ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/06 ojú ìwé 8
  • Ṣó O Lè Tún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Rẹ Ṣe?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó O Lè Tún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Rẹ Ṣe?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ O Lè Kópa Nínú Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • O Ha Ti Gbìyànju Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́ Bí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Wíwá Àwọn Ẹni Yíyẹ Rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Máa Ra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Pa Dà Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 4/06 ojú ìwé 8

Ṣó O Lè Tún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Rẹ Ṣe?

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká tún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìwàásù wa ṣe?

1 Àwa Kristẹni ti gba ìkésíni láti “di apẹja ènìyàn.” (Mát. 4:19) Bíi tàwọn apẹja, bí àwa náà bá ṣètò àkókò ká lè lọ wàásù nígbà tá a máa bá àwọn èèyàn nílé, àṣeyọrí wa á túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Lọ́pọ̀ ilẹ̀, àwọn ọjọ́ kan wà tí ọ̀sán á máa gùn ju òru lọ láwọn oṣù tó ń bọ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wà nílé lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ mọ́ ọwọ́ alẹ́. Ara wọn máa ń sábà silé ó sì máa ń rọrùn fún wọn láti gbàlejò. Ṣé wàá lè tún àkókò rẹ ṣètò kó o lè ráyè lọ wàásù fáwọn èèyàn nírú àkókò yìí?—1 Kọ́r. 9:23.

2. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a fi lè mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn?

2 Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́: Bá a bá ṣètò láti jẹ́rìí lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, á jẹ́ ká lè rí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i sọ ìhìn rere náà fun. (Òwe 21:5) Àwọn èwe lè jẹ́rìí lẹ́yìn àkókò ilé ẹ̀kọ́. Àwa tó kù lè ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn àkókò iṣẹ́. Àwọn àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lè ṣètò láti wàásù fún bíi wákàtí kan kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ti ọ̀sẹ̀ náà.

3. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà wàásù lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ àti lọ́wọ́ alẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?

3 Ìwàásù láti ilé dé ilé lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ àti lọ́wọ́ alẹ́ lè jẹ́ ká ríbi bá àwọn tí a kì í sábà bá nílé sọ̀rọ̀. Láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù kan, ó lè jẹ́ pé ìjẹ́rìí òpópónà àti irú ìjẹ́rìí mìíràn ló máa dáa láti ṣe lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Kódà àwọn kan tí rí i pé ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ló dáa jù láti ṣe ìpadàbẹ̀wò kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo ìfòyemọ̀ ká sì máa gba tàwọn ẹlòmíràn rò nígbà tá a bá ń wàásù nírọ̀lẹ́?

4 A Nílò Ìfòyemọ̀: Ó yẹ ká lo òye nígbà tá a bá ń wàásù nírọ̀lẹ́. Ó sábà máa ń dára jù lọ ká fi ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́ mọ sí ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ nìkan dípò ọwọ́ alẹ́ nígbà tó ṣeé ṣe kí ẹni náà ti fẹ́ sùn. (Fílí. 4:5) Bó o bá kan ilẹ̀kùn, dúró síbi tí wọ́n á ti rí ọ kedere kó o sì sọ irú ẹni tó o jẹ́ fún wọn lọ́nà tó ṣe kedere. Lójú ẹsẹ̀ ni kó o ti sọ ohun tó o wá ṣe. Bó bá jẹ́ àkókò tí ọwọ́ wọn dí bí àkókò tí wọ́n ń jẹun ló lọ, sọ fún wọn pé wàá padà wá. Máa rí i pé ò ń ro tiwọn mọ́ tìẹ ní gbogbo ìgbà.—Mát. 7:12.

5. Báwo la ṣe lè dáàbò bo ara wa kúrò lọ́wọ́ ewu nígbà tá a bá ń wàásù?

5 A tún gbọ́dọ̀ máa kíyè sí àwọn nǹkan tó lè wu wá léwu. Bó o bá ń wàásù lọ́wọ́ alẹ́ tàbí nígbà tí ilẹ̀ bá ṣú, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kẹ́ ẹ pé méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Òpópónà tí iná rẹ̀ mọ́lẹ̀ kedere táwọn èèyàn sì ń rìn lọ rìn bọ̀ ni kẹ́ ẹ ti máa wàásù. Àwọn ibi tó láàbò nìkan ni kẹ́ ẹ ti máa wàásù o. Ẹ ò gbọ́dọ̀ wàásù lálẹ́ láwọn ibi tó léwu o.—Òwe 22:3.

6. Àwọn àǹfààní mìíràn wo la lè rí nínú ìjẹ́rìí lọ́wọ́ ọ̀sán mọ́ ìrọ̀lẹ́?

6 Wíwàásù lọ́wọ́ ọ̀sán mọ́ ìrọ̀lẹ́ á jẹ́ ká lè bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ àti aṣáájú-ọ̀nà déédéé ṣiṣẹ́. (Róòmù 1:12) Àní ṣé wàá lè ṣàtúnṣe sí àkókò rẹ̀ kó o bàa lè lọ́wọ́ sí apá iṣẹ́ ìsìn yìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́