ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/96 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún July

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún July
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 1
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 8
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 15
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 22
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 29
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 7/96 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún July

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 1

Orin 90

12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a ṣà yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ lórí ìròyin March fún iṣẹ́ ìsin pápá ti orílẹ̀-èdè lápapọ̀ àti ti ìjọ.

15 min: “Mímú Ẹ̀jẹ́ Wa Ṣẹ Lójoojúmọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé láti inú Insight, Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 1162, ìpínrọ̀ 6 àti 7, tí ń fi ìdí tí ẹ̀jẹ́ fi jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe hàn kún un.

18 min: “Fara Wé Jèhófà Nípa Fífi Tinútinú Ṣàníyàn Nípa Àwọn Ẹlòmíràn.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 3) Lo ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ láti gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà kalẹ̀. Pinnu èwo nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí ó wà lọ́wọ́ nínú ìjọ ni ó lè ru ìfẹ́ àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìpínlẹ̀ yín sókè. Lẹ́yìn náà, ṣàyẹ̀wo ìpínrọ̀ 2 àti 3 nìkan, kí o sì ṣàṣefihàn bí a ṣe lè bójú tó ìkésíni àkọ́kọ́ àti ìpadàbẹ̀wò nípa lílo ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Fi bí àwọn akéde ṣe lè gbé ìgbékalẹ̀ tiwọn dìde fún fífi ìwé pẹlẹbẹ mìíràn tí yóò bá ìpínlẹ̀ àdúgbò mu síta hàn.

Orin 112 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 8

Orin 63

5 min: Ìfilọ̀ àdúgbò.

23 min: “Jíjẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Wá Máa Tàn Ṣáá.” Gbé ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí lé orí ìpínrọ̀ 1 sí 5. Kí a kárí ìpínrọ̀ 6 sí 16 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 6 sí 9, 15, àti 16. Lo ìpínrọ̀ 17 sí 19 láti fi parí rẹ̀. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsín bójú tó o, bí ó bá ṣeé ṣe.

17 min: “A Nílò Àwọn Arákùnrin Púpọ̀ Sí i Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Bí àkókò bá ti yọ̀ǹda sí, ṣàyẹ̀wò àwọn àbá lórí bí a ṣe lè bójú tó àwọn àìní ti ìnáwó, gẹ́gẹ́ bí a ti jíròrò rẹ̀ nínú Ilé-Ìṣọ́nà, September 15, 1993, ojú ìwé 28 sí 31.

Orin 16 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 15

Orin 162

10 min: Ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.

20 min: “O Ha Ti Gbìyànju Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́ Bí?” Ọ̀rọ̀ àsọyé pẹ̀lú ìlóhùnsí àwùjọ àti àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò mélòó kan. Ròyin àwọn ohun tí a ti kíyè sí ládùúgbò nígbà tí a ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ wa ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́. Fi àwọn ìrírí tí ń fi àwọn àbájáde dídára láti inú jíjẹ́rìí ní ìrọ̀lẹ́ hàn kún un. Ṣe ìlàlẹ́sẹẹsẹ ètò tí ìjọ ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún àwọn ìpàdé iṣẹ́ ìsìn.

15 min: “Fara Wé Jèhófà Nípa Fífi Tinútinú Ṣàníyàn Nípa Àwọn Ẹlòmíràn.” (Ìpínrọ̀ 4 àti 5) Jíròro kìkì ìpínrọ̀ 4 àti 5 àti àwọn kókó pàtàkì díẹ̀ láti inú ìwé pẹlẹbẹ náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú. Lẹ́yìn náà, ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dábàá fún ìkésíni àkọ́kọ́ àti ìpadàbẹ̀wò.

Orin 64 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 22

Orin 108

5 min: Ìfilọ̀ àdúgbò. Ní ṣókí, ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé ìròyìn tí ó dé kẹ́yìn, ní títọ́ka sí àwọn kókó pàtàkì tí ń fani lọ́kàn mọ́ra tí a lè lò láti fi wọ́n lọni ní ẹnu ọ̀nà.

12 min: “Fara Wé Jèhófà Nípa Fífi Tinútinú Ṣàníyàn Nípa Àwọn Ẹlòmíràn.” (Ìpínrọ̀ 6 sí 8) Lo ìpínrọ̀ tí ó kẹ́yìn nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà láti fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti tètè máa ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fi ìwé pẹlẹbẹ sílẹ̀ fún. Ní lílo ìpínrọ̀ 6 àti 7, ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi ìwé pẹlẹbẹ náà, Ète Igbesi-Aye lọni nígbà ìkésíni àkọ́kọ́ àti bí a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú orí kìíní ìwé Ìmọ̀, nígbà ìpadàbẹ̀wò. Rán àwọn akéde létí pé wọ́n lè gbé ìgbékalẹ̀ tiwọn dìde fún fífi àwọn ìwé pẹlẹbẹ mìíràn síta, ní títẹ̀ lé àwọn ìgbékalẹ̀ àwòkọ́ṣe tí a dámọ̀ràn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

13 min: “Lépa Góńgó Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún. Ìjíròrò láàárín alàgbà kan àti ọ̀dọ́langba kan tàbí méjì, tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, December 15, 1988, ojú ìwé 25 sí 27. Àwọn èwe náà ń gbìyànjú láti pinnu àwọn góńgó tí wọn yóò lépa lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ilé ẹ̀kọ́ gíga. Wọ́n ń fi ìfẹ́ hàn nínú àǹfààní ohun ti ara tí àwọn iṣẹ́ ayé ń nawọ́ rẹ̀ sí wọn. Alàgbà tọ́ka sí àwọn ìdí tí ó jíire tí ó fi dára jù lọ láti nàgà fún iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Àwọn ọ̀dọ́langba náà gbà bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ṣiyè méjì pé bóyá àwọ́n lè ṣe aṣáájú ọ̀nà kí àwọn sì pèsè fún ara àwọn nípa tara. Alàgbá ṣàjọpín àwọn ìrírí láti inú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà pẹ̀lú wọn, tí ń fi hàn pé iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà jẹ́ góńgó tí ó bọ́gbọ́n mu, tí ọwọ́ sì lè tẹ̀, tí ń mú ìdùnnú wá fún ọ̀pọ̀. Ìjíròrò náà parí pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́langba náà tí wọ́n ń fi ìmọrírì wọn hàn fún àlàyé alàgbà náà, tí wọ́n sì sọ ìpinnu wọn láti ronú jinlẹ̀ gidigidi lórí lílépa góńgó ṣíṣàjọpín kíkún nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà.

15 min: “Bí A Óò Ṣe Fi Ìwé Ìmọ̀ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn.” Ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó kárí ìpínrọ̀ 12 sí 16 nínú àkìbọnú June 1996. Fi àṣefihàn méjì, ti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ń lọ lọ́wọ́ kún un. Àkọ́kọ́ ń fi bí a tí í kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ láti múra ẹ̀kọ́ sílẹ̀ nípa kíkun àwọn ọ̀rọ̀ tàbí fífàlà sábẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe kókó, tí ó dáhùn àwọn ìbéèrè tí a tẹ̀ náà ní tààràtà hàn. Ìkejì fi ohun tí o lè sọ láti fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níṣìírí láti wá sí Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà hàn.

Orin 116 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní July 29

Orin 212

5 min: Ìfilọ̀ àdúgbò.

15 min: Kí Ni Ó Ń Gbà Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Alàgbà kán darí ìjíròrò láàárín àwọn méjì tàbí mẹ́ta, tí wọ́n ti ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ní ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí a lè gbà kẹ́sẹ járí sí i ní bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́: (1) Gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. (2) Nípìn-ín déédéé nínú onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti wá àwọn olùfìfẹ́hàn rí. (3) Kọ orúkọ gbogbo àwọn tí ó fìfẹ́ hàn sílẹ̀, kí o sì tètè ṣèpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn. (4) Máa fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ gbogbo àwọn tí ó bá fìfẹ́ hàn. (Wo ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà, “Bíbẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli,” tí ó wà ní ojú ìwe 20 nínú Ilé-Ìṣọ́nà February 15, 1996.) (5) Ní ìgbọ́kànlé nínú ìtóótun rẹ láti kọ́ni, nípa lílo àwọn ìdámọ̀ràn mẹ́rin tí a là lẹ́sẹẹsẹ ní ojú ìwé 15 sí 19 nínú Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1985.

25 min: “Ojúṣe Rẹ Nínu Kíkọ́lé fún Ọjọ́ Ọ̀la.” Ìbéèrè àti ìdáhùn, tí ó kárí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ inú àkìbọnú. Ka ìpínrọ̀ 6, 7, 13, àti 14. Gbóríyìn fún àwọn ará fún ọrẹ ọlọ́làwọ́ tí wọ́n ń ṣe sínú Owó Àkànlo Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba àti fún ìtìlẹ́yìn tí wọ́n ṣe fún iṣẹ́ ìdáwọ́lé ìkọ́lé èyíkéyìí ládùúgbò.

Orin 12 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́