tọ́, Ẹ Wà Lójúfò!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Máa Ronú Bó Ṣe Tọ́, Ẹ Wà Lójúfò!”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • MÁA ṢỌ́RA TÓ O BÁ Ń WO ÀWỌN NǸKAN TÓ Ń ṢẸLẸ̀ LÁYÉ
  • BÁWO LA ṢE LÈ MÁA KÍYÈ SÍ ARA WA?
  • MÁA LO ÀKÓKÒ Ẹ LỌ́NÀ TÓ DÁA JÙ LỌ
  • Kí Nìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Máa Ṣọ́nà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ẹ Wà Lójúfò Bíi Ti Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Fífojú Sọ́nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • ‘Ẹ Máa Ṣọ́nà’—Wákàtí Ìdájọ́ Ti dé!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
w23 February ojú ìwé 14-19

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 8

“Ẹ Máa Ronú Bó Ṣe Tọ́, Ẹ Wà Lójúfò!”

“Ẹ máa ronú bó ṣe tọ́, ẹ wà lójúfò!”​—1 PÉT. 5:8.

ORIN 144 Tẹjú Mọ́ Èrè Náà!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa

1. Kí ni Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nípa ìgbà tí òpin máa dé, ìkìlọ̀ wo ló sì fún wọn?

NÍ ỌJỌ́ díẹ̀ ṣáájú ikú Jésù, mẹ́rin lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bi í pé: ‘Kí ló máa jẹ́ àmì ìparí ètò àwọn nǹkan?’ (Mát. 24:3) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun táwọn ọmọlẹ́yìn yẹn ń béèrè ni báwọn ṣe máa mọ ìgbà tí Jerúsálẹ́mù máa pa run. Nígbà tí Jésù dá wọn lóhùn, kì í ṣe ìgbà tí Jerúsálẹ́mù máa pa run nìkan ló sọ, ó tún sọ̀rọ̀ nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan” tá à ń gbé báyìí. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí òpin máa dé, ó ní: “Ní ti ọjọ́ yẹn tàbí wákàtí yẹn, kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run àti Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àyàfi Baba.” Lẹ́yìn náà, ó kìlọ̀ fún gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n “wà lójúfò,” kí wọ́n sì “máa ṣọ́nà.”​—Máàkù 13:32-37.

2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn Kristẹni tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù máa ṣọ́nà?

2 Ó ṣe pàtàkì pé káwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ máa ṣọ́nà torí ìyẹn ló máa gba ẹ̀mí wọn là. Jésù ti jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí wọ́n á fi mọ ìgbà tí Jerúsálẹ́mù máa pa run. Ó sọ pé: “Tí ẹ bá rí i tí àwọn ọmọ ogun pàgọ́ yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tó máa dahoro ti sún mọ́lé.” Tó bá dìgbà yẹn, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù, kí wọ́n sì “bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.” (Lúùkù 21:20, 21) Àwọn tó ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù yìí ló là á já nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù run.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Àkókò tí òpin ayé máa dé là ń gbé báyìí. Torí náà, àwa náà gbọ́dọ̀ máa ṣọ́nà, ká sì wà lójúfò. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́ra bá a ṣe ń gbọ́ nípa àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé, bá a ṣe lè máa kíyè sára àti bá a ṣe lè fọgbọ́n lo ìwọ̀nba àkókò tó ṣẹ́ kù lọ́nà tó dáa jù lọ.

MÁA ṢỌ́RA TÓ O BÁ Ń WO ÀWỌN NǸKAN TÓ Ń ṢẸLẸ̀ LÁYÉ

4. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọ̀ nípa bí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí ṣe fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ń ṣẹ?

4 Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí jẹ́ ká rí i pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ. Ìdí pàtàkì sì wà tó fi yẹ kó máa wù wá láti mọ̀ nípa ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jésù jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan táá máa ṣẹlẹ̀ tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé ayé burúkú Sátánì yìí máa tó pa run. (Mát. 24:3-14) Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi gbà wá níyànjú pé ká máa fiyè sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń ṣẹ, kí ìgbàgbọ́ wa lè túbọ̀ lágbára. (2 Pét. 1:19-21) Àwọn ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ìwé tó kẹ́yìn Bíbélì sọ pé: “Ìfihàn látọ̀dọ̀ Jésù Kristi, èyí tí Ọlọ́run fún un, kó lè fi àwọn nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn ẹrú rẹ̀.” (Ìfi. 1:1) Torí náà, ó máa ń wù wá láti mọ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti báwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa wọn ṣe ń ṣẹ, ká sì tún máa sọ̀rọ̀ nípa wọn láàárín ara wa.

Ohun táwọn tọkọtaya ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. 1. Tọkọtaya kan ń wo tẹlifíṣọ̀n, wọ́n sì rí bí àwọn olórí orílẹ̀-èdè ṣe ń bá ara wọn ṣàdéhùn àlàáfíà. Nígbà tí wọ́n dé Ilé Ìpàdé, tọkọtaya yẹn ń sọ èrò tara wọn nípa nǹkan tí wọ́n wò fáwọn arábìnrin méjì kan. 2. Tọkọtaya míì ń wo ìròyìn látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí.Lẹ́yìn náà, wọ́n ń wàásù fún ọkùnrin kan tó wá sídìí àtẹ ìwé.

Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì láàárín ara wa, kí ló yẹ ká yẹra fún, àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe? (Wo ìpínrọ̀ 5)b

5. Kí ló yẹ ká yẹra fún, àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe? (Tún wo àwọn àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

5 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì láàárín ara wa, kò yẹ ká máa méfò nípa àwọn nǹkan tá a rò pé ó máa ṣẹlẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé a ò ní fẹ́ sọ ohunkóhun tó máa da ìṣọ̀kan ìjọ rú. Bí àpẹẹrẹ, a lè gbọ́ báwọn alákòóso ayé ṣe ń sọ báwọn ṣe máa yanjú àwọn rògbòdìyàn kan tó ń ṣẹlẹ̀, káwọn sì jẹ́ kí àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ wà. Dípò ká máa sọ pé ohun táwọn alákòóso ayé sọ ti jẹ́ ká rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ inú 1 Tẹsalóníkà 5:3 ti ṣẹ, ṣe ló yẹ ká lọ wo ohun tí ètò Ọlọ́run sọ kẹ́yìn nípa ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé nǹkan tí ètò Ọlọ́run ń kọ́ wa là ń bá àwọn ará sọ, gbogbo ìjọ ló máa ní “èrò kan náà.”​—1 Kọ́r. 1:10; 4:6.

6. Kí la rí kọ́ nínú 2 Pétérù 3:11-13?

6 Ka 2 Pétérù 3:11-13. Àpọ́sítélì Pétérù jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká ní èrò tó tọ́ tá a bá ń ka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ó gbà wá níyànjú pé ká máa fi ‘ìgbà tí ọjọ́ Jèhófà máa wà níhìn-ín sọ́kàn dáadáa.’ Kí nìdí? Kì í ṣe torí pé a fẹ́ mọ “ọjọ́ àti wákàtí” tí Jèhófà máa ja ogun Amágẹ́dọ́nì, àmọ́ ìdí tá a ṣe ń fi ọjọ́ yẹn sọ́kàn ni pé a fẹ́ lo ìwọ̀nba àkókò tó ṣẹ́ kù láti máa ‘hùwà mímọ́, ká sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.’ (Mát. 24:36; Lúùkù 12:40) Lédè míì, a fẹ́ máa hùwà tó dáa, ká sì rí i pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló ń mú ká ṣe gbogbo ohun tá à ń ṣe. Àmọ́ ká tó lè máa ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa kíyè sí ara wa.

BÁWO LA ṢE LÈ MÁA KÍYÈ SÍ ARA WA?

7. Báwo la ṣe lè máa fi hàn pé à ń kíyè sí ara wa? (Lúùkù 21:34)

7 Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kì í ṣe ohun tó ń lọ láyé nìkan ló yẹ kí wọ́n máa kíyè sí, ó tún yẹ kí wọ́n máa kíyè sí ara wọn náà. Ó kìlọ̀ fún wọn nínú Lúùkù 21:34, ohun tó sọ níbẹ̀ sì yé wọn dáadáa. (Kà á.) Ṣé ẹ kíyè sí ohun tí Jésù sọ? Ó ní: “Ẹ kíyè sí ara yín.” Ẹni tó ń kíyè sí ara ẹ̀ máa ń ṣọ́ra kí nǹkan kan má bàa ba àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ó sì máa ń yẹra fáwọn nǹkan náà. Tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, àá máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.​—Òwe 22:3; Júùdù 20, 21.

8. Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni?

8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni nímọ̀ràn pé ká máa kíyè sára wa. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe bí aláìlọ́gbọ́n àmọ́ bí ọlọ́gbọ́n.” (Éfé. 5:15, 16) Gbogbo ìgbà ni Sátánì máa ń gbìyànjú láti ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà jẹ́, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá nímọ̀ràn pé ká “máa fi òye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́” ká lè borí gbogbo àdánwò Sátánì.​—Éfé. 5:17.

9. Báwo la ṣe lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe?

9 Kì í ṣe gbogbo nǹkan tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ni Bíbélì sọ fún wa. Àtìgbàdégbà la máa ń ṣe àwọn ìpinnu kan tí Bíbélì ò sọ ohunkóhun nípa ẹ̀. Torí náà, tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu tó tọ́, a gbọ́dọ̀ fòye mọ ohun tí “ìfẹ́ Jèhófà” jẹ́. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, tá a sì ń ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a kà. Bá a bá ṣe ń mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́, tá a sì ń sapá láti ní “èrò inú Kristi,” àá túbọ̀ máa hùwà “bí ọlọ́gbọ́n,” kódà tí Bíbélì ò bá sọ ohun tó yẹ ká ṣe nírú ipò bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́r. 2:14-16) Nígbà míì, ó máa ń rọrùn láti mọ àwọn nǹkan tó yẹ ká sá fún, àmọ́ láwọn ìgbà míì kì í rọrùn.

10. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó yẹ ká sá fún?

10 Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó yẹ ká sá fún ni kéèyàn máa tage, ọtí àmujù, àjẹjù, kéèyàn máa sọ̀rọ̀ àbùkù sáwọn ẹlòmíì, kéèyàn máa wo fíìmù ìwà ipá, àwòrán ìṣekúṣe àtàwọn nǹkan míì tó jọ wọ́n. (Sm. 101:3) Gbogbo ìgbà ni Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá wa máa ń wá bó ṣe fẹ́ ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́. (1 Pét. 5:8) Tá ò bá kíyè sára, Sátánì lè mú ká di onílara, oníwọra, ká máa parọ́, ká kórìíra àwọn èèyàn, ká máa gbéra ga, ká sì máa di àwọn èèyàn sínú. (Gál. 5:19-21) Níbẹ̀rẹ̀, ó lè jọ pé irú àwọn ìwà yìí ò fi bẹ́ẹ̀ burú. Àmọ́ tá ò bá tètè jáwọ́, ó lè gbilẹ̀ lọ́kàn wa, kí ìwà náà sì kó wa síṣòro.​—Jém. 1:14, 15.

11. Ewu wo ló yẹ ká sá fún tá a lè má tètè fura sí, kí sì nìdí?

11 Ewu kan tá a lè má tètè fura sí àmọ́ tó yẹ ká sá fún ni ẹgbẹ́ búburú. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí ná. Ká sọ pé ìwọ àtẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ jọ ń ṣiṣẹ́. O fẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé èèyàn dáadáa làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí náà o máa ń ṣe dáadáa sí i, o sì máa ń ràn án lọ́wọ́. Kódà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìwọ àtẹni náà máa ń lọ jẹun pa pọ̀ lọ́sàn-án. Kó o tó mọ̀, ó ti di lemọ́lemọ́. Nígbà míì, ẹni náà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣekúṣe, ọ̀rọ̀ yẹn kì í sì í bá ẹ lára mu. Àmọ́ nígbà tó yá, ó mọ́ ẹ lára débi pé o ò rí ohun tó burú nínú ẹ̀ mọ́. Bó ṣe dọjọ́ kan nìyẹn, ló bá sọ pé òun fẹ́ gbé ẹ jáde lẹ́yìn iṣẹ́, o sì gbà fún un. Ní báyìí, o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú bíi tiẹ̀. Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, ìgbà wo lo ò ní bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà bíi tiẹ̀? Lóòótọ́, gbogbo èèyàn la máa ń finúure hàn sí, tá a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún, àmọ́ ó yẹ ká máa rántí pé ìwà àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ lè ṣàkóbá fún wa. (1 Kọ́r. 15:33) Tá a bá ń kíyè sára bí Jésù ṣe kìlọ̀ fún wa, a ò ní máa bá àwọn tí kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà rìn. (2 Kọ́r. 6:15) Tá a bá ń kíyè sára, a máa tètè rí àwọn nǹkan tó lè kó wa síṣòro, àá sì sá fún wọn.

MÁA LO ÀKÓKÒ Ẹ LỌ́NÀ TÓ DÁA JÙ LỌ

12. Kí ló yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa ṣe bí wọ́n ṣe ń dúró dìgbà tí òpin máa dé?

12 Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe ń dúró dìgbà tí òpin máa dé, ó yẹ kí wọ́n jẹ́ kí ọwọ́ wọn dí torí pé Jésù ti gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún wọn. Ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run “ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ìṣe 1:6-8) Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ńlá ni Jésù gbé fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Torí náà, tí wọ́n bá ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti wàásù fáwọn èèyàn, ìyẹn á fi hàn pé wọ́n ń lo àkókò wọn lọ́nà tó dáa jù lọ.

13. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo àkókò wa lọ́nà tó dáa jù lọ? (Kólósè 4:5)

13 Ka Kólósè 4:5. Tá a bá fẹ́ máa kíyè sí ara wa, ó yẹ ká ronú nípa ohun tá à ń fi àkókò wa ṣe. Ìdí sì ni pé “ìgbà àti èèṣì” lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni nínú wa. (Oníw. 9:11) Yàtọ̀ síyẹn, ìgbàkigbà la lè kú.

Arábìnrin tó ń wo ìròyìn nínú tẹlifíṣọ̀n àti arábìnrin tó ń wo ìròyìn látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí jọ ń kọ́ obìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n fi fídíò “Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba?” hàn án.

Báwo la ṣe lè lo àkókò wa lọ́nà tó dáa jù lọ? (Wo ìpínrọ̀ 14-15)

14-15. Báwo la ṣe lè máa lo àkókò wa lọ́nà tó dáa jù lọ? (Hébérù 6:11, 12) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 A lè lo àkókò wa lọ́nà tó dáa jù lọ tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, tá a sì ń mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ lágbára sí i. (Jòh. 14:21) Ó yẹ ká ‘dúró gbọn-in, ká má yẹsẹ̀, ká sì máa ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo.’ (1 Kọ́r. 15:58) Torí náà tí òpin bá dé, bóyá òpin ayé búburú yìí ni o tàbí a kú, a ò ní kábàámọ̀ pé a fi àkókò wa ṣe ìfẹ́ Jèhófà.​—Mát. 24:13; Róòmù 14:8.

15 Lónìí, Jésù ṣì ń darí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Jésù ń mú ìlérí tó ṣe fún wọn ṣẹ pé òun máa wà pẹ̀lú wọn. Jésù ń lo ètò Ọlọ́run láti dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ń fún wa láwọn nǹkan tá a nílò láti ṣiṣẹ́ náà. (Mát. 28:18-20) Tá a bá ń ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni, à ń pa àṣẹ Jésù mọ́ nìyẹn, èyí sì ń jẹ́ ká wà lójúfò bá a ṣe ń retí ìgbà tí Jèhófà máa pa ayé búburú yìí run. Torí náà, tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Hébérù 6:11, 12, a ò ní sọ̀rètí nù “títí dé òpin.”​—Kà á.

16. Kí la pinnu pé àá máa ṣe?

16 Jèhófà ti yan ọjọ́ àti wákàtí tó máa pa ayé búburú Sátánì yìí run. Tó bá dìgbà yẹn, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà ti sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa ayé tuntun ló máa jẹ́ kó ṣẹ láì ku ẹyọ kan. Nígbà míì, ó máa ń ṣe wá bíi pé ìgbà tí Jèhófà máa pa ayé búburú yìí run ti ń pẹ́ jù. Àmọ́, ó dájú pé ọjọ́ Jèhófà “kò ní pẹ́ rárá!” (Háb. 2:3) Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá “máa retí Jèhófà,” àá sì “dúró de Ọlọ́run ìgbàlà [wa].”​—Míkà 7:7.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra bá a ṣe ń wo àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé?

  • Tá a bá fẹ́ fi hàn pé à ń kíyè sára, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká sá fún?

  • Báwo la ṣe lè lo àkókò wa lọ́nà tó dáa jù lọ?

ORIN 139 Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun

a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá ò ṣe ní jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́ bá a ṣe ń wo àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lágbàáyé. Yàtọ̀ síyẹn, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa kíyè sára wa àti bó ṣe yẹ ká máa lo àkókò wa lọ́nà tó dáa jù lọ.

b ÀWÒRÁN: (Òkè) Tọkọtaya kan ń gbọ́ ìròyìn lórí tẹlifíṣọ̀n. Nígbà tí ìpàdé parí lọ́jọ́ kan, wọ́n ń sọ èrò tara wọn fáwọn ará kan nípa ohun tí wọ́n wò nínú ìròyìn. (Ìsàlẹ̀) Tọkọtaya kan ń wo ìròyìn látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí kí wọ́n lè mọ ohun tí ètò Ọlọ́run sọ kẹ́yìn nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Wọ́n ń fún àwọn èèyàn láwọn ìwé tí ẹrú olóòótọ́ tẹ̀ jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́