Ẹ̀KỌ́ 32
Fífi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀
BÍ OLÙBÁNISỌ̀RỌ̀ bá fi ìdánilójú sọ̀rọ̀, àwọn èèyàn á rí i pé ó gba ohun tó ń sọ gbọ́ dáadáa. Irú ìdánilójú tí à ń wí yìí hàn gbangba nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe. Ó kọ̀wé sí àwọn tó di onígbàgbọ́ ní ìlú Tẹsalóníkà pé: “Ìhìn rere tí a ń wàásù kò fara hàn láàárín yín nínú ọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n nínú . . . ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára.” (1 Tẹs. 1:5) Ìdánilójú yẹn hàn gbangba nínú ọ̀nà tí ò ń gbà sọ̀rọ̀ àti irú ìgbésí ayé tí ó gbé. Ó yẹ kí ọ̀nà tí a gbà ń ṣàlàyé òótọ́ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì fi hàn pé ó dá àwa náà lójú hán-únhán-ún pẹ̀lú.
Fífi ìdánilójú sọ̀rọ̀ kì í ṣe ohun kan náà pẹ̀lú jíjẹ́ ẹni tó jẹ́ pé èrò tirẹ̀ nìkan ló máa ń yé e, jíjẹ́ alákatakítí, tàbí afọ́nnu. Kàkà bẹ́ẹ̀, tí ẹni tó ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ dá òun lójú bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ńṣe ló máa ń sọ ọ́ lọ́nà tí yóò fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára.—Héb. 11:1.
Àkókò Téèyàn Ní Láti Fi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀. Nígbà tí o bá wà lóde ẹ̀rí, ó ṣe pàtàkì pé kí o fi ìdánilójú sọ̀rọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, bí àwọn èèyàn ṣe ń kíyè sí ọ̀rọ̀ rẹ ni wọ́n tún ń kíyè sí ọ̀nà tí o gbà ń sọ ọ́ pẹ̀lú. Wọ́n máa ń fi òye mọ bí ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ ṣe rí gan-an lára ìwọ fúnra rẹ. Fífi ìdánilójú sọ̀rọ̀ lè jẹ́ kó hàn gbangba sí àwọn èèyàn ju bí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ṣe lè ṣe lọ pé ohun tó wúlò gidigidi lò ń sọ.
Ó tún ṣe pàtàkì bákan náà pé ká fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ bí a bá ń bá àwùjọ àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa sọ̀rọ̀. Ńṣe ni àpọ́sítélì Pétérù kọ ìwé onímìísí tó kọ́kọ́ kọ láti fi fún àwọn ará “ní ìṣírí àti ìjẹ́rìí àfi-taratara-ṣe pé èyí ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tòótọ́ ti Ọlọ́run.” Nínú ìwé tí ó kọ yìí, ó gba àwọn ará níyànjú pé: “Ẹ dúró gbọn-in gbọn-in.” (1 Pét. 5:12) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Róòmù, ó fi ìdánilójú sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ lọ́nà tó ṣe wọ́n láǹfààní. Ó kọ̀wé pé: “Mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 8:38, 39) Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé ìgbaniníyànjú nípa bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé ká wàásù fún àwọn èèyàn, ìtara rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ yìí sì fi hàn gbangba pé ó dá a lójú pé iṣẹ́ ìwàásù yìí ṣe pàtàkì. (Ìṣe 20:18-21; Róòmù 10:9, 13-15) Ó yẹ kí àwọn Kristẹni alàgbà lóde òní fi irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀ hàn bí wọ́n ṣe ń kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Nígbà tí àwọn òbí bá ń bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí, yálà lákòókò ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí ní àwọn ìgbà mìíràn, wọ́n ní láti sọ ọ́ lọ́nà tó ń fi hàn pé ohun tí wọ́n ń sọ dá wọn lójú. Ìyẹn ń béèrè pé kí àwọn òbí fúnra wọn fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn ọ̀nà rẹ̀ dé inú ọkàn tiwọn alára. Ìgbà yẹn ni wọ́n tó lè bá ọmọ wọn sọ̀rọ̀ látọkànwá lọ́nà tí yóò fi hàn pé ohun tí wọ́n ń sọ dá wọn lójú, ‘nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.’ (Lúùkù 6:45; Diu. 6:5-7) Bí àwọn òbí bá ní irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀ yóò sún wọn láti jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú níní ‘ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè kankan.’—2 Tím. 1:5.
Ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí o ṣàlàyé ara rẹ lọ́nà tó fi hàn pé ohun tí ò ń sọ dá ọ lójú nígbà tí àwọn èèyàn bá dojú ìbéèrè kọ ọ́ nípa ohun tí o gbà gbọ́. Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yín, tàbí olùkọ́ yín, tàbí ẹni tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lè sọ fún ọ pé ó ya òun lẹ́nu pé o kò bá àwọn ṣe irú ayẹyẹ kan. Fífi àlàyé tó bọ́gbọ́n mu tó sì dájú dáhùn lè mú kí ó bọ̀wọ̀ fún dídúró tí o dúró lórí ohun tí Bíbélì sọ. Ká wá ní ńṣe ni ẹnì kan ń gbìyànjú láti tì ọ́ hu ìwà àìtọ́ kan, bóyá ìwà àìṣòótọ́, ìkóògùnjẹ tàbí ìṣekúṣe ńkọ́? Ó ṣe pàtàkì pé kí o jẹ́ kí ó yé e pé o kò ní hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ láé, àti pé kò sí ohun tó lè sọ tí yóò mú ọ gbà láti hu irú ìwà yẹn. Èyí béèrè pé kí o sọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò fi hàn pé ohun tó ò ń sọ dá ọ lójú nígbà tí o bá ń kọ ohun tí onítọ̀hún ní kí o ṣe. Nígbà tí Jósẹ́fù ń kọ ìṣekúṣe tí aya Pọ́tífárì fi lọ̀ ọ́, ó fi àìyẹhùn sọ pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” Nígbà tí obìnrin yìí sọ pé àfi kí ó bá òun sùn sẹ́, ó sá jáde nínú ilé yẹn.—Jẹ́n. 39:9, 12.
Bí A Ṣe Ń Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Dáni Lójú. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni ọ̀rọ̀ tí o lò máa ń ṣe láti fi bí ohun tí ò ń sọ ṣe dá ọ lójú tó hàn. Ọ̀pọ̀ ìgbà tí Jésù sọ gbólóhùn pàtàkì kan ló kọ́kọ́ sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún ọ.” (Jòh. 3:3, 5, 11; 5:19, 24, 25) Pọ́ọ̀lù fi bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dá a lójú tó hàn nípa lílo àwọn gbólóhùn bíi “Mo gbà gbọ́ dájú,” “Mo mọ̀, mo sì gbà nínú Jésù Olúwa,” àti “Èmi ń sọ òtítọ́, èmi kò purọ́.” (Róòmù 8:38; 14:14; 1 Tím. 2:7) Nígbà mìíràn, tí ọ̀rọ̀ bá kan ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Jèhófà, Jèhófà máa ń mí sí àwọn wòlíì rẹ̀ láti sọ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ ọ̀hún dájú, bíi “Yóò ṣẹ láìkùnà.” (Háb. 2:3) Nígbà tí o bá ń tọ́ka sí irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀, o lè lo irú gbólóhùn kan náà. Bí ó bá jẹ́ pé Jèhófà lo gbẹ́kẹ̀ lé, tí o kò gbẹ́kẹ̀ lé ara rẹ, tí o sì ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ̀rọ̀ fún àwọn èèyàn, ńṣe làwọn gbólóhùn tó ń fi irú ìdálójú bẹ́ẹ̀ hàn yóò jẹ́ ẹ̀rí pé ìgbàgbọ́ rẹ lágbára.
Ìtara ọkàn àti bí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe dún ketekete tún lè fi hàn pé ohun tí ò ń sọ dá ọ lójú pẹ̀lú. Ìrísí ojú rẹ àti bí o ṣe fi ọ̀rọ̀ àti ara ṣàpèjúwe máa ń pa pọ̀ mú kí èyí ṣeé ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí kálukú ṣe máa ń ṣe é yàtọ̀ síra. Bí o bá tiẹ̀ jẹ́ onítìjú ẹ̀dá tàbí olóhùn dídẹ̀, bó bá ti lè dá ọ lójú pé òótọ́ ọ̀rọ̀ lò ń sọ àti pé ó yẹ kí àwọn èèyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀hún, ìdánilójú yẹn yóò hàn gbangba.
Àmọ́ ṣá o, a ní láti rí i pé ọ̀nàkọnà tí a bá gbà sọ ohun tó dá wa lójú jẹ́ bí ọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣe rí lára wa lóòótọ́. Bí àwọn èèyàn bá lọ rí i pé ńṣe là ń díbọ́n dípò ká sọ̀rọ̀ látọkànwá, wọn á gbà pé ohun tí à ń sọ kò fi bẹ́ẹ̀ wúlò. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tó ti ṣe pàtàkì jù ni pé kí o má ṣe díbọ́n lọ́nàkọnà. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé wàá túbọ̀ gbóhùn sókè kí ó túbọ̀ dún ketekete ju bí o ṣe máa ń sọ̀rọ̀ lọ, ó sinmi lórí bí àwùjọ rẹ bá ṣe pọ̀ tó. Ṣùgbọ́n ohun tí o ní láti fi sọ́kàn ni pé o fẹ́ fi òótọ́ inú sọ̀rọ̀, o sì fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà tí o gbà ń sọ̀rọ̀.
Àwọn Ohun Tó Ń Ranni Lọ́wọ́ Láti Fi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe rí lára rẹ ni yóò pinnu bí o ṣe máa fi ìdánilójú sọ ọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí o múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ dáadáa. Tí o bá kàn da ọ̀rọ̀ yẹn kọ látinú ìwé tí o sì wá ń tún un sọ bí ayékòótọ́, ìyẹn nìkan kò tó. Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ yẹn yé ọ yékéyéké, kí o sì lè sọ ọ́ lọ́rọ̀ ara rẹ. Ó ní láti dá ìwọ alára lójú pé òótọ́ ọ̀rọ̀ lò ń sọ àti pé ó wúlò fún àwùjọ rẹ. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, bí o bá ń múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀, o ní láti fi ipò ìgbésí ayé àwọn olùgbọ́ rẹ, ohun tí wọ́n lè ti mọ̀ nípa kókó tí o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí, tàbí bí ó ṣe lè rí lára wọn sọ́kàn.
Bí ọ̀rọ̀ wa ṣe dá wa lójú máa ń tètè hàn sí àwọn èèyàn tí ọ̀rọ̀ bá yọ̀ mọ́ wa lẹ́nu bí a ṣe ń sọ ọ́. Nítorí náà, yàtọ̀ sí pé kí o múra ọ̀rọ̀ tó jíire sílẹ̀, tún múra ọ̀nà tó o máa gbà sọ ọ́ dáadáa pẹ̀lú. Fara balẹ̀ kíyè sí àwọn apá tó ń béèrè pé kí o túbọ̀ fi ìtara ọkàn sọ̀rọ̀ nínú iṣẹ́ rẹ kí o lè sọ ọ́ láìgbára lé àkọsílẹ̀ ìránnilétí rẹ. Kí o sì tún rántí láti gbàdúrà pé kí Jèhófà bù kún ìsapá rẹ. Nípa báyìí, wàá lè ‘máyà le nípasẹ̀ Ọlọ́run wa’ láti sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa fi hàn pé ó dá ọ lójú hán-únhán-ún pé òótọ́ ọ̀rọ̀ lò ń sọ àti pé ọ̀rọ̀ yẹn ṣe pàtàkì gan-an.—1 Tẹs. 2:2.