ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/03 ojú ìwé 1
  • Iṣẹ́ Ìwàásù Nínú Ayé Tí Kò Dúró Sójú Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iṣẹ́ Ìwàásù Nínú Ayé Tí Kò Dúró Sójú Kan
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lo Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Lọ́ọ́lọ́ọ́ Láti Ru Ìfẹ́ Sókè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Mímúra Sílẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Múra Tán Láti Ṣe Ìyípadà?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Máa Lo Àwọn Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Lágbègbè Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 6/03 ojú ìwé 1

Iṣẹ́ Ìwàásù Nínú Ayé Tí Kò Dúró Sójú Kan

1 Nǹkan mà ń yára yí padà o! Ní ọ̀sán-kan-òru-kan, àjálù kan, ìṣòro ọrọ̀ ajé, rúkèrúdò ìṣèlú tàbí ìròyìn nípa jàǹbá kan tó tàn kálẹ̀ lè di ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn yóò máa sọ láàárín ara wọn. Àmọ́, ká tó pajú pẹ́, àwọn èèyàn ti lè yí àfiyèsí wọn sí nǹkan mìíràn. (Ìṣe 17:21; 1 Kọ́r. 7:31) Nínú ayé tí kò dúró sójú kan yìí, báwo la ṣe lè mú káwọn èèyàn tẹ́tí sí wa kí a bàa lè ṣàjọpín ìhìn Ìjọba náà pẹ̀lú wọn?

2 Fòye Mọ Ohun Tó Ń Jẹ Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́kàn: Ọ̀nà kan tá a lè gbà mú kí àwọn èèyàn tẹ́tí sí wa ni nípa títọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́. Ní àkókò kan tí Jésù ń rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ láti ronú jinlẹ̀ nípa àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run, ó mẹ́nu kan àwọn àjálù kan tí kò pẹ́ tó ṣẹlẹ̀ sí àsìkò náà tó sì wà lọ́kàn àwọn èèyàn náà. (Lúùkù 13:1-5) Bákan náà, nígbà tá a bá ń wàásù ìhìn rere náà, ẹ jẹ́ ká tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ìròyìn gbé jáde tàbí ọ̀ràn kan ládùúgbò tí àwọn tí ń gbé ní ìpínlẹ̀ wa á fẹ́ láti gbọ́. Àmọ́ ṣá o, nígbà tá a bá ń jíròrò irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká ṣọ́ra kí ọ̀rọ̀ wa má lọ fi hàn pé à ń dá sí ọ̀ràn ìṣèlú tàbí ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.—Jòh. 17:16.

3 Báwo la ṣe lè mọ̀ nǹkan táwọn èèyàn ń ronú nípa rẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́? Ọ̀nà tó dára jù lè jẹ́ pé ká kàn bi wọ́n ní ìbéèrè kan, kí a sì wá tẹ́tí sílẹ̀ sóhun tí wọ́n á sọ. (Mát. 12:34) Ìfẹ́ tá a ní sáwọn èèyàn á sún wa láti kíyè sí ojú táwọn ẹlòmíràn fi ń wo nǹkan, kí a sì fọgbọ́n ṣèwádìí síwájú sí i. Ọ̀rọ̀ tí onílé kan sọ wẹ́rẹ́ lè jẹ́ ká mọ ohun tó ń jẹ ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn tí ń gbé lágbègbè náà lọ́kàn, èyí sì lè wá ṣí ayé sílẹ̀ láti wàásù fún wọn.

4 Mímúra Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Sílẹ̀: Láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá nínú ayé tí kò dúró sójú kan yìí, a lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìjíròrò Bíbélì Kí A Sì Máa Báa Nìṣó. Àwọn àbá wíwúlò lórí bí a ṣe lè ki àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ bọnú ìgbékalẹ̀ wa la tò sí ojú ìwé 2 sí3 àti ojú ìwé 6, lábẹ́ àkòrí náà “Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Lọ́ọ́lọ́ọ́” àti “Ìwà-Ọ̀daràn/Ààbò.” Irú ìsọfúnni yìí wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2000, ojú ìwé 4. Nígbà tó o bá ń múra bó o ṣe máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀ sílẹ̀, rí i dájú pé o ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó bá a mu.

5 Bí a ti ń kíyè sí bí àníyàn àwọn tí ń gbé ní ìpínlẹ̀ wa ṣe ń yí padà látìgbàdégbà, ó yẹ ká máa gbé ìhìn rere náà kalẹ̀ lọ́nà tí yóò gbà bá ipò wọn mu. Ní ọ̀nà yẹn, àá lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ohun tó kàn wọ́n gbọ̀ngbọ̀n nínú ìgbésí ayé. Nípa bẹ́ẹ̀, àá lè ran àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti mọ Ẹni náà tí àwọn ànímọ́ àti ìlànà rẹ̀ kì í yí padà.—Ják. 1:17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́