ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/00 ojú ìwé 3-6
  • Fífi Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Wàásù Ìhìn Rere Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Wàásù Ìhìn Rere Náà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ẹ Dúró Lọ́nà Pípé Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ẹ̀yin Òbí​—Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè “Di Ọlọ́gbọ́n fún Ìgbàlà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Jẹ́ Kí Òtítọ́ Tó O Gbà Gbọ́ Dá Ẹ Lójú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 2/00 ojú ìwé 3-6

Fífi Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Wàásù Ìhìn Rere Náà

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní, Jésù Kristi gbé iṣẹ́ kan fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, iṣẹ́ náà ni láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà àti láti “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mát. 24:14; 28:19, 20) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fi ìtọ́ni yìí ṣeré rárá, ìyẹn ló fi jẹ́ pé bí ọ̀rúndún ogún yìí ti ń lọ sópin, iye àwọn Kristẹni tó jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ àwọn ará wa ti ròkè lálá, ó ti lé ní mílíọ̀nù márùn-ún lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [5,900,000] ọmọ ẹ̀yìn, ní igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [234] ilẹ̀. Ṣe ni a kàn ń hó ìhó ìyìn ńlá sí Baba wa ọ̀run!

2 A ti wọnú ọ̀rúndún kọkànlélógún báyìí. Ńṣe ni Elénìní wa ń ta onírúurú ọgbọ́n, tó ń wá ọ̀nà láti ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ wíwàásù nípa Ìjọba náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì táà ń ṣe. Ó máa ń fẹ́ fi wàhálà oríṣiríṣi tó kún inú ètò àwọn nǹkan yìí pín ọkàn wa níyà, ó ń fẹ́ kí nǹkan wọ̀nyí gbàkókò wa, kí wọ́n sì tán wa lókun ní àfikún sí onírúurú ìdààmú àti àníyàn tí kò tóó gbé pọ́n. Kàkà tí a ó fi gba ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí láyè láti máa pinnu ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé fún wa, a ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pinnu ohun tó gbọ́dọ̀ gbapò iwájú jù lọ, ìyẹn ni, ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà. (Róòmù 12:2) Èyí túmọ̀ sí ṣíṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ká máa ‘wàásù ọ̀rọ̀ náà ní àsìkò tí ó rọgbọ àti ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú, kí a sì ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún.’—2 Tím. 4:2, 5.

3 Ní Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀: Àwọn Kristẹni ní láti “dúró lọ́nà tí ó pé . . . àti pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run.” (Kól. 4:12) Gbólóhùn náà, “ìdálójú ìgbàgbọ́,” túmọ̀ sí “ohun téèyàn gbà gbọ́ tọkàntọkàn; kéèyàn ní ìdánilójú nǹkan.” Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run dájú, a sì tún gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé àkókò òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bùṣe. Ìgbàgbọ́ wa gbọ́dọ̀ gbóná bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó sọ pé “ní ti tòótọ́, [ìhìn rere ni] agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà sí gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́.”—Róòmù 1:16.

4 Èṣù máa ń lo àwọn olubi àtàwọn afàwọ̀rajà, tí àwọn alára ti ṣìnà, láti darí àwọn èèyàn, kí wọ́n sì kó wọn ṣìnà. (2 Tím. 3:13) Níwọ̀n bí a ti kì wá nílọ̀ nípa èyí tẹ́lẹ̀, a ń ṣiṣẹ́ lórí mímú ìdánilójú wa lágbára sí i pé àwa la ń sọ òtítọ́. Kàkà tí a ó fi jẹ́ kí àwọn àníyàn ìgbésí ayé paná ìtara wa, a ní láti máa bá a lọ ní fífi ire Ìjọba náà sípò àkọ́kọ́. (Mát. 6:33, 34) Kò sì yẹ kó jẹ́ pé níbi tọ́jọ́ dé yìí, ká tún máa ronú pé òpin ètò àwọn nǹkan yìí ṣì jìn. Ó ti dé tán o. (1 Pét. 4:7) Lóòótọ́ ni a lè máa lérò pé ìhìn rere náà ò kúkú fi bẹ́ẹ̀ tẹ̀ síwájú mọ́ láwọn ilẹ̀ kan nítorí pé a ti jẹ́rìí kúnnákúnná níbẹ̀, bó tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ ìkìlọ̀ náà gbọ́dọ̀ máa bá a lọ.—Ìsík. 33:7-9.

5 Àwọn ìbéèrè pàtàkì níbi tọ́jọ́ dé yìí ni pé: ‘Ǹjẹ́ mo ń fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wa lọ́wọ́, èyíinì ni láti máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn? Nígbà tí mo bá ń wàásù ìhìn rere náà, ǹjẹ́ mo máa ń fi hàn pé ọ̀ràn Ìjọba náà dá mi lójú tádàá? Ǹjẹ́ mo ti pinnu láti ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ń gba ẹ̀mí là yìí?’ Báa bá mọ bí òpin ti sún mọ́lé tó, a ò ní gbàgbéra rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni a ó gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ táa gbé lé wa lọ́wọ́. Nípa ṣíṣe èyí la fi lè gba ara wa àtàwọn tó ń gbọ́ wa là. (1 Tím. 4:16) Báwo ni gbogbo wa ṣe lè fẹsẹ̀ ìgbàgbọ́ wa múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́?

6 Fìwà Jọ Àwọn Ará Tẹsalóníkà: Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún ronú lọ sórí iṣẹ́ àṣekára táwọn ará ní Tẹsalóníkà ṣe, ó kọ̀wé sí wọn pé: “Ìhìn rere tí a ń wàásù kò fara hàn láàárín yín nínú ọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n nínú agbára pẹ̀lú àti nínú ẹ̀mí mímọ́ àti ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ irú ènìyàn tí a wá jẹ́ sí yín nítorí yín; ẹ sì di aláfarawé wa àti ti Olúwa, níwọ̀n bí ẹ ti tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ náà lábẹ́ ìpọ́njú púpọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ẹ̀mí mímọ́.” (1 Tẹs. 1:5, 6) Bẹ́ẹ̀ ni, Pọ́ọ̀lù yin ìjọ tó wà ní Tẹsalóníkà nítorí pé láìfi ìpọ́njú rẹpẹtẹ pè, wọ́n ń fi ìtara àti ìgbàgbọ́ tó lágbára wàásù nìṣó. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe fún wọn? Dé àyè kan, ìtara àti ìgbàgbọ́ tó lágbára tí wọ́n rí i pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ ní, ló ní ipa rere lórí wọn. Lọ́nà wo?

7 Ìgbésí ayé Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó ń bá a rìnrìn àjò jẹ́rìí sí i pé ẹ̀mí Ọlọ́run wà lára wọn àti pé tọkàntọkàn ni wọ́n gba ohun tí wọ́n ń wàásù rẹ̀ gbọ́. Kó tó di pé Pọ́ọ̀lù àti Sílà dé Tẹsalóníkà, ojú wọn rí màbo ní Fílípì. Láìdúró gbẹ́jọ́, ńṣe ni wọ́n lù wọ́n, tí wọ́n sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, tí wọ́n sì ti ẹsẹ̀ wọn bọnú àbà. Bó ti wù kó rí, híhàn tí wọ́n hàn wọ́n léèmọ̀ yìí ò paná ìtara tí wọ́n ní fún ìhìn rere náà. Ọlọ́run tú wọn sílẹ̀, ó sì mú kí onítúbú náà àti agboolé rẹ̀ di onígbàgbọ́, ó sì ṣe ọ̀nà bí àwọn arákùnrin wọ̀nyí yóò ṣe máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lọ.—Ìṣe 16:19-34.

8 Agbára ẹ̀mí Ọlọ́run ni Pọ́ọ̀lù fi gúnlẹ̀ láyọ̀ sí Tẹsalóníkà. Níbẹ̀, ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣiṣẹ́ àṣelàágùn láti gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, ó sì fi torí-tọrùn ṣe iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ará Tẹsalóníkà lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Gbogbo àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ láti polongo ìhìn rere ló nawọ́ gán. (1 Tẹs. 2:9) Ìdánilójú tí Pọ́ọ̀lù fi wàásù ní ipa tó lágbára lórí àwọn èèyàn àdúgbò náà gan-an, ipa náà pọ̀ débi pé àwọn kan nínú wọ́n jáwọ́ nínú bíbọ̀rìṣà, wọ́n sì di ìránṣẹ́ Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́.—1 Tẹs. 1:8-10.

9 Inúnibíni kò mú káwọn onígbàgbọ́ tuntun ṣíwọ́ wíwàásù ìhìn rere náà. Nítorí pé ìgbàgbọ́ táwọn ará Tẹsalóníkà ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ń gún wọn ní kẹ́sẹ́, tó sì dá wọn lójú hán-únhán-ún pé ìbùkún ayérayé yóò jẹ́ tiwọn, ńṣe ni ọkàn wọn ń sún wọn láti pòkìkí òtítọ́ tí wọ́n ti fi taratara tẹ́wọ́ gbà. Ìgbòkègbodò ìjọ yẹn pọ̀ débi pé ìròyìn nípa ìgbàgbọ́ àti ìtara wọn tàn dé àwọn ibi yòókù ní Makedóníà, àní títí dé Ákáyà pàápàá. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé kó tó di pé Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sáwọn ará Tẹsalóníkà ni ìròyìn nípa iṣẹ́ rere wọn ti dé etígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn. (1 Tẹs. 1:7) Àpẹẹrẹ yìí mà kúkú dáa o!

10 Kí Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti Fáwọn Èèyàn Máa Sún Wa Ṣiṣẹ́: Báwo làwa náà ṣe lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára bíi tàwọn ará Tẹsalóníkà, nígbà táa bá ń wàásù ìhìn rere lónìí? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa wọn pé: “Láìdábọ̀ ni a ń fi iṣẹ́ ìṣòtítọ́ yín sọ́kàn àti akitiyan tí ẹ ń ṣe nítorí ìfẹ́.” (1 Tẹs. 1:3, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, New World Translation Reference Bible) Ó hàn gbangba pé wọ́n ní ìfẹ́ àtọkànwá jíjinlẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run àti fáwọn èèyàn tí wọ́n ń wàásù fún. Ìfẹ́ kan náà yìí ló sún Pọ́ọ̀lù àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti fún àwọn ará Tẹsalóníkà ní, “kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn [àwọn fúnra wọn] pẹ̀lú.”—1 Tẹs. 2:8.

11 Bákan náà, ìfẹ́ jíjinlẹ̀ táa ní fún Jèhófà àti fún ọmọnìkejì wa ló ń sún wa láti fẹ́ ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà nínú iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run ti gbé lé wa lọ́wọ́. Táa bá ní irú ìfẹ́ yẹn, a ó mọ̀ pé iṣẹ́ títan ìhìn rere kálẹ̀ yìí, iṣẹ tiwa ni, ẹrù iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi fún wa ni. Nípa ríronú lọ́nà rere, àní lọ́nà tó fi ìmọrírì hàn, lórí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa nípa títọ́ wa sọ́nà “ìyè tòótọ́,” a óò máa sún wa láti sọ àwọn àgbàyanu òtítọ́ kan náà táa gbà gbọ́ tọkàntọkàn fáwọn èèyàn.—1 Tím. 6:19.

12 Bí a ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà lójú méjèèjì, ńṣe ló yẹ kí ìfẹ́ táa ní fún Jèhófà àti fáwọn èèyàn máa pọ̀ sí i. Bó bá sì ń pọ̀ sí i lóòótọ́, ọkàn wa yóò sún wa láti koná mọ́ ìsapá wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé, a ó sì túbọ̀ máa lọ́wọ́ nínú gbogbo onírúurú ọ̀nà ìjẹ́rìí táa bá ní àǹfààní rẹ̀. A ó lo gbogbo àǹfààní táa bá ní láti jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà fáwọn ẹbí wa, fáwọn ará àdúgbò wa, àti fáwọn ojúlùmọ̀ wa. Bí ọ̀pọ̀ jù lọ tiẹ̀ ń kọ etí ikún sí ìhìn rere táa ń wàásù, táwọn kan sì ń wá báwọn ṣe lè bẹ́gi dínà iṣẹ́ ìpòkìkí Ìjọba náà, síbẹ̀síbẹ̀, ayọ̀ kún inú wa. Èé ṣe? Nítorí a mọ̀ pé a ti sa gbogbo ipá wa láti jẹ́rìí nípa Ìjọba náà, a sì ti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jèrè ìgbàlà. Jèhófà yóò sì bù kún ìsapá wa báa ti ń wá àwọn tó ní àyà ìgbàṣe kiri. Kódà nígbà tí ìdààmú ìgbésí ayé bá dé bá wa, tí Sátánì sì ń wá ọ̀nà láti pa wá lẹ́kún, ìgbàgbọ́ wa ṣì máa ń lágbára, ìtara wa láti jẹ́rìí fáwọn èèyàn kì í sì í jó rẹ̀yìn. Bí gbogbo wa bá ń ṣe ipa tiwa, ìyọrísí rẹ̀ ni pé a óò ní àwọn ìjọ tó dúró dáadáa, tó kún fún àwọn onítara, gẹ́gẹ́ bí ìjọ Tẹsalóníkà.

13 Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Rárá Lábẹ́ Àdánwò: Ìgbàgbọ́ tún ṣe kókó nígbà táa bá dojú kọ àdánwò. (1 Pét. 1:6, 7) Jésù là á mọ́lẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé bí wọ́n bá ń tọ òun lẹ́yìn, wọn yóò di “ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:9) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù àti Sílà nìyẹn nílùú Fílípì. Ìwé Ìṣe orí kẹrìndínlógún sọ pé wọ́n ju Pọ́ọ̀lù àti Sílà sí ẹ̀wọ̀n inú lọ́hùn-ún, wọ́n sì ti ẹsẹ̀ wọn bọnú àbà. Ohun tí wọ́n sábà máa ń pè lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí gbàgede agboolé tàbí ìloro tí wọ́n kọ́ àwọn àtìmọ́lé kótópó-kótópó yí ká rẹ̀, níbi tí ìmọ́lẹ̀ àti afẹ́fẹ́ ti lè ráyè wọlé. Àmọ́ ṣe ni ẹ̀wọ̀n inú lọ́hùn-ún ṣókùnkùn biribiri, ìwọ̀nba afẹ́fẹ́ ló sì ń ráyè wọlé. Pọ́ọ̀lù àti Sílà ní láti fara da òkùnkùn, ooru, àti òórùn tó ń bù tìì nínú àhámọ́ burúkú yìí. Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ara yóò ti máa ro wọ́n burúkú-burúkú nígbà tí wọ́n ti ti ẹsẹ̀ wọn sínú àbà fún ọ̀pọ̀ wákàtí pẹ̀lú ọgbẹ́ yánnayànna tó ń ṣẹ̀jẹ̀, tí kòbókò ti dá sí gbogbo ẹ̀yìn wọn?

14 Láìfi gbogbo àdánwò wọ̀nyí pè, Pọ́ọ̀lù àti Sílà dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ àtọkànwá, èyí sì fún wọn lókun láti sin Jèhófà láìka àdánwò náà sí. Ẹsẹ ìkẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní orí kẹrìndínlógún ròyìn ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ pé Pọ́ọ̀lù àti Sílà “ń gbàdúrà, wọ́n sì ń fi orin yin Ọlọ́run.” Àní, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀wọ̀n inú lọ́hùn-ún ni wọ́n wà, ó dá wọn lójú gbangba pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn, ìyẹn ni wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí kọrin sókè tó bẹ́ẹ̀ táwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù fi ń gbóhùn wọn! A gbọ́dọ̀ ní irú ìgbàgbọ́ yẹn lónìí nígbà táa bá ń rí ìdánwò ìgbàgbọ́.

15 Àwọn àdánwò tí Èṣù ń gbé kò wá kò níye. Tàwọn kan lè jẹ́ inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn ẹbí. Àìmọye àwọn ará wa lọ̀ràn òfin sì ti dá ìṣòro sílẹ̀ fún. A lè dojú kọ àtakò látọ̀dọ̀ àwọn apẹ̀yìndà. Ìṣòro àìrówóná àti àníyàn àtijẹ àtimu kò tún gbẹ́yìn. Àwọn ọmọléèwé ń dojú kọ ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Báwo la ṣe lè borí àdánwò wọ̀nyí? Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́?

16 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a gbọ́dọ̀ ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà wà ní ẹ̀wọ̀n inú lọ́hùn-ún, wọn ò lo àkókò yẹn fún ríráhùn nípa ohun tójú wọ́n ń rí tàbí kí wọ́n máa ronú pé àwọn ló wá dẹni tí ìyà ń jẹ báyìí. Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń forin yìn ín. Èé ṣe? Nítorí pé wọ́n ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Baba wọn ọ̀run. Wọ́n mọ̀ pé tìtorí òdodo làwọn ṣe ń jìyà, wọ́n sì mọ̀ pé ìgbàlà wọn ń bẹ lọ́wọ́ Jèhófà.—Sm. 3:8.

17 Tí àwa náà bá dojú kọ àdánwò lónìí, ojú Jèhófà la gbọ́dọ̀ máa wò. Pọ́ọ̀lù rọ àwa táa jẹ́ Kristẹni pé ‘kí a máa sọ àwọn ohun tí a ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà wa àti agbára èrò orí wa.’ (Fílí. 4:6, 7) Ẹ wo bó ti ń tuni nínú tó láti mọ̀ pé Jèhófà ò ní fi àwa nìkan sílẹ̀ ní gàdàmù nígbà àdánwò! (Aísá. 41:10) Ìgbà gbogbo ló máa ń wà pẹ̀lú wa, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń sìn ín tọkàntọkàn.—Sm. 46:7.

18 Ohun pàtàkì míì tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìgbàgbọ́ hàn ni ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lójú méjèèjì. (1 Kọ́r. 15:58) Ìdí tí wọ́n fi ju Pọ́ọ̀lù àti Sílà sẹ́wọ̀n kò ju pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù lójú méjèèjì. Àwọn àdánwò tí wọ́n rí ha mú kí wọ́n jáwọ́ nínú wíwàásù bí? Rárá o, ńṣe ni wọ́n ń wàásù nìṣó, kódà nígbà tí wọ́n wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, lẹ́yìn tí wọ́n sì tú wọn sílẹ̀, wọ́n rìnrìn àjò lọ sí Tẹsalóníkà, wọ́n sì wọnú sínágọ́gù àwọn Júù láti “bá wọn fèrò-wérò láti inú Ìwé Mímọ́.” (Ìṣe 17:1-3) Táa bá ní ìgbàgbọ́ tó múná nínú Jèhófà, tó sì dá wa lójú pé ọ̀dọ̀ wa ni òtítọ́ wà, kò sí nǹkan kan táá “lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 8:35-39.

19 Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Lóde Òní: Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ títayọ ló wà lóde òní ní ti àwọn èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára bíi ti Pọ́ọ̀lù àti Sílà. Arábìnrin kan tó la àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Auschwitz já sọ nípa ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin àti ìdánilójú táwọn ará tó wà níbẹ̀, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ní. Ó sọ pé: “Nígbà kan tí wọ́n ń lù wá lẹ́nu gbọ́rọ̀, ọ̀kan lára ọ̀gá wọn tọ̀ mí wá pẹ̀lú ìkúùkù dídì. Ó ké tantan pé: ‘Kí la ó ti wá ṣọ̀rọ̀ ẹ̀yin aráabí yìí sí báyìí? Báa bá fọlọ́pàá mú yín, kì í dùn yín. Báa bá sọ yín sẹ́wọ̀n, kò tu irun kankan lára yín. Báa bá kó yín lọ ságọ̀ọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, àgunlá àguntẹ̀tẹ̀. Báa bá dá ẹjọ́ ikú fún yín, ẹ kàn máa dúró gbagidi síbẹ̀ ni, bí ẹni pé ẹ̀yin kọ́ ni wọ́n dájọ́ ikú fún. Kí la ó ti wá ṣọ̀rọ̀ yín sí báyìí?’” Ó mà ń fún ìgbàgbọ́ lókun o, láti rí ìgbàgbọ́ táwọn ará wá ní lábẹ́ irú àwọn ipò líle koko bẹ́ẹ̀! Ojú Jèhófà ni wọ́n ń wò nígbà gbogbo fún ìrànlọ́wọ́ láti fara dà á.

20 Dájúdájú, a rántí ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ará wa nígbà kèéta ẹlẹ́yàmẹ̀yà tó wáyé ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí àwọn arákùnrin táa fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ wà nínú ewu, síbẹ̀ wọ́n rí i dájú pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn ń rí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ. Gbogbo wọn ló dúró bí olóòótọ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó lágbára pé ‘ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.’—Aísá. 54:17.

21 Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí wọ́n ní ọkọ tàbí aya aláìgbàgbọ́ ló ní ìgbàgbọ́ tó lágbára àti ìfaradà. Arákùnrin kan ní orílẹ̀-èdè Guadeloupe dojú kọ àtakò gbígbóná janjan látọ̀dọ̀ aya rẹ̀ aláìgbàgbọ́. Kí ó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a, kí ó sì dí i lọ́wọ́ ìpàdé Kristẹni lílọ, ìyàwó yìí kì í gbọ́ oúnjẹ fọ́kọ ẹ̀, kì í fọ aṣọ rẹ̀, kì í lọ aṣọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í rán aṣọ ọkọ rẹ̀ tó bá ya. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ló fi ń yan ọkọ rẹ̀ lódì. Àmọ́ ọkọ rẹ̀ fara dà á nítorí pé ó ń fi ìgbàgbọ́ àtọkànwá sin Jèhófà, ó sì ń gbàdúrà sí i fún ìrànlọ́wọ́. Ìgbà wo ló ṣe ìyẹn dà? Ó tó nǹkan bí ogún ọdún—kó tó di pé ọkàn ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ díẹ̀díẹ̀. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tí ìyàwó rẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìrètí Ìjọba Ọlọ́run.

22 Lákòótán, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ìgbàgbọ́ lílágbára táwọn ọ̀dọ́ wa, lọ́kùnrin lóbìnrin ní, bí wọ́n ti ń lọ síléèwé lójoojúmọ́, tí wọ́n sì ń dojú kọ ẹ̀mí ṣehun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe àtàwọn ìpèníjà míì. Ọ̀dọ́bìnrin Ẹlẹ́rìí kan sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń yọ àwọn lẹ́nu tó níléèwé láti ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe, ó ní: “Nígbà tóo bá wà nílé ẹ̀kọ́, gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ẹ ni wọ́n á máa ṣe nǹkan tí yóò mú kí o fẹ́ lẹ́mìí ọ̀tẹ̀ díẹ̀. Àwọn ojúgbà ẹ á túbọ̀ máa fi ọ̀wọ̀ tìẹ wọ̀ ẹ́, tóo bá ṣe nǹkan tó fi hàn pé o lẹ́mìí ọ̀tẹ̀.” Kékeré mà kọ́ lohun tójú àwọn ọ̀dọ́ wa ń rí! Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe ìpinnu tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú èrò inú àti ọkàn-àyà wọn pé àwọn ò ní juwọ́ sílẹ̀ nígbà ìdánwò.

23 Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ wa ló ń ṣe dáadáa tó bá dọ̀ràn pípa ìwà títọ́ mọ́ nígbà àdánwò. Àpẹẹrẹ kan ni ti ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń gbé ní ilẹ̀ Faransé. Lọ́jọ́ kan lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán, àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan fẹ́ fipá mú un kí ó fẹnu ko àwọn lẹ́nu, ṣùgbọ́n ó gbàdúrà, ó sì kọ̀ jálẹ̀, ni àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà bá fi í lọ́rùn sílẹ̀. Nígbà tó yá, ọ̀kan lára wọn padà wá sọ fún un pé ìgboyà rẹ̀ wú òun lórí. Ó wá lo àǹfààní yìí láti jẹ́rìí kúnnákúnná fún un nípa Ìjọba náà, ó ṣàlàyé ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga tí Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwọn tó bá fẹ́ nípìn-ín nínú àwọn ìbùkún Ìjọba náà máa tẹ̀ lé. Láàárín ọdún yẹn níléèwé, ó tún ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ̀ fún gbogbo ọmọ kíláàsì rẹ̀.

24 Àǹfààní ńlá la mà ní o, pé a wà lára àwọn tó wu Jèhófà láti lò fún fífi ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ rẹ̀! (Kól. 4:12) Kò mọ síbẹ̀ o, a tún ní àgbàyanu àǹfààní ti pípa ìwà títọ́ mọ́ nígbà tí Sátánì Èṣù, kìnnìún abìjàwàrà Elénìní wa, bá gbéjà kò wá. (1 Pét. 5:8, 9) Kí a má gbàgbé o, pé ìhìn Ìjọba náà ni Jèhófà ń lò láti fi ṣí ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún àwa tí ń wàásù rẹ̀ àtàwọn tó ń feti sí i. Ǹjẹ́ kí àwọn ìpinnu táa ń ṣe àti ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ máa fi hàn pé Ìjọba náà là ń fi sípò àkọ́kọ́. Ẹ jẹ́ ká máa fi ìgbàgbọ́ tó lágbára wàásù ìhìn rere náà nìṣó!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́