Bí A Ṣe Lè Yí Àwọn Ẹlòmíràn Lérò Padà
1 Wọ́n mọ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé ó jẹ́ òjíṣẹ́ tó máa ń yíni lérò padà. (Ìṣe 19:26) Kódà Ágírípà Ọba sọ fún un pé: “Ní àkókò kúkúrú, ìwọ yóò yí mi lérò padà di Kristẹni.” (Ìṣe 26:28) Kí ló mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù máa yí èèyàn lérò padà tó bẹ́ẹ̀? Ó máa ń ṣàlàyé tó bọ́gbọ́n mu látinú Ìwé Mímọ́ nípa mímú kí àlàyé tó ń ṣe bá àwọn tó ń fetí sí i mú.—Ìṣe 28:23.
2 Ní àfarawé Pọ́ọ̀lù, ó yẹ kí àwa pẹ̀lú mọ bí a ṣeé yíni lérò padà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Lọ́nà wo? Nípa lílo òye nígbà tí a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ àti nígbà tí a bá ń fetí sí wọn. (Òwe 16:23) Ṣíṣe àwọn ohun mẹ́ta pàtàkì yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí.
3 Fetí Sílẹ̀ Dáadáa: Bí ẹlòmíràn bá ti ń sọ̀rọ̀, fetí sílẹ̀ láti mọ ibi tí èdè yín ti yéra tí wàá lè gbé ìjíròrò rẹ kà. Bí ẹni náà bá ṣàtakò, gbìyànjú láti mọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Á dára kí o mọ ohun tó gbà gbọ́ gan-an, ìdí tó fi ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, àti ohun tó jẹ́ kó dá a lójú. (Òwe 18:13) Fọgbọ́n wádìí ohun tí ń bẹ lọ́kàn rẹ̀.
4 Béèrè Ìbéèrè: Bí ẹnì kan bá sọ pé òun gba Mẹ́talọ́kan gbọ́, o lè béèrè pé: “Ṣé látilẹ̀ lo ti gba Mẹ́talọ́kan gbọ́?” Kí o tún wá béèrè pé: “Ǹjẹ́ o ti kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa kókó yìí?” O tún lè béèrè pé: “Bí Ọlọ́run bá jẹ́ apá kan Mẹ́talọ́kan, ǹjẹ́ kò yẹ ká retí pé kí Bíbélì sọ ọ́ ní kedere?” Ìdáhùn tí ẹni yẹn bá mú jáde yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bá ẹni yẹn jíròrò nípa ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ.
5 Lo Agbára Ìrònú Tó Yè Kooro: Ẹlẹ́rìí kan béèrè lọ́wọ́ obìnrin kan tó gbà gbọ́ pé Jésù ni Ọlọ́run pé: ‘Bí o bá ń gbìyànjú láti ṣàpèjúwe pé àwọn èèyàn méjì kan bára dọ́gba, irú ìbátan wo nínú ìdílé ni wàá lò?’ Obìnrin náà dáhùn pé: “Mo lè lo ti tẹ̀gbọ́n tàbúrò.” Ẹlẹ́rìí náà wá fi kún un pé: “Bóyá kẹ̀, o tiẹ̀ lè lo ti àwọn ìbejì tí wọn kò yàtọ̀ síra. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù ń kọ́ wa pé ká wo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi Baba àti òun gẹ́gẹ́ bí Ọmọ, kí lohun tí Jésù ń sọ?” Ọ̀rọ̀ wá yé obìnrin náà pé ọ̀kan ju èkejì lọ, ó sì ní ọlá àṣẹ jù ú lọ. (Mát. 20:23; Jòh.14:28; 20:17) Ọ̀nà ìyíniléròpadà jẹ́ kí Ẹlẹ́rìí yẹn lè dé èrò inú àti ọkàn-àyà obìnrin náà.
6 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa tẹ́wọ́ gba òtítọ́, bó ti wù ká gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu tó sì kúnjú ìwọ̀n tó. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi Pọ́ọ̀lù, ẹ jẹ́ ká jẹ́ aláápọn ní wíwá àwọn aláìlábòsí-ọkàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa rí, ká máa yí wọn lérò padà láti tẹ́wọ́ gba ìhìn Ìjọba náà.—Ìṣe 19:8.