ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/10 ojú ìwé 1
  • Jẹ́ Kí Ẹ̀kọ́ Rẹ Máa Yíni Lérò Pa Dà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Ẹ̀kọ́ Rẹ Máa Yíni Lérò Pa Dà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílo Ìwé Mímọ́ Bí Ó Ti Yẹ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ṣó O Máa Ń Ṣalágbàwí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Máa Lo “Idà Ẹ̀mí” Lọ́nà Tó Jáfáfá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Bí A Ṣe Lè Yí Àwọn Ẹlòmíràn Lérò Padà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 4/10 ojú ìwé 1

Jẹ́ Kí Ẹ̀kọ́ Rẹ Máa Yíni Lérò Pa Dà

1. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó múná dóko lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

1 Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àwọn òjíṣẹ́ tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ mọ̀ pé fífi “ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́” ju pé kéèyàn kàn máa sọ ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́. (2 Tím. 2:15) Báwo la ṣe lè máa lo “ìyíniléròpadà” nígbà tá a bá ń kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?—Ìṣe 28:23.

2. Báwo la ṣe lè mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

2 Darí Àfiyèsí Wọn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: Lákọ̀ọ́kọ́, pe àfiyèsí àwọn èèyàn sí Bíbélì lọ́nà tó máa jẹ́ kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú rẹ̀. Tá a bá ń fi hàn pé ohun tá a kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dá wa lójú, èyí lè mú kí ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ túbọ̀ máa fọkàn sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá à ń kà. (Héb. 4:12) A lè sọ pé: “Mo ti jàǹfààní gan-an nígbà tí mo mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ọ̀rọ̀ yìí. Kíyè sí ohun tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ.” Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, máa darí àfiyèsí àwọn èèyàn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nípa kíkà á jáde ní tààràtà.

3. Kí la lè ṣe kí olùgbọ́ wa bàa lè lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a bá kà?

3 Ohun kejì ni pé kó o ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tẹ́ ẹ kà. Ọ̀pọ̀ kì í sábà lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n bá gbọ́ ọ. Ó gba pé ká ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn kí wọ́n tó lè mọ bó ṣe bá ohun tá à ń jíròrò mu. (Lúùkù 24:26, 27) Pe àfiyèsí onílé sí àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ náà tó tànmọ́lẹ̀ sí ohun tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò. Tó o bá bi í ní ìbéèrè, ìdáhùn rẹ̀ lè jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ohun tó ò ń sọ yé e.—Òwe 20:5; Ìṣe 8:30.

4. Kí ni ohun kẹta tó yẹ kó o ṣe bó o bá fẹ́ kọ́ni lọ́nà tó máa yíni lérò pa dà?

4 Fèrò Wérò Láti Inú Ìwé Mímọ́: Ohun kẹta ni pé, kó o jẹ́ kí ẹ̀kọ́ rẹ wọni lọ́kàn. Jẹ́ kí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ rí bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tẹ́ ẹ bá kà ṣe kan òun fúnra rẹ̀. Bó o bá ń bá àwọn èèyàn fèrò wérò láti inú Ìwé Mímọ́, èyí lè mú kí wọ́n yí èrò wọn pa dà. (Ìṣe 17:2-4; 19:8) Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tó o bá ka Sáàmù 83:18 o lè jíròrò bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká kọ́kọ́ mọ orúkọ ẹnì kan ká tó lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, o lè bi í pé, “Ǹjẹ́ o rò pé àdúrà rẹ á túbọ̀ nítumọ̀ bó o bá mọ orúkọ Ọlọ́run?” Bó o bá ń jẹ́ kí ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ rí bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tẹ́ ẹ kà ṣe kan ìgbésí ayé rẹ̀, á jẹ́ kó mọ bó ṣe wúlò tó. Tá a bá ń bá a nìṣó ní fífi ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yíni lérò pa dà, a óò fa àwọn olóòótọ́ ọkàn mọ́ra láti wá sin Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè.—Jer. 10:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́