Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 17
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 17
Orin 48 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 10 ìpínrọ̀ 20 sí 27 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìṣe 5-7 (10 min.)
No. 1: Ìṣe 5:17-32 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Lẹnì Kan Lè Ṣe Tó Bá Fẹ́ Kí Jèhófà Mọ Òun?—2 Tím. 2:19 (5 min.)
No. 3: Kí Nìdí Tá A Fi Ń Bẹ Àwọn Èèyàn Wò Léraléra?—td 20B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Bá A Ṣe Lè Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Èèyàn Lóde Ẹ̀rí. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 190, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 192, ìpínrọ̀ 1. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn bí akéde kan ṣe ń wàásù láìbọ̀wọ̀ fún ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà, kí akéde náà tún àṣefihàn náà ṣe, kó sì wá bọ̀wọ̀ fún ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀.
10 min: Ran Ẹni Tí Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́wọ́ Kó Lè Di Akéde. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 79, ìpínrọ̀ 1 sí kókó tó gbẹ̀yìn lójú ìwé 80.
10 min: “A Ní Àǹfààní Púpọ̀ Sí I Láti Yin Jèhófà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká.
Orin 9 àti Àdúrà