ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 22 ojú ìwé 153-ojú ìwé 156 ìpínrọ̀ 5
  • Lílo Ìwé Mímọ́ Bí Ó Ti Yẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lílo Ìwé Mímọ́ Bí Ó Ti Yẹ
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Kí Ìdí Tó O Fi Ka Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Nínasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Jẹ́ Kí Ẹ̀kọ́ Rẹ Máa Yíni Lérò Pa Dà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 22 ojú ìwé 153-ojú ìwé 156 ìpínrọ̀ 5

Ẹ̀KỌ́ 22

Lílo Ìwé Mímọ́ Bí Ó Ti Yẹ

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o rí i dájú pé ọ̀nà èyíkéyìí tó o bá gbà lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan bá ìdí tí ọ̀rọ̀ yẹn fi wáyé níbẹ̀ mu àti pé ó bá Bíbélì mu lódindi. Bí o ṣe lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tún gbọ́dọ̀ bá ohun tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti tẹ̀ jáde mu.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Ohun kékeré kọ́ ni kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí àwọn èèyàn ní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:3, 4) Èyí sọ ọ́ di dandan fún wa láti fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni lọ́nà tí ó tọ́.

NÍGBÀ tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ohun tó yẹ ká ṣe ju ká kàn ṣáà ti ka àwọn ẹsẹ kan látinú Bíbélì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Tím. 2:15.

Láti ṣe èyí túmọ̀ sí pé bí a ṣe ń ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ gbọ́dọ̀ bá ohun tí Bíbélì alára fi kọ́ni mu. Èyí ń béèrè pé ká gbé ìdí tí ọ̀rọ̀ yẹn fi wáyé níbẹ̀ yẹ̀ wò, dípò tí a ó kàn fi fa àwọn gbólóhùn tó kàn wù wá níbẹ̀ yọ, kí á sì wá fi èrò tara wa kún un. Jèhófà gbẹnu Jeremáyà kìlọ̀ fáwọn wòlíì tó sọ pé ẹnu Jèhófà làwọn ti gbọ́ ọ̀rọ̀ táwọn ń sọ, nígbà tó jẹ́ pé “ìran ọkàn-àyà tiwọn” ni wọ́n ń sọ ní ti gidi. (Jer. 23:16) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe fi ìmọ̀ ọgbọ́n orí ènìyàn ta àbààwọ́n sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà tó kọ̀wé pé: “Àwa ti kọ àwọn ohun má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ tí ń tini lójú sílẹ̀ ní àkọ̀tán, a kò rin ìrìn àlùmọ̀kọ́rọ́yí, bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣe àbùlà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Láyé ìgbà yẹn, àwọn onímàgòmágó tí ń ta wáìnì máa ń fomi lú wáìnì wọn kí ó lè pọ̀ sí i, kí owó lè túbọ̀ wọlé fún wọn. Àwa kì í ṣe àbùlà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa dída ọgbọ́n orí ènìyàn pọ̀ mọ́ ọ̀rọ̀ náà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti jẹ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí pẹ̀lú òtítọ́ inú, bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí a ti rán wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ní iwájú Ọlọ́run, ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, ni àwa ń sọ̀rọ̀.”—2 Kọ́r. 2:17; 4:2.

Nígbà mìíràn, o lè lo ẹsẹ Bíbélì kan láti fi gbé ìlànà kan yọ. Bíbélì kún fún àwọn ìlànà tó ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà yíyèkooro láti kojú onírúurú ipò. (2 Tím. 3:16, 17) Ṣùgbọ́n, o gbọ́dọ̀ rí i dájú pé o lo ẹsẹ Bíbélì lọ́nà pípéye, láìlọ́ ọ lọ́rùn, láìmú kí ó máa sọ ohun tí ìwọ bá fẹ́. (Sm. 91:11, 12; Mát. 4:5, 6) Bí o ṣe lò ó gbọ́dọ̀ bá ète Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu látòkèdélẹ̀.

‘Fífi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́’ tún wé mọ́ lílóye èrò tí Bíbélì ń gbìn síni lọ́kàn. Kì í ṣe “kóńdó” tí a fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn. Àwọn olùkọ́ni inú ìsìn tí wọ́n tako Jésù Kristi fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́, àmọ́ wọn ò náání àwọn ohun pàtàkì tí Ọlọ́run ń béèrè, ìyẹn àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́. (Mát. 22:23, 24; 23:23, 24) Jésù a máa gbé ànímọ́ Bàbá rẹ̀ yọ nígbà tó bá ń kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí Jésù ṣe ní ìtara fún òtítọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fáwọn èèyàn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. A gbọ́dọ̀ sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.—Mát. 11:28.

Báwo la ṣe lè rí i dájú pé a ò ṣi Ìwé Mímọ́ lò? Kíka Bíbélì déédéé yóò ràn wá lọ́wọ́. Ó tún yẹ ká mọyì “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tí Jèhófà ń lò, ìyẹn ẹgbẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró tí Jèhófà ń tipasẹ̀ rẹ̀ pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún agboolé ìgbàgbọ́. (Mát. 24:45) Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé àti kíkópa nínú wọn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jàǹfààní nínú ìtọ́ni tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà ń pèsè.

Bí ìwé Reasoning From the Scriptures bá wà lédè rẹ, tí o sì mọ̀ ọ́n lò dáadáa, kò ní nira fún ọ rárá láti mọ ọ̀nà tó tọ́ láti gbà lo ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a sábà máa ń lò lóde ẹ̀rí. Bó o bá fẹ́ lo ẹsẹ kan tí o kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ yóò sún ọ láti ṣe ìwádìí yíyẹ, kí o bàa lè fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́ nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀.—Òwe 11:2.

Jẹ́ Kí Ìlò Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere. Nígbà tó o bá ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn, rí i dájú pé wọ́n lóye bí ẹsẹ tó o lò ṣe tan mọ́ kókó tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Bó bá jẹ́ ìbéèrè lo fi nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ náà, ó yẹ káwọn olùgbọ́ rẹ rí i bí ẹsẹ náà ṣe dáhùn ìbéèrè ọ̀hún. Bó bá jẹ́ pé ò ń fi ẹsẹ náà ti gbólóhùn kan lẹ́yìn ni, rí i dájú pé akẹ́kọ̀ọ́ náà lóye bí ẹsẹ náà ṣe ṣàlàyé kókó náà.

Wíwulẹ̀ ka ẹsẹ náà, àní kéèyàn kà á pẹ̀lú ìtẹnumọ́ pàápàá, kì í sábàá tó. Rántí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ ohun tó wà nínú Bíbélì, tó sì jẹ́ pé kíkà á lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré lè máà tó láti mú kí wọ́n lóye kókó tí ò ń sọ. Pe àfiyèsí sí apá ibi tó tan mọ́ kókó tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ lé lórí gan-an nínú ẹsẹ náà.

Èyí sábà máa ń béèrè pé kí o mú àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì-pàtàkì ibẹ̀ jáde, ìyẹn àwọn ọ̀rọ̀ tí kókó tí ẹ̀ ń sọ dá lé lórí gan-an. Ọ̀nà tó rọrùn jù lọ ni pé kó o tún àwọn ọ̀rọ̀ tí ń lani lóye wọ̀nyẹn sọ. Bó bá jẹ́ ẹnì kan lò ń bá sọ̀rọ̀, o lè béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kó rí ọ̀rọ̀ pàtàkì wọ̀nyẹn. Nígbà tí àwọn olùbánisọ̀rọ̀ kan bá ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀, wọ́n máa ń yàn láti lo àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tó ní ìtumọ̀ kan náà tàbí kí wọ́n tún àlàyé náà ṣe kí àwùjọ lè lóye wọn dáadáa. Àmọ́ tó o bá yàn láti ṣe èyí, ṣọ́ra, kí ọ̀rọ̀ rẹ má bàa rú àwùjọ lójú, tí wọn ò fi ní rí bí kókó tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí ṣe tan mọ́ ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà.

Tó o bá lè mú kí àwọn kókó ọ̀rọ̀ ṣe kedere, o ti fi ìpìlẹ̀ rere lélẹ̀ nìyẹn. Ohun tó kàn ni pé kí o wá ṣàlàyé síwájú sí i. Ṣé o jẹ́ kí ìdí tó o fi fẹ́ ka Ìwé Mímọ́ náà ṣe kedere nígbà tó ò ń nasẹ̀ rẹ̀? Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣàlàyé ọ̀nà tí àwọn ọ̀rọ̀ tí o tẹnu mọ́ gbà tan mọ́ ohun tó o fọkàn àwùjọ sí pé kí wọ́n máa retí. Ṣàlàyé yékéyéké nípa bí wọ́n ṣe tan mọ́ra. Ká tiẹ̀ wá sọ pé o kò lo irú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ṣe kedere bẹ́ẹ̀, ó ṣì yẹ kó o ṣàlàyé síwájú sí i.

Àwọn Farisí bi Jésù ní ìbéèrè kan tí wọ́n rò pé ó le koko bí ojú ẹja, wọ́n ní: “Ó ha bófin mu fún ọkùnrin láti kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ lórí onírúurú ìdí gbogbo?” Jésù gbé èsì rẹ̀ ka Jẹ́nẹ́sísì 2:24. Ṣàkíyèsí pé apá kan nínú ẹsẹ yẹn ló darí àfiyèsí sí, ó sì wá lò ó bó ṣe yẹ. Lẹ́yìn tó tọ́ka sí i pé ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ di “ara kan,” Jésù wá kan ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó pé: “Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mát. 19:3-6.

Báwo ló ṣe yẹ kí àlàyé rẹ gùn tó, kí ọ̀nà tó o gbà lo Ìwé Mímọ́ lè ṣe kedere? Àwùjọ rẹ àti bí kókó tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí ti ṣe pàtàkì sí ló yẹ kó pinnu ìyẹn. Ohun tó yẹ kó o máa lépa ni bí ọ̀rọ̀ rẹ á ṣe tètè yéni àti bí o ṣe máa sọ ojú abẹ níkòó.

Máa Fèrò Wérò Látinú Ìwé Mímọ́. Ìwé Ìṣe 17:2, 3 sọ fún wa pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù “fèrò-wérò láti inú Ìwé Mímọ́” nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Tẹsalóníkà. Gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà ló yẹ kó sapá láti ní ànímọ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó fi hàn pé a ti sọ nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, lẹ́yìn náà ló wá là á mọ́lẹ̀ pé: “Èyí ni Kristi náà, Jésù yìí tí mo ń kéde fún yín.”

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn Hébérù, ọ̀pọ̀ ìgbà ló fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Láti tẹnu mọ́ kókó kan tàbí láti mú un ṣe kedere, ó máa ń fa ẹyọ ọ̀rọ̀ kan tàbí gbólóhùn kúkúrú kan yọ, á sì wá sọ bí ó ṣe ṣe pàtàkì tó. (Héb. 12:26, 27) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ìtàn tó wà nínú Hébérù orí kẹta, ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Sáàmù 95:7-11. Ṣàkíyèsí pé ó wá ṣàlàyé lórí apá mẹ́ta lára rẹ̀: (1) ó ṣàlàyé lórí ọkàn-àyà (Héb. 3:8-12), (2) ó ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ náà “Lónìí” (Héb. 3:7, 13-15; 4:6-11), (3) ó sì ṣàlàyé ìtumọ̀ gbólóhùn náà: “Wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi” (Héb. 3:11, 18, 19; 4:1-11). Sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yẹn nínú bó o ṣe ń lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan.

Ṣàkíyèsí ọ̀nà tó múná dóko tí Jésù gbà fèrò wérò látinú Ìwé Mímọ́ nínú ìtàn tó wà ní Lúùkù 10:25-37. Ọkùnrin kan tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú Òfin béèrè pé: “Olùkọ́, nípa ṣíṣe kí ni èmi yóò fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Nígbà tí Jésù máa fèsì, ó kọ́kọ́ ní kí ọkùnrin náà sọ èrò rẹ̀ lórí ọ̀ràn náà. Lẹ́yìn náà ni Jésù wá tẹnu mọ́ bí ó ṣe ṣe pàtàkì tó láti ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí. Nígbà tó wá hàn kedere pé òye ọ̀rọ̀ náà kò tíì yé ọkùnrin yìí, Jésù wá ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ẹyọ ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo nínú ẹsẹ náà, èyíinì ni “aládùúgbò.” Dípò kí ó kàn sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ńṣe ló lo àpèjúwe kan tó ran ọkùnrin náà lọ́wọ́ láti fúnra rẹ̀ parí ọ̀rọ̀ náà síbi tó tọ́.

Ó ṣe kedere pé nígbà tí Jésù bá ń dáhùn ìbéèrè, kì í fa àwọn ẹsẹ Bíbélì tó dáhùn ìbéèrè náà yọ ní tààràtà lásán. Ńṣe ló máa ń fọ́ ohun tí ẹsẹ wọ̀nyí sọ sí wẹ́wẹ́, tí á sì wá fi bí ẹsẹ náà ṣe dáhùn ìbéèrè tó wà nílẹ̀ hàn.

Nígbà táwọn Sadusí ń tako ìrètí àjíǹde, apá kan pàtó nínú Ẹ́kísódù 3:6 ni Jésù pe àfiyèsí sí. Ṣùgbọ́n kò fi mọ sórí kíka ẹsẹ yẹn nìkan. Ó fèrò wérò lórí rẹ̀ láti fi hàn kedere pé àjíǹde jẹ́ ara ète Ọlọ́run.—Máàkù 12:24-27.

Mímọ bá a ṣe ń fèrò wérò lọ́nà tí ó tọ́, tí ó sì múná dóko nínú Ìwé Mímọ́ ṣe pàtàkì gan-an kí o tó lè di olùkọ́ tó pegedé.

BÍ O ṢE LÈ DI ẸNI TÓ NÍ ÀNÍMỌ́ YÌÍ

  • Máa ka Bíbélì déédéé. Máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, kí o sì máa múra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀ dáadáa.

  • Rí i dájú pé o mọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì èyíkéyìí tó o bá fẹ́ lò. Fara balẹ̀ ka ẹsẹ náà kí o lè ní òye tó gún régé nípa ohun tí ó ń sọ.

  • Jẹ́ kó mọ́ ọ lára láti máa ṣe ìwádìí nínú àwọn ìwé táwa Kristẹni ń lò.

ÌDÁNRAWÒ: Gbé ìtumọ̀ 2 Pétérù 3:7 yẹ̀ wò. Ǹjẹ́ ó fi hàn pé ilẹ̀ ayé á jóná lúúlúú? (Nígbà tó o bá ń túmọ̀ “ilẹ̀ ayé,” tún ronú nípa ohun tí “àwọn ọ̀run” túmọ̀ sí. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló fi hàn pé a ń lo “ilẹ̀ ayé” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ? Àwọn wo, tàbí kí ni àwọn ohun náà gan-an tí a ó pa run, gẹ́gẹ́ bí 2Pe 3 ẹsẹ keje ti sọ? Báwo nìyẹn ṣe bá ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Nóà mu, èyí tí 2Pe 3 ẹsẹ karùn-ún àti ìkẹfà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́