Ẹ̀KỌ́ 13
Wíwo Ojú Àwùjọ
OJÚ wa máa ń fi ìṣarasíhùwà wa àti bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wa hàn. Ó lè fi hàn pé ẹnu ya èèyàn tàbí pé ẹ̀rù bà á. Ó lè fi ìyọ́nú tàbí ìfẹ́ hàn. Nígbà mìíràn, ó lè fi hàn pé èèyàn ń ṣiyè méjì tàbí pé inú onítọ̀hún bà jẹ́. Ọkùnrin àgbàlagbà kan sọ nípa àwọn ará ìlú rẹ̀, tí wọ́n ti jìyà púpọ̀ pé: “Ojú wa la fi ń sọ̀rọ̀.”
Àwọn ẹlòmíràn lè ní àwọn èrò kan nípa wa tàbí nípa ohun tí a sọ nítorí ibi tí a gbójú sí. Nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀yà, àwọn èèyàn sábà máa ń fọkàn tán ẹni tó bá ń fi ìdùnnú wo ojú wọn. Ní ìdà kejì, wọ́n lè ṣiyè méjì nípa òtítọ́ ọkàn tàbí ìtóótun ẹni tó bá tẹrí mọ́lẹ̀ tàbí tó ń wo nǹkan mìíràn dípò kí ó máa wo ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀. Nínú àwọn ẹ̀yà mìíràn, wọ́n ka wíwo ojú ẹni kòrókòró sí ìwà àfojúdi, ìwà òfínràn, tàbí ìpèníjà. Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì nígbà tí èèyàn bá ń bá ẹni tó jẹ́ ẹ̀yà kejì, tàbí olóyè tàbí ẹnì kan tó wà ní ipò gíga sọ̀rọ̀. Ní àwọn ibì kan pẹ̀lú, bí ẹnì kan bá ń bá ẹni tí ó jù ú lọ sọ̀rọ̀ tó sì wá ń wo ẹyinjú ẹni yẹn, àrífín ni wọn yóò kà á sí.
Ṣùgbọ́n, níbi tí kò bá ti burú, wíwo ojú ẹni nígbà tí a bá ń sọ gbólóhùn pàtàkì kan lè pe àfiyèsí pàtàkì sí ohun tí a sọ. A lè wò ó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé ohun tí olùbánisọ̀rọ̀ ń sọ dá a lójú. Wo ohun tí Jésù ṣe nígbà tí ẹnu ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gidigidi, tí wọ́n sì sọ pé: “Ta ni a lè gbà là ní ti tòótọ́?” Bíbélì ròyìn pé: “Ní wíwò wọ́n lójú, Jésù wí fún wọn pé: ‘Lọ́dọ̀ ènìyàn, èyí kò ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.’” (Mát. 19:25, 26) Ìwé Mímọ́ tún fi hàn pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fara balẹ̀ ṣàkíyèsí ìṣesí àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀. Nígbà kan, ọkùnrin kan tó yarọ láti ìgbà tí wọ́n ti bí i wà níbi tí Pọ́ọ̀lù ti ń sọ̀rọ̀. Ìṣe 14:9, 10 sọ pé: “Ọkùnrin yìí ń fetí sílẹ̀ bí Pọ́ọ̀lù ti ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ pé, bí ó ti tẹjú mọ́ ọn, tí ó sì rí i pé ó ní ìgbàgbọ́ pé a lè mú òun lára dá, ó wí pẹ̀lú ohùn rara pé: ‘Dìde nà ró ṣánṣán lórí ẹsẹ̀ rẹ.’”
Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe Lóde Ẹ̀rí. Nígbà tí o bá wà lóde ẹ̀rí, yára mọ́ àwọn èèyàn kí o sì rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn bí o ti ń tọ̀ wọ́n lọ. Níbi tí ó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, lo àwọn ìbéèrè tí ń múni ronú jinlẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí nǹkan tó ṣeé ṣe kí ẹ̀yin méjèèjì nífẹ̀ẹ́ sí. Bí o ti ń ṣe èyí, gbìyànjú láti rí i pé ojú yín kojú tàbí ó kéré tán, kí o rí i pé o wo ojú ẹni náà lọ́nà tó fi ọ̀wọ̀ àti inúure hàn. Ẹ̀rín músẹ́ látọ̀dọ̀ ẹni tí ojú rẹ̀ fi hàn pé inú rẹ̀ dún látọkànwá máa ń fani mọ́ra. Irú ìṣesí bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kí ẹni yẹn mọ púpọ̀ nípa irú ẹni tí o jẹ́, ó sì lè jẹ́ kí ara túbọ̀ tu ẹni yẹn bí ẹ ti ń fọ̀rọ̀ wérọ̀.
Níbi tí ó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, ṣíṣàkíyèsí ohun tí ojú ẹni yẹn fi hàn lè jẹ́ kí o mọ ibi tó yẹ kí o gbé ọ̀rọ̀ gbà. Bí inú bá ń bí ẹni náà tàbí tó bá jẹ́ pé ńṣe ni kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, yóò ṣeé ṣe fún ọ láti rí i. Bí ohun tí ò ń sọ kò bá yé e, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti mọ̀ bẹ́ẹ̀. Bí kò bá lè ní sùúrù mọ́, wàá mọ̀. Bó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ gidigidi, èyí yóò hàn kedere pẹ̀lú. Bí ojú rẹ̀ bá ṣe rí lè mú kí o mọ̀ bóyá kó o yára tàbí kó o rọra sọ̀rọ̀, bóyá kó o túbọ̀ gbìyànjú láti mú kí ó lóhùn sí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn, bóyá o ní láti dá ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn dúró tàbí bóyá ó yẹ kí o tilẹ̀ tún fi bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án.
Bóyá ńṣe lò ń jẹ́rìí ní gbangba ni o tàbí ò ń báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, gbìyànjú láti rí i pé ò ń wo ojú ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ṣùgbọ́n, má ṣe tẹjú mọ́ ọn nítorí ìyẹn lè dójú tì í. (2 Ọba 8:11) Ṣùgbọ́n máa wo ojú ẹni yẹn látìgbàdégbà bó ṣe yẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ sọ́rẹ̀ẹ́. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, èyí máa ń fi han ẹni yẹn pé o ní ìfẹ́ àtọkànwá sí òun. Àmọ́ ṣá o, nígbà tí o bá ń ka Bíbélì tàbí ìtẹ̀jáde mìíràn, ìwé tí ò ń kà ni wàá gbájú mọ́. Ṣùgbọ́n tó o bá fẹ́ tẹnu mọ́ kókó kan, o yẹ kó o wo ẹni yẹn ní tààràtà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wàá kàn wò ó fẹ̀rẹ̀ ni. Bí o bá ń gbójú sókè wo ẹni yẹn látìgbàdégbà, wàá lè mọ ìṣarasíhùwà rẹ̀ nípa ohun tí ò ń kà.
Bí ìtìjú kò bá kọ́kọ́ jẹ́ kó o máa wojú ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Bí o bá ti ń gbìyànjú ẹ̀ déédéé, á di ohun tó mọ́ ẹ lára láti máa wojú ẹni bó ṣe yẹ, ó sì lè jẹ́ kí o túbọ̀ lè báni fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà tó jíire.
Nígbà Tí O Bá Ń Sọ Àsọyé. Bíbélì sọ fún wa pé kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè, “ó . . . gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.” (Lúùkù 6:20) Kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀. Bí o bá fẹ́ sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ kan, kọjú sí wọn kí o sì dúró fún ìgbà díẹ̀ kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Lọ́pọ̀ ibi, èyí á béèrè pé kí o wo ojú àwọn kan nínú àwùjọ. Dídúró fún ìgbà díẹ̀ yìí lè jẹ́ kí o borí ìbẹ̀rù tó ṣeé ṣe kí o ní nígbà tó o bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Yóò tún jẹ́ kí àwùjọ lè tipa ìṣarasíhùwà rẹ mọ irú ọ̀rọ̀ tí wọn ń retí láti gbọ́. Láfikún sí i, ṣíṣe tí o bá ṣe èyí yóò jẹ́ kí àwùjọ fara balẹ̀ láti lè fetí sí ọ.
Nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀, máa wo àwùjọ. Má kàn máa wo gbogbo àwùjọ fìrì láti apá kan sí ìkejì. Gbìyànjú láti máa wo ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú àwùjọ lójú. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nínú gbogbo ẹ̀yà ni wọ́n ti máa ń retí pé kí ẹni tó ń bá àwùjọ èèyàn sọ̀rọ̀ máa wo ojú àwùjọ dé ìwọ̀n àyè kan.
Wíwo ojú àwọn olùgbọ́ rẹ ju wíwulẹ̀ yíjú wò wọ́n láti apá kan sí apá kejì. Ńṣe ni kó o wo ojú ẹnì kan nínú àwùjọ lọ́nà tó fọ̀wọ̀ fúnni, bí ó bá sì yẹ bẹ́ẹ̀, kí o sọ odindi gbólóhùn kan jáde sí irú ẹni bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, wo ojú ẹlòmíràn, kí o sì tún sọ gbólóhùn kan tàbí méjì sí ẹni yẹn pẹ̀lú. Má ṣe wo ẹnì kan fún ìgbà pípẹ́ débi tí ojú á fi bẹ̀rẹ̀ sí tì í, má sì ṣe máa dá kìkì àwọn díẹ̀ wò nínú gbogbo àwùjọ. Máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ láti wo olúkúlùkù tó wà nínú àwùjọ, ṣùgbọ́n bí o bá darí ọ̀rọ̀ sí ẹnì kan, bá ẹni yẹn sọ̀rọ̀ ní ti gidi kí o sì ṣàkíyèsí ìṣesí rẹ̀ kí o tó tún kọjú sí ẹlòmíràn.
Orí tábìlì ìbánisọ̀rọ̀ ni kí o fi ìwé tí o fi ń sọ̀rọ̀ sí, tàbí kí ó wà ní ọwọ́ rẹ tàbí nínú Bíbélì rẹ, kí ó lè jẹ́ pé tí o bá fẹ́ bojú wò ó, ẹyinjú nìkan ni wàá kàn máa yí tí wàá sì ti rí i. Bó bá di dandan pé kí o tẹ orí rẹ kí o tó lè rí ìwé tí o fi ń sọ̀rọ̀, kò ní ṣeé ṣe fún ọ láti wojú àwùjọ dáadáa. Ó yẹ kí o ronú nípa bí wàá ṣe máa wo ìwé tí o fi ń sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́ tó àti àkókò náà gan-an tó yẹ kí o wò ó. Bí o bá ń wo ìwé tí o fi ń sọ̀rọ̀ nígbà tí o bá ń mẹ́nu kan àwọn kókó pàtàkì, o ò ní lè rí ìṣesí àwọn olùgbọ́ rẹ, yàtọ̀ sí ìyẹn ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ kò tún ní lágbára tó bó ṣe yẹ. Bákan náà, bí o bá ń wo ìwé tí o fi ń sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́ jù, o ò ní lè wo ojú àwùjọ dáadáa.
Nígbà tí o bá ju bọ́ọ̀lù sí ẹnì kan, wàá wò ó bóyá ẹni yẹn mú un tàbí kò mú un. Kókó kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ ohun tí ò ń “jù” sí àwùjọ. Ìṣesí wọn lè fi hàn pé wọ́n “mú un,” bóyá kí wọ́n mi orí, kí wọ́n rẹ́rìn-ín músẹ́, tàbí kí wọ́n tẹjú mọ́ ọ. Bí o bá ń wo ojú wọn dáadáa, èyí á jẹ́ kí o lè rí i dájú pé wọ́n ń “mú” kókó ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ.
Bí wọ́n bá yàn ọ́ láti kàwé fún ìjọ, ṣé ó yẹ kí o gbìyànjú láti máa wo àwùjọ nígbà tí o bá ń kà á? Bí o bá ń ka Bíbélì tí àwùjọ sì ń fojú bá a lọ nínú tiwọn, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn kò ní mọ̀ bóyá o gbójú sókè tàbí o kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n wíwo ojú àwùjọ lè mú kí ìwé tí ò ń kà tani jí nítorí á jẹ́ kí o lè mọ ìṣarasíhùwà wọn nípa ohun tí ò ń kà. Bí àwọn kan bá sì wà nínú àwùjọ tí wọn kò wo Bíbélì wọn bóyá tí ọkàn wọn tilẹ̀ ń ro nǹkan mìíràn, bí ojú wọn bá ṣe pẹ̀kí pẹ̀lú ti olùbánisọ̀rọ̀, ìyẹn lè pe àfiyèsí wọn padà sí Bíbélì tí ò ń kà. Àmọ́ ṣá o, kí o máa gbójú sókè fìrí ni o, kí o má sì ṣe é lọ́nà tí yóò mú kí o ṣi ìwé kà. Láti ṣe èyí, ohun tó dára jù lọ ni pé kí o gbé Bíbélì rẹ dání kí o sì gbórí sókè, kí o má tẹ orí wálẹ̀.
Nígbà mìíràn, a máa ń fún àwọn alàgbà ní iṣẹ́ ní àpéjọ láti bójú tó àsọyé tó jẹ́ ìwé kíkà. Ó gba ìrírí, ìmúrasílẹ̀ dáadáa, àti ìfidánrawò púpọ̀ láti lè kà á bó ṣe yẹ. A mọ̀ pé iṣẹ́ tó jẹ́ ìwé kíkà kì í jẹ́ kí èèyàn lè fi bẹ́ẹ̀ wojú àwùjọ. Ṣùgbọ́n bí olùbánisọ̀rọ̀ bá ti múra sílẹ̀ dáadáa, ó yẹ kí ó lè máa wo àwọn olùgbọ́ rẹ̀ látìgbàdégbà tí ojú rẹ̀ kò sì ní tàsé ibi tí ò ń kà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kí àwùjọ lè máa fiyè sí i, yóò sì jẹ́ kí wọ́n jàǹfààní ní kíkún látinú ìtọ́ni tẹ̀mí tó ń fúnni.