ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 15 ojú ìwé 18
  • Fi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìtara
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Sọ̀rọ̀ Bí Ẹni Ń Báni Fọ̀rọ̀ Wérọ̀
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 15 ojú ìwé 18

Ẹ̀KỌ́ 15

Fi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀

Ẹsẹ Bíbélì tá a tọ́ka sí

1 Tẹsalóníkà 1:5

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé o gbà pé òótọ́ ni ohun tí ò ń sọ àti pé ọ̀rọ̀ náà ṣe pàtàkì.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Múra sílẹ̀ dáadáa. Ṣàyẹ̀wò ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí dáadáa títí wàá fi rí ọ̀nà tí Bíbélì gbà fi hàn pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni. Fi ọ̀rọ̀ ṣókí tó sì rọrùn ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ. Pọkàn pọ̀ sórí àǹfààní tó máa ṣe fún àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀. Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.

    Àwọn àbá

    Nígbà tó o bá ń múra ọ̀rọ̀ rẹ, ńṣe ni kó o sọ̀rọ̀ sókè, èyí á jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ ṣe kedere lọ́kàn rẹ, kó sì já geere nígbà tó o bá ń sọ ọ́.

  • Lo àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà dá ẹ lójú. Dípò ti wàá fi máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìtẹ̀jáde kan bó ṣe wà níbẹ̀ gẹ́lẹ́, ńṣe ni kó o sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ara rẹ. Lo àwọn ọ̀rọ̀ tó máa fi hàn pé ohun tó ò ń sọ dá ẹ lójú.

  • Fi ìdánilójú sọ̀rọ̀, kó o sì sọ̀rọ̀ látọkàn wá. Gbóhùn sóke bó ṣe yẹ. Máa wo ojú àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀, tí kò bá burú láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní àgbègbè yín.

    Àwọn àbá

    Fi sọ́kàn pé kí èèyàn fi ìdánilójú sọ̀rọ̀ kò túmọ̀ sí pé kó má ṣe fi ọgbọ́n sọ̀rọ̀ tàbí pé kó máa sọ̀rọ̀ bíi pé èrò tiẹ̀ nìkan ló dára jù tàbí kó máa fipá mú àwọn èèyàn láti ṣe nǹkan. Tó o bá tiẹ̀ fẹ́ fi ìdánilójú sọ̀rọ̀, o ṣì lè fi ìfẹ́ rọ àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ láti ṣe ohun tó yẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́