Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 8
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 8
Orin 75 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 27 ìpínrọ̀ 19 sí 26, àti àpótí tó wà lójú ìwé 212, 214 àti 217 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Dáníẹ́lì 7-9 (10 min.)
No. 1: Dáníẹ́lì 7:13-22 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìwàláàyè Jésù Gẹ́gẹ́ Bí Èèyàn Ni A Fi San “Ìràpadà fún Gbogbo Èèyàn”—td 27A (5 min.)
No. 3: Àwọn Ọ̀nà Wo Ni Jèhófà Gbà Jẹ́ Adúróṣinṣin?—Ìṣí. 15:4; 16:5 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Bí Ẹnì Kan Bá Sọ Pé, ‘Ọwọ́ Mi Dí.’ Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 11 àti 12. Ẹ jíròrò díẹ̀ lára àwọn àbá tó wà níbẹ̀ nípa bí a ṣe lè dá ẹni tó bá sọ pé ọwọ́ òun dí lóhùn àtàwọn nǹkan míì táwọn ará ti ṣe láṣeyọrí nígbà tí wọ́n bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ pàdé. Ṣe àṣefihàn méjì ní ṣókí.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Mátíù 21:12-16 àti Lúùkù 21:1-4, kẹ́ ẹ sì jíròrò àwọn ohun tá a lè rí kọ́ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì náà.
10 min: “Ǹjẹ́ O Lè Kópa Nínú Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ kejì, ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n kópa nínú ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́.
Orin 92 àti Àdúrà