ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 19 ojú ìwé 22
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtara
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Rírí I Dájú Pé Ọ̀rọ̀ Wọni Lọ́kàn
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Gbéni Ró Kó sì Ṣàǹfààní
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 19 ojú ìwé 22

Ẹ̀KỌ́ 19

Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Òwe 3:1

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Jẹ́ kí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ rí bí ohun tí ò ń sọ ṣe wúlò tó, kí wọ́n sì ṣe ohun tó yẹ.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Sọ ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n yẹ ara wọn wò. Béèrè àwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ tó máa jẹ́ kí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ronú nípa ojú tí wọ́n fi ń wo nǹkan.

  • Sọ ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n ní èrò tó dára. Rọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ pé kí wọ́n máa ronú jinlẹ̀ nípa ìdí tí wọ́n fi ń ṣe àwọn nǹkan tó dára. Jẹ́ kó yé wọn pé ohun tó dára jù lọ tó yẹ kó wà lọ́kàn wa tá a bá fẹ́ ṣe ohunkóhun ni ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà, àwọn èèyàn àti ẹ̀kọ́ Bíbélì. Sọ ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n rí i pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì bọ́gbọ́n mu, kì í ṣe pé kó o kàn máa rọ̀jò ọ̀rọ̀ lé wọn lórí. Dípò tí wàá fi kàn wọ́n lábùkù, ohun tó dára ni pé nígbà tó o bá fi máa parí ọ̀rọ̀ rẹ kí wọ́n ti gba ìṣírí táá mú kí wọ́n sa gbogbo ipá wọn láti túbọ̀ máa ṣe dáadáa.

  • Jẹ́ kí àwọn èèyàn mọyì Jèhófà. Sọ bí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, àwọn ìlànà Bíbélì, àtàwọn àṣẹ tó wà nínú Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti bí wọ́n ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Sọ ohun tó máa jẹ́ kí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ máa ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, kí wọ́n sì máa sapá láti ṣe ohun tó wù ú.

    Àwọn àbá

    Rántí pé Jèhófà ló ń fa àwọn èèyàn. Fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbà wọ́n níyànjú láti ṣe ohun tó tọ́.

LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Tó bá ṣeé ṣe, béèrè àwọn ìbéèrè kan lọ́wọ́ ẹni tí ò ń bá sọ̀rọ̀ tó máa jẹ́ kó o mọ ohun tó gbà gbọ́ gangan. Ṣàkíyèsí ojú rẹ̀ àti bó ṣe ń sọ̀rọ̀, kó o lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ gangan. Ṣùgbọ́n, o gbọ́dọ̀ ṣe sùúrù o. Fi sọ́kàn pé kí ẹnì kan tó lè máa sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún ẹ fàlàlà, ó ti gbọ́dọ̀ fọkàn tán ẹ dáadáa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́