Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Wíwo Ojú Wọn
1 Nígbà tá a bá ń wàásù níbi térò máa ń pọ̀ sí tàbí láti ilé dé ilé, ojú wa sábà máa ń ṣe mẹ́rin pẹ̀lú àwọn èèyàn ká tó bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ̀rọ̀. Láàárín àkókò kúkúrú yẹn, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti fi bí wọ́n ṣe ṣojú mọ̀ bóyá wọ́n fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, a tiẹ̀ tún lè mọ̀ bóyá wọ́n ní nǹkan kan lọ́kàn tó ń dà wọ́n láàmú. Àwọn fúnra wọn sì lè fòye mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa wa. Ohun tí obìnrin kan sọ rèé nípa ìbẹ̀wò tí Ẹlẹ́rìí kan ṣe sọ́dọ̀ rẹ̀: “Ohun tí mo máa ń rántí nípa ẹ̀rín músẹ́ rẹ̀ ni ìbàlẹ̀ ọkàn tó ní. Ara mi ti wà lọ́nà láti gbọ́ ohunkóhun tó fẹ́ sọ.” Èyí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún obìnrin náà láti tẹ́tí sílẹ̀ gbọ́ ìhìn rere náà.
2 Wíwo ojú àwọn èèyàn ni ọ̀nà tó dáa jù láti bẹ̀rẹ̀ ìwàásù nígbà tá a bá ń ṣe ìjẹ́rìí òpópónà tàbí nígbà tá a bá ń jẹ́rìí níbi táwọn èèyàn sábà máa ń pọ̀ sí. Arákùnrin kan máa ń jẹ́ kójú ẹ̀ ṣe mẹ́rin pẹ̀lú tàwọn èèyàn tí wọ́n bá fẹ́ rìn pàdé ẹ̀. Bí ojú wọ́n bá ti ṣe mẹ́rin, á rẹ́rìn-ín músẹ́, á sì fi ìwé ìròyìn lọ̀ wọ́n. Nípa lílo ọ̀nà yìí láti gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìjíròrò tó gbádùn mọ́ ọn, ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde ló sì ti fi sóde.
3 Fi Òye Mọ Èrò Àwọn Èèyàn: Bá a bá ń wo ojú àwọn èèyàn, á ràn wá lọ́wọ́ láti mọ èrò wọn. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ ò bá lóye ohun tá à ń sọ tàbí tí ò fẹ́ gba ohun tá a sọ gbọ́, ó máa hàn lójú ẹ̀. Bí ọwọ́ ẹ̀ bá dí tàbí tó dà bíi pé ara ẹ̀ ò balẹ̀, a máa mọ̀ bá a bá wo ojú ẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, a ó lè mú kí ọ̀rọ̀ wa bá ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ mu tàbí ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa ṣe ṣókí bó bá ṣe yẹ. Ọ̀nà tó dáa gan-an láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún ni pé ká máa kíyè sí ìṣesí wọn.
4 Sísọ̀rọ̀ Látọkànwá Pẹ̀lú Ìdánilójú: Ọ̀pọ̀ àṣà ìbílẹ̀ ló gbà pé ẹní bá ń wojú ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀, ló ń sọ̀rọ̀ látọkànwá. Wo ohun tí Jésù ṣe nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í pé: “Ta ni a lè gbà là ní ti tòótọ́?” Bíbélì ròyìn pé: “Ní wíwò wọ́n lójú, Jésù wí fún wọn pé: ‘Lọ́dọ̀ ènìyàn, èyí kò ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.’” (Mát. 19:25, 26) Kò síyè méjì pé ìdánilójú tó hàn lójú Jésù túbọ̀ mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ rinlẹ̀. Nítorí náà, bí àwa náà bá ń wo ojú àwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀, á ṣeé ṣe fún wa láti máa tan ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kálẹ̀ látọkànwá pẹ̀lú ìdánilójú.—2 Kọ́r. 2:17; 1 Tẹs. 1:5.