Ǹjẹ́ O Máa Ń Múra Tán Láti Ṣe Ìyípadà?
1. Àwọn ìyípadà wo ló yẹ ká ṣe torí bí nǹkan ṣe ń yí pa dà nínú ayé?
1 Nínú 1 Kọ́ríńtì 7:31, Bíbélì fi ayé wé orí ìtàgé níbi tí ìran ti ń yí pa dà, tí àwọn òṣèré ń lọ tí wọ́n sì ń bọ̀. Bí nǹkan ṣe ń yí pa dà láyé yìí gba pé kí àwa náà máa ṣe ìyípadà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa àti nínú bá a ṣe ń ṣètò àkókò wa, títí kan bá a ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀. Ǹjẹ́ o ti múra tán láti máa ṣe àwọn ìyípadà tó bá yẹ?
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọwọ́ yí pa dà ká lè máa bá ètò Ọlọ́run rìn?
2 Bó O Ṣe Ń Wàásù: Ọjọ́ pẹ́ tí ètò Ọlọ́run ti ń ṣe àwọn ìyípadà tó bá yẹ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù kọ́kọ́ rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe wá wúrà tàbí fàdákà sínú àpò wọn títí kan àsùnwọ̀n oúnjẹ. (Mát. 10:9, 10) Àmọ́ nígbà tó yá, ó yí ìtọ́ni yẹn pa dà torí ó mọ̀ pé wọ́n máa ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti pé iṣẹ́ ìwàásù ṣì máa gbòòrò dé àwọn ìpínlẹ̀ míì. (Lúùkù 22:36) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá, onírúurú ọ̀nà ni ètò Ọlọ́run ti gbà wàásù, a ti lo káàdì ìjẹ́rìí, ọkọ̀ tó ní gbohùngbohùn títí kan gbígbé ohùn sáfẹ́fẹ́ lórí rédíò, èyí sì bá bí nǹkan ṣe rí lásìkò yẹn mu. Ṣùgbọ́n lóde òní tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í gbélé, kì í ṣe ìwàásù ilé-dé-ilé nìkan la gbájú mọ́, a tún ń wàásù níbi táwọn èèyàn bá pọ̀ sí, a sì máa ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. Tá a bá kíyè sí pé a kì í fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn èèyàn nílé ní ọ̀sán, a tún rọ̀ wá pé ká máa wàásù láti ilé dé ilé ní ìrọ̀lẹ́. A ó lè fi hàn pé àwa náà ń bá kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run ti Jèhófà rìn bó ṣe ń yí pa dà lórí ìrìn.—Ìsík. 1:20, 21.
3. Àwọn ìyípadà wo la lè máa ṣe ká lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
3 Bó O Ṣe Ń Gbé Ọ̀rọ̀ Kalẹ̀: Kí ni ohun tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn jù ní àdúgbò rẹ? Ṣé ọ̀rọ̀ owó ni? Àbí ọ̀rọ̀ ìdílé wọn? Àbí ọ̀rọ̀ ààbò? Àbí ogun? Ó dáa ká mọ bí nǹkan ṣe ń lọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa àti ìṣòro táwọn èèyàn ibẹ̀ ń ní, ká lè mọ bí a ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ lọ́nà tí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ sí. (1 Kọ́r. 9:20-23) Táwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀ bá sọ ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn, dípò ká kàn fún wọn ní ìdáhùn ṣókí ká lè máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ, ohun tó bógbọ́n mu ni pé ká mú ọ̀rọ̀ wa bá ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn mu.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká tètè máa ṣe àwọn ìyípadà tó bá yẹ?
4 Láìpẹ́, ayé yìí máa kógbá sílé, ìpọ́njú ńlá yóò sì bẹ̀rẹ̀. Ó dájú pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù.” (1 Kọ́r. 7:29) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa ṣe àwọn ìyípadà tó bá yẹ láìjáfara, ká lè ṣe àṣeparí ohun tó pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù láàárín ìwọ̀nba àkókò tó ṣẹ́ kù yìí!