ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 5/15 ojú ìwé 21-23
  • Dídé Inú Ọkàn-àyà Nípasẹ̀ Lílo Ọnà Ìyíniléròpadà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dídé Inú Ọkàn-àyà Nípasẹ̀ Lílo Ọnà Ìyíniléròpadà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílo Ìyíniléròpadà Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́
  • Kíkojú Èrò Ìmọ̀lára
  • Bí A Ṣe Lè Yí Àwọn Ẹlòmíràn Lérò Padà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Fiyè Sí “Ọnà Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kejì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 5/15 ojú ìwé 21-23

Dídé Inú Ọkàn-àyà Nípasẹ̀ Lílo Ọnà Ìyíniléròpadà

Ọ̀RỌ̀ náà, “ìyíniléròpadà,” máa ń kọ ọ̀pọ̀ ènìyàn lóminú. Ó lè mú èrò alákitiyan òǹtajà kan tàbí ti ìpolówó tí a gbé kalẹ̀ láti tan òǹrajà jẹ tàbí láti fi rẹ́ ẹ jẹ síni lọ́kàn. Nínú Bíbélì pàápàá, nígbà mìíràn ìyíniléròpadà ní ìtumọ̀ òdì, ó lè túmọ̀ sí sísọni dìbàjẹ́ tàbí mímúni ṣáko lọ. Fún àpẹẹrẹ, Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn ará Gálátíà pé: “Ẹ̀yin ti ń sáré dáadáa tẹ́lẹ̀. Ta ní dí yín lọ́wọ́ nínú bíbá a nìṣó ní ṣíṣègbọràn sí òtítọ́? Irú ìyíniléròpadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ẹni tí ń pè yín wá.” (Gálátíà 5:7, 8) Pọ́ọ̀lù tún kìlọ̀ fún àwọn ará Kólósè pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan ‘mọ̀ọ́mọ̀ fi àwọn ìjiyàn tí ń yíni lérò padà ṣì wọ́n lọ́nà.’ (Kólósè 2:4) Irú ìyíniléròpadà bẹ́ẹ̀ sinmi lé àwọn ìjiyàn tí ó kún fún ọgbọ́nkọ́gbọ́n, tí a gbé ka àwọn ìpìlẹ̀ èké.

Àmọ́ ṣáá o, nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì sí Tímótì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ náà ìyíniléròpadà ní ìtumọ̀ mìíràn. Ó kọ̀wé pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́, ní mímọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn.” (2 Tímótì 3:14) Ìyá Tímótì àti ìyá rẹ̀ àgbà, ipasẹ̀ àwọn tí ó gbà kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́, kò rẹ́ ẹ jẹ nípa ‘yíyí i lérò padà láti gbà gbọ́.’—2 Tímótì 1:5.a

Nígbà tí wọ́n sé Pọ́ọ̀lù mọ́lé ní Róòmù, ó jẹ́rìí kúnnákúnná fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, “nípa lílo ìyíniléròpadà pẹ̀lú wọn nípa Jésù láti inú òfin Mósè àti àwọn Wòlíì, láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.” (Ìṣe 28:23) Ṣé Pọ́ọ̀lù ń tan àwọn olùgbọ́ rẹ̀ jẹ ni? Rárá o! Nípa báyìí, ó ṣe kedere pé ìyíniléròpadà kì í fi ìgbà gbogbo jẹ́ ohun tí ó burú.

Nígbà tí a bá lò ó ní èrò rere, ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a tú sí “yí lérò padà,” túmọ̀ sí láti mú gbà gbọ́ dájú, láti mú kí ìyípadà nínú èrò inú ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ ìfèròwérò tí ó gbéṣẹ́, tí ó sì bọ́gbọ́n mu. Olùkọ́ kan lè tipa báyìí gbé àlàyé rẹ̀ ka orí ìpìlẹ̀ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, kí ó wá fi ìyíniléròpadà gbin ìgbàgbọ́ nínú òtítọ́ Bíbélì sínú àwọn ẹlòmíràn. (2 Tímótì 2:15) Ní tòótọ́, èyí jẹ́ àmì iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù. Kódà Dímẹ́tíríù alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí ó ka àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni sí èké, ṣàlàyé pé: “Kì í ṣe ní Éfésù nìkan, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní gbogbo àgbègbè Éṣíà, bí Pọ́ọ̀lù yìí ti yí ogunlọ́gọ̀ tí ó tóbi púpọ̀ lérò padà, tí ó sì ti yí wọn padà sí èrò mìíràn, tí ó ń wí pé àwọn èyí tí a fi ọwọ́ ṣe kì í ṣe ọlọ́run.”—Ìṣe 19:26.

Lílo Ìyíniléròpadà Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́

Jésù Kristi fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:19, 20) Ní èyí tí ó ju 230 ilẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣègbọràn sí àṣẹ yìí. Ní oṣù kọ̀ọ̀kan jálẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn wọn ti 1997, kárí ayé, wọ́n ṣe 4,552,589 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.

Bí o bá ní àǹfààní láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, o lè fojú sọ́nà fún àwọn ìpèníjà tí yóò béèrè fún lílo ọnà ìyíniléròpadà. Fún àpẹẹrẹ, kí a sọ pé nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ tí yóò tẹ̀ lé e, ìbéèrè kan dìde nípa Mẹ́talọ́kan. Kí ni ìwọ yóò ṣe bí o bá mọ̀ pé ẹni tí o ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ gba ẹ̀kọ́ yìí gbọ́? O lè fún un ní ìwé tí ó ṣàlàyé nípa kókó yìí. Lẹ́yìn tí ó bá ti kà á, o lè wá rí i pé a ti yí i lérò padà láti gbà gbọ́ pé Ọlọ́run àti Jésù kì í ṣe ẹni kan náà. Ṣùgbọ́n bí àwọn ìbéèrè kan bá ṣì ṣẹ́ kù, kí wá ni o lè ṣe?

Fetí sílẹ̀ dáadáa. Èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ nípa kókó èyíkéyìí. Fún àpẹẹrẹ, bí ẹni tí o ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá sọ pé, “Mo gba Mẹ́talọ́kan gbọ́,” o lè tètè gbẹ́nu lé ìjíròrò láti inú Ìwé Mímọ́ láti já ìgbàgbọ́ yìí ní koro. Ṣùgbọ́n onírúurú èrò ni ó wà nípa Mẹ́talọ́kan. Èrò ẹni tí o ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí o fẹ́ ṣàlàyé nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Ó lè jẹ́ pé báyìí ni ọ̀ràn rí ní ti àwọn ìgbàgbọ́ mìíràn, irú bí àtúnwáyé, àìleèkú ọkàn, àti ìgbàlà. Nítorí náà, fetí sílẹ̀ dáadáa kí o tó sọ̀rọ̀. Má fi ohun tí o rò pinnu ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà gbà gbọ́.—Òwe 18:13.

Béèrè ìbéèrè. Èyí lè ní nínú: ‘Ṣé láti ìbẹ̀rẹ̀ wá ni o ti gba Mẹ́talọ́kan gbọ́? O ha ti fi ìgbà kan rí ṣèwádìí jinlẹ̀-jinlẹ̀ nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí? Bí Ọlọ́run bá jẹ́ apá kan mẹ́talọ́kan, Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kò ha ní sọ bẹ́ẹ̀ fún wa ní kedere àti ní tààràtà?’ Bí o ṣe ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́, máa dánu dúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti béèrè àwọn ìbéèrè bí: ‘Ohun tí a ti gbé yẹ̀wò títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí ha mọ́gbọ́n dání lójú rẹ bí?’ ‘O ha fara mọ́ àlàyé yìí bí?’ Nípa lílò tí o bá ń lo àwọn ìbéèrè lọ́nà tí ó jáfáfá, o ń mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà kópa nínú ẹ̀kọ́ kíkọ́. Kò yẹ kí ó kàn jẹ́ pé ṣe ni ó fetí sí ọ bí o ti ń fọ́ kókó kan sí wẹ́wẹ́.

Lo ìfèròwérò gbígbéṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, bí o bá ń jíròrò ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, o lè sọ fún ẹni tí o ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ pé: ‘Nígbà tí a batisí Jésù, ohùn kan wá láti ọ̀run, tí ó sọ pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” Bí ó bá ṣe pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run wà ní orí ilẹ̀ ayé tí a ń batisí rẹ̀, yóò ha rán ohùn rẹ̀ lọ sí ọ̀run kí ó sì tún padà wá kí a lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wọnnì lórí ilẹ̀ ayé bí? Èyíinì kì yóò ha ṣini lọ́nà bí? Ọlọ́run, “ẹni tí kò lè purọ́,” yóò ha ṣe irú ohun ìtànjẹ bẹ́ẹ̀ bí?’—Lúùkù 3:21, 22; Títù 1:1, 2.

Ìfèròwérò gbígbéṣẹ́ tí a gbé kalẹ̀ lọ́nà ọgbọ́n sábà máa ń ṣàṣeyọrí. Gbé àpẹẹrẹ obìnrin kan tí a ó pè ní Barbara yẹ̀ wò. Ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, ó gbà gbọ́ pé Jésù ni Ọlọ́run àti pé ó jẹ́ ara mẹ́talọ́kan tí ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ apá kan rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún un pé Ọlọ́run àti Jésù jẹ́ ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó sì fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ hàn án tí ó ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn.b Barbara kò lè já Bíbélì ní koro. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ìjákulẹ̀ bá a. Ó ṣe tán, ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan jẹ́ ohun iyebíye fún un.

Ẹlẹ́rìí náà fi sùúrù fèrò wérò pẹ̀lú Barbara. Ó béèrè pé: “Ká ní o ń gbìyànjú láti kọ́ mi pé ẹni méjì jẹ́ ọgbọọgba, ipò ìbátan wo nínú ìdílé ni ìwọ yóò fi ṣàpèjúwe rẹ̀?” Ó ronú fún sáà kan, ó sì fèsì pé: “Mo lè lo arákùnrin méjì.” Ẹlẹ́rìí náà dáhùn pé: “Òdodo ọ̀rọ̀. Bóyá o tilẹ̀ lè lo àwọn ìbejì tí wọ́n jọra. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù kọ́ wa pé kí a wo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá, kí a sì wo òun gẹ́gẹ́ bí Ọmọ, kí ni ó ń sọ?” Barbara fèsì, bí ojú rẹ̀ ti ń là, pé: “Ó yé mi wàyí. Ó ń ṣàpèjúwe ọ̀kan bí ẹni tí ó dàgbà ju èkejì, tí ó sì ní ọlá àṣẹ jù ú lọ.”

Ẹlẹ́rìí náà dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, àti pé àwọn Júù tí ń gbọ́ ohun tí Jésù ń sọ, yóò dé orí ìparí èrò yẹn pàápàá jù lọ, nítorí pé àwùjọ tí baba ti jẹ́ olórí agboolé ni wọ́n ń gbé.” Ní dídé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ládé, Ẹlẹ́rìí náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí a bá gbé irúfẹ́ àpèjúwe tí ó ṣe wẹ́kú bẹ́ẹ̀ kalẹ̀ láti fi kọ́ni ní èròǹgbà jíjẹ́ ọgbọọgba—ti àwọn arákùnrin tàbí ti àwọn ìbejì tí wọ́n jọra—dájúdájú, Jésù, tí í ṣe Olùkọ́ Ńlá, lè ti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ náà ‘baba’ àti ‘ọmọ’ láti fi ṣàpèjúwe ìbátan tí ó wà láàárín òun àti Ọlọ́run.”

Níkẹyìn, Barbara lóye kókó náà, ó sì tẹ́wọ́ gbà á. A ti dé inú ọkàn-àyà rẹ̀ nípasẹ̀ lílo ọnà ìyíniléròpadà.

Kíkojú Èrò Ìmọ̀lára

Àwọn ìgbàgbọ́ tí ó ti wọni lọ́kàn ṣinṣin sábà máa ń wé mọ́ èrò ìmọ̀lára. Gbé ọ̀ràn Edna yẹ̀ wò, ẹni tí ó jẹ́ Kátólíìkì olùfọkànsìn. Àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ tí í ṣe ọ̀dọ́langba fi ẹ̀rí tí ó ṣe kedere hàn án láti inú Ìwé Mímọ́ pé Ọlọ́run àti Jésù kì í ṣe ẹni kan náà. Edna lóye ohun tí ó gbọ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó fi inú rere sọ ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdúró gbọn-in pé: “Mo gba Mẹ́talọ́kan mímọ́ gbọ́.”

Bóyá o ti ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀. Ojú tí àwọn kan fi ń wo àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn wọn ni bí ẹni pé ìwọ̀nyí jẹ́ apá kan àmì ìdánimọ̀ wọn. Láti yí irú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ́ẹ̀ lérò padà, a nílò ju kìkì ọgbọ́n ìrònú tí a kàn gbé kalẹ̀ ṣákálá tàbí ọ̀wọ́ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàápàá tí ó fi hàn pé ojú ìwòye onítọ̀hún kún fún ìṣìnà. A lè yanjú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ nípa lílo ìyọ́nú ní àfikún sí ọnà ìyíniléròpadà. (Fi wé Róòmù 12:15; Kólósè 3:12.) Òtítọ́ ni, ó yẹ kí olùkọ́ tí ó jáfáfá ní ìgbàgbọ́ tí ó lágbára. Fún àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù lo gbólóhùn bí “mo gbà gbọ́ dájú” àti “mo mọ̀, mo sì gbà nínú Jésù Olúwa.” (Róòmù 8:38; 14:14) Àmọ́ ṣáá o, nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wa, kò yẹ kí a ní ẹ̀mí èrò-tèmi-ló-tọ́ tàbí kí a jẹ́ olódodo lójú ara wa, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ kí a bẹ̀rẹ̀ sí pẹ̀gàn tàbí kí a máa tẹ́ àwọn ènìyàn nígbà tí a bá ń gbé àwọn òtítọ́ inú Bíbélì kalẹ̀. Dájúdájú a kò ní fẹ́ láti mú akẹ́kọ̀ọ́ náà bínú tàbí kí a tilẹ̀ fi ìwọ̀sí lọ̀ ọ́.—Òwe 12:18.

Ó máa ń gbéṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí a bá ka ìgbàgbọ́ akẹ́kọ̀ọ́ sí, tí a sì gbà pé ó ní ẹ̀tọ́ láti ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Ìrẹ̀lẹ̀ ni kókó pàtàkì tí a nílò. Olùkọ́ tí ó bá ní ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú kì í nímọ̀lára pé ẹ̀dá tòun lọ́lá ju ti ẹni tí òun ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. (Lúùkù 18:9-14; Fílípì 2:3, 4) Ìyíniléròpadà lọ́nà ti Ọlọ́rùn wé mọ́ ìrẹ̀lẹ̀, èyí tí ń sọ ní ti tòótọ́ pé: ‘Jèhófà ti fi tàánútàánú ràn mí lọ́wọ́ láti rí eléyìí. Jẹ́ kí èmi náà fi hàn ọ́.’

Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Kọ́ríńtì pé: “Àwọn ohun ìjà ogun wa kì í ṣe ti ara, ṣùgbọ́n wọ́n jẹ alágbára láti ọwọ́ Ọlọ́run fún dídojú àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in dé. Nítorí àwọn ìrònú àti gbogbo ohun gíga fíofío tí a gbé dìde lòdì sí ìmọ̀ nípa Ọlọ́run ni àwa ń dojú wọn dé; a sì ń mú gbogbo ìrònú wá sí oko òǹdè láti mú un ṣègbọràn sí Kristi.” (2 Kọ́ríńtì 10:4, 5) Lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti fi dojú àwọn ẹ̀kọ́ èké tí ó ti fìdí rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in dé, títí kan àwọn àṣà àti ìṣesí tí ó ti di mọ́líkì, àwọn èyí tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Ní ṣíṣe èyí, Àwọn Ẹlẹ́rìí rántí pé Jèhófà ti fi tìfẹ́tìfẹ́ mú sùúrù fún wọn. Ẹ wo bí inú wọ́n ti dùn tó láti ní Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti lo irinṣẹ́ lílágbára yìí láti fi fa àwọn ẹ̀kọ́ èké tu, kí wọ́n sì dé inú ọkàn-àyà nípasẹ̀ lílo ọnà ìyíniléròpadà!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Yùníìsì àti Lọ́ìsì—Àwọn Olùkọ́ni Àwòfiṣàpẹẹrẹ,” ní ojú ìwé 7 sí 9 nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ yìí.

b Wo Jòhánù 14:28; Fílípì 2:5, 6; Kólósè 1:13-15. Fún ìsọfúnni púpọ̀ sí i, wo ìwé pẹlẹbẹ náà Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

Dídé Inú Ọkàn-Àyà Ẹni Tí O Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́

◻ Gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Jèhófà láti lè dé inú ọkàn-àyà akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà.—Nehemáyà 2:4, 5; Aísáyà 50:4.

◻ Mòye ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà gbà gbọ́ àti ìdí tí ẹ̀kọ́ èké náà fi fà á lọ́kàn mọ́ra.—Ìṣe 17:22, 23.

◻ Bí o ti n fi àwọn èrò àjọgbà ṣe kókó ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, fi inú rere àti sùúrù gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, tí ó sì bọ́gbọ́n mu.—Ìṣe 17:24-34.

◻ Bí ó bá ṣeé ṣe, lo àwọn àpèjúwe gbígbéṣẹ́ láti fún àwọn òtítọ́ inú Bíbélì lókun.—Máàkù 4:33, 34.

◻ Fi àǹfààní títẹ́wọ́gba ìmọ̀ pípéye láti inú Bíbélì han akẹ́kọ̀ọ́ náà.—1 Tímótì 2:3, 4; 2 Tímótì 3:14, 15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́