ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/96 ojú ìwé 1-7
  • O Ha Ti Gbìyànju Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Ha Ti Gbìyànju Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́ Bí?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣó O Lè Tún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Rẹ Ṣe?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ǹjẹ́ O Lè Kópa Nínú Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Wíwá Àwọn Ẹni Yíyẹ Rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Wàásù Ìhìn Rere Náà Níbi Gbogbo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 7/96 ojú ìwé 1-7

O Ha Ti Gbìyànju Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́ Bí?

1 Gbogbo wa ń rí inú dídùn nínú jíjẹ́ ẹni tí ń méso jáde nínú iṣẹ́ wa. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, nígbà tí kò bá ṣeé ṣe fún wa láti rí àbájáde rere, iṣẹ́ lè di èyí tí ń súni, tí kò sì tẹ́ni lọ́rùn. Òpò tí ó ní ète máa ń mú èrè wá fúnni, ó sì jẹ́ ìbùkún. (Fi wé Oníwàásù 3:10-13.) A lè lo ìlànà yìí fún iṣẹ́ ìwàásù wa. A mọ̀ láti inú ìrírí pé, nígbà tí a bá lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, tí ó sì ṣeé ṣe fún wa láti jíròro Bíbélì pẹ̀lú àwọn ènìyàn, a máa ń padà sílé pẹ̀lú ìtura tẹ̀mí. A máa ń nímọ̀lára pé a ti ṣàṣeparí ohun kan ní ti gidi.

2 Ní àwọn agbègbè kan, bíbá àwọn ènìyàn nílé ní àwọn àkókò kan lóòjọ́ ti di ìṣòro ńlá. Ìròyín fi hàn pé ní ibi púpọ̀, èyí tí ó ju ìdajì àwọn ènìyàn lọ ni a kì í bá nílé nígbà tí a bá ṣe ìkésíni ní òwúrọ̀. Ọ̀pọ̀ ìjọ ti kojú ìṣòro yìí nípa ṣíṣètò fún ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì ti ṣàṣeyọrí ńlá. Àwọn akéde ròyìn pé, nígbà tí àwọ́n bá ṣe ìkésíni ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i máa ń wà nílé, ní gbogbogbòò, ara àwọn ènìyán sì máa ń balẹ̀, wọ́n sì máa ń túbọ̀ ní ìtẹ̀sí láti tẹ́tí sílẹ̀ sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Ìwọ́ ha ti gbìyànjú ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́ ní ìpínlẹ̀ yín bí?—Fi wé Máàkù 1:32-34.

3 Ẹ̀yin Alàgbà, Ẹ Ṣètò fún Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́: Ní àwọn agbègbè kan, àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn ní ìrọ̀lẹ́ ni a ti kọ́wọ́ tì lẹ́yìn dáradára. A lè gba ti àwọn ọ̀dọ́ akéde tí wọ́n ń jáde ilé ẹ̀kọ́ ní ọ̀sán, àti àwọn àgbàlagbà tí wọ́n máa ń darí dé láti ibi iṣẹ́ ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ rò. Àwọn akéde tí kì í ṣeé ṣe fún láti jáde iṣẹ́ ìsin pápá ní òpin ọ̀sẹ̀ máa ń ri pé ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan tí ó gbéṣẹ́ fún wọn láti ṣàjọpín déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù.

4 Onírúurú ìgbòkègbodò wà tí ẹ lè lọ́wọ́ sí nínú ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́. Ẹ lè fi ìwé ìròyìn jẹ́rìí láti ilé dé ilé tàbí kí ẹ lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ń fi lọni ní oṣù náà. Ìrọ̀lẹ́ jẹ́ àkókò kan tí ó dára láti kàn sí àwọn ènìyàn tí kò sí nílé nígbà tí àwọn akéde ké sí wọn ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà tàbí ní òpin ọ̀sẹ̀. Àwọn ìpínlẹ̀ tí ó dára fún ìjẹ́rìí òpópónà lè wà pẹ̀lú, tí yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún yín láti kàn sí àwọn ènìyàn tí ń darí wálé láti ibi iṣẹ́. Ọ̀pọ̀ ń rí i pé ìrọ̀lẹ́ ni àkókò tí ó dára jù lọ láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fi ọkàn-ìfẹ́ hàn.

5 Jẹ́ Oníṣọ̀ọ́ra àti Ọlọ́gbọ́n Inú: Jíjáde ní alẹ́ tàbí nígbà tí ilẹ̀ ti ṣú, lè léwu ní àwọn agbègbè kan. Yóò bọ́gbọ́n mu láti rìn ní méjìméjì tàbí lẹ́gbẹẹgbẹ́ ní àwọn òpópónà tí ó nímọ̀ọ́lẹ̀ kedere, kí ẹ sì ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé tàbí ilé àdágbé kìkì tí ẹ bá ní ìdánilójú pé ẹ̀mí yín dè. Nígbà tí o bá kan ìlẹ̀kùn, dúró síbi tí wọ́n ti lè rí ọ, kí o sì sọ ẹni tí o jẹ́ ní kedere. Jẹ́ afòyemọ̀. Tí o bá kíyè sí i pé àkókò tí o ṣèbẹ̀wò kò rọgbọ, bíi nígbà tí ìdílé náà ń jẹun lọ́wọ́, sọ fún wọn pé ìwọ yóò ṣèbẹ̀wò ní ọjọ́ mìíràn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó dára jù lọ láti fi ìjẹ́rìí rẹ mọ sí ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, dípò ṣíṣèbẹ̀wò lálẹ́, nígbà tí àwọn onílé lè máa múra àtisùn.

6 Àwọn ọjọ́ tí ilẹ̀ kì í tètè ṣú jẹ́ àkókò tí ó dára gan-an fún jíjẹ́rìí. Bí a ti ń ṣe ‘iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run tọ̀sán tòru,’ Jèhófà yóò máa bù kún ìsapá wa dájúdájú.—Iṣi. 7:15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́