Ǹjẹ́ O Lè Kópa Nínú Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́?
1. Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan ṣe sọ, ìgbà wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń wàásù láti ilé dé ilé?
1 Ìwé kan tó dá lórí bí ìgbésí ayé ṣe rí nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì sọ pé, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sábà máa ń wàásù láti ilé dé ilé “bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ títí di ọwọ́ alẹ́ pátápátá.” A ò lè sọ bóyá aago tí Pọ́ọ̀lù ń jáde lọ wàásù gan-an nìyẹn, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù máa ń fẹ́ láti “ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere.” (1 Kọ́r. 9:19-23) Pọ́ọ̀lù ti ní láti ṣètò àkókò rẹ̀ kó bàa lè ṣeé ṣe fún un láti wàásù láti ilé dé ilé ní àkókò tó máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn bá sọ̀rọ̀.
2. Kí nìdí tí ìrọ̀lẹ́ fi jẹ́ àkókò tó dáa láti jẹ́rìí?
2 Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àárọ̀ làwọn akéde sábà máa ń wàásù láti ilé dé ilé láàárín ọ̀sẹ̀. Àmọ́, ṣé àárọ̀ náà ló dáa jù láti wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tiyín? Arákùnrin kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sọ bí ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ rẹ̀ ṣe rí, ó ní: “Agbára káká la máa fi ń bá àwọn èèyàn nílé láàárọ̀. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wà nílé lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́.” Ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́ lè fún wa láǹfààní tó dáa jù láti wàásù ìhìn rere fún àwọn ọkùnrin ní pàtàkì. Ara sábà máa ń tu àwọn èèyàn lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì máa ń fi àyè sílẹ̀ ká lè bá wọn fèrò wérò. Kí àwọn alàgbà ṣètò bí ìjọ á ṣe máa ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, tí wọ́n bá rí i pé ó máa dáa pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.
3. Báwo la ṣe lè lo ìfòyemọ̀ tá a bá ń jẹ́rìí lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́?
3 Máa Lo Ìfòyemọ̀: Tá a bá ń jẹ́rìí lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, ó ṣe pàtàkì pé ká máa lo ìfòyemọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o kan ilẹ̀kùn ẹnì kan lásìkò tí ọwọ́ rẹ̀ dí, bóyá nígbà tó ń jẹun lọ́wọ́, ohun tó dáa jù ni pé kó o sọ fún un pé wàá pa dà wá nígbà míì. Ó tún bọ́gbọ́n mu pé ká máa ṣiṣẹ́ ní méjì-méjì tàbí ká lọ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ. Ẹ má ṣe lọ sọ́dọ̀ àwọn tẹ́ ẹ fẹ́ wàásù fún nígbà tí wọ́n ti ń múra láti sùn, kí ẹ má bàa dí wọn lọ́wọ́. (2 Kọ́r. 6:3) Tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa léwu láti wàásù láwọn àdúgbò kan tí ilẹ̀ bá ti ṣú, kí ẹ wàásù níbẹ̀ kí ilẹ̀ tó ṣú.—Òwe 22:3.
4. Àwọn ìbùkún wo la máa ń rí nínú ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́?
4 Àwọn Ìbùkún Tá A Máa Rí: A máa ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù dáadáa nígbà tá a bá rí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀. Bá a ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn tó la túbọ̀ ń láǹfààní láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ ‘kí a lè gbà wọ́n là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.’ (1 Tím. 2:3, 4) Ǹjẹ́ o lè ṣètò àkókò rẹ kó lè ṣeé ṣe fún ẹ láti kópa nínú ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́?