ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/09 ojú ìwé 2
  • “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo Nítorí Ìhìn Rere”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo Nítorí Ìhìn Rere”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Múra Tán Láti Ṣe Ìyípadà?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Ṣó O Lè Tún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Rẹ Ṣe?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Mímú Ìhìn Rere Náà Dé Ọ̀dọ̀ Gbogbo Àwọn Tá A Bá Lè Rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ṣé O Múra Tán Láti Di Apẹja Èèyàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 2/09 ojú ìwé 2

“Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo Nítorí Ìhìn Rere”

1. Kí làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run máa ń fẹ́ láti ṣe fáwọn èèyàn, kí sì nìdí?

1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ka pípolongo ìhìn rere fáwọn èèyàn sí ohun àìgbọ́dọ̀máṣe. (1 Kọ́r. 9:16, 19, 23) Bákan náà, torí pé a fẹ́ káwọn èèyàn jèrè ìyè àìnípẹ̀kun, ìyẹn ló ń mu ká máa lọ wàásù ìhìn rere fún wọn.

2. Àwọn àyípadà wo la máa ń fẹ́ ṣe nígbà tá a bá ń wàásù, kí sì nìdí?

2 Wàásù Níbi Tó O Ti Lè Rí Àwọn Èèyàn àti Nígbà Tó O Lè Bá Wọn: Àwọn apẹja tó mọṣẹ́ máa ń dẹ ìwọ̀ tàbí àwọ̀n síbi tí wọ́n ti lè rí ẹja pa àti nígbà tí wọ́n lè rí ẹja, wọn kì í dẹ ẹ́ síbi tó bá ṣá à ti rọ̀ wọ́n lọ́rùn àti nígbà tó bá rọ̀ wọ́n lọ́rùn. Ó yẹ káwa náà tá a jẹ́ “apẹja ènìyàn” ṣe àwọn àyípadà kan kó lè ṣeé ṣe fún wa láti máa rí àwọn èèyàn wàásù fún ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ ní ayọ̀ téèyàn máa ń rí nínú kíkó “ẹja onírúurú jọ.” (Mát. 4:19; 13:47) Ǹjẹ́ a lè máa wá àwọn èèyàn lọ sílé lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ tàbí ká ṣe ìjẹ́rìí òpópónà láàárọ̀ kùtù? Ohun tó wà lórí ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù ni láti “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere,” ó sì lo àwọn àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Ìṣe 17:17; 20:20, 24.

3, 4. Tá a bá wà lóde ẹ̀rí, báwo la ṣe lè mú kọ́rọ̀ wa bá ipò onílé mu, kí ló sì máa jẹ́ àbájáde ẹ̀?

3 Jẹ́ Kí Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Rẹ Bá Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Yín Mu: Àwọn apẹja sábà máa ń yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà pẹja pa dà, kí wọ́n lè rí oríṣi ẹja kan pa. Báwo la ṣe lè wàásù ìhìn rere lọ́nà tó máa fa àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa mọ́ra? A gbọ́dọ̀ lo ọgbọ́n láti dá ọ̀rọ̀ kan tó ń jẹ gbogbo èèyàn lọ́kàn sílẹ̀, ká wá fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí onílé máa sọ lórí ọ̀rọ̀ náà. (Ják. 1:19) A tún lè béèrè àwọn ìbéèrè tó máa mú kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. (Òwe 20:5) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa gbé ìhìn rere náà kalẹ̀ lọ́nà tá á mú kí wọ́n ṣe àwọn àyípadà pàtàkì nígbèésí ayé wọn. Pọ́ọ̀lù di “ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.” (1 Kọ́r. 9:22) Mímọ béèyàn ṣe ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó bá ipò onílé mu jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà mú kọ́rọ̀ wa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn.

4 Ẹ ò rí i pé ayọ̀ ńlá ló jẹ́ láti máa wàásù “ìhìn rere ohun tí ó dára jù” fáwọn èèyàn! (Aísá. 52:7) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe “ohun gbogbo nítorí ìhìn rere” ká bàa lè wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó.—1 Kọ́r. 9:23.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́