Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 16
Orin 98
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 29-31
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 29:1-20
No. 2: Ìdí Tó Fi Yẹ Ká “Dẹ́kun Ṣíṣàníyàn” (Mát. 6:25)
No. 3: Ìgbọràn Ń Dáàbò Bò Ọ́ (lr orí 7)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 172
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù February sílẹ̀.
15 min: “Ẹ Máa Ṣe Ohun Gbogbo Nítorí Ìhìn Rere.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
15 min: Ṣó O Lè Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lákòókò Ìrántí Ikú Kristi Yìí? Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn fi ìtara sọ àsọyé yìí. Sọ àwọn ohun tó yẹ káwọn tó máa ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ dójú ìlà rẹ̀. Sọ ayọ̀ àti ìbùkún táwọn tó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ máa ń ní. Sọ ètò tí ìjọ ṣe fún àfikún ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lóṣù March, April àti May. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde méjì tàbí mẹ́ta tó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ́dún tó kọjá. Àwọn àyípadà wo ni wọ́n ṣe sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọn kó bàa lè ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n rí níbẹ̀? Fún gbogbo ìdílé níṣìírí láti wo ohun tí wọ́n lè ṣe tí ẹnì kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ìdílé wọn á fi lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nígbà Ìrántí Ikú Kristi tó ń bọ̀ yìí.
Orin 151