ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 18 ojú ìwé 21
  • Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtara
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 18 ojú ìwé 21

Ẹ̀KỌ́ 18

Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ

Ẹsẹ Bíbélí tí a tọ́ka sí

1 Kọ́ríńtì 9:​19-23

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Sọ ohun tó máa mú kí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ronú jinlẹ̀, tó sì máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Ronú nípa ohun táwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Dípò tí wàá kàn fi máa tún ohun tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ sọ, sọ ọ́ lọ́nà tó máa jẹ́ kí wọ́n fi ojú tó yàtọ̀ wo ọ̀rọ̀ náà.

    Àwọn àbá

    Má ṣe pẹ́ lórí àlàyé nípa àwọn nǹkan tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ńṣe ni kó o fi sùúrù ṣàlàyé àwọn nǹkan tuntun.

  • Ṣe ìwádìí, kó o sì ṣe àṣàrò. Tó bá ṣeé ṣe, sọ̀rọ̀ nípa nǹkan táwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ tàbí kó o fi àwọn ohun tó ń lọ láyé ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì. Ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àti bí kókó náà ṣe tan mọ́ àwọn àpẹẹrẹ tó o fẹ́ lò.

    Àwọn àbá

    Bó o ṣe ń ṣàyẹ̀wò ohun tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, bi ara rẹ láwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí ìwọ fúnra rẹ ronú jinlẹ̀, bíi ‘kí ni, kí nìdí, ìgbà wo, ibo, ta ni àti báwo.’ Bó o ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ, o lè máa béèrè irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀, kó o sì máa dáhùn wọn láti mú kí ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ tani jí.

  • Jẹ́ kí wọ́n rí i pé ọ̀rọ̀ rẹ ṣe pàtàkì. Ṣàlàyé bí àwọn kókó pàtàkì inú Ìwé Mímọ́ ṣe lè ran àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ nínú ìgbé ayé wọn ojoojúmọ́. Sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtó kan tàbí ohun tẹ́nì kan ṣe tó kan àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́