ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/01 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 26
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 5
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 2/01 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 12

Orin 6

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. A óò jíròrò nípa fídíò náà, The Bible—Mankind’s Oldest Modern Book, ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ February 26. A óò gbé ìjíròrò náà karí àwọn ìbéèrè tó wà lójú ìwé 7 nínú ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí.

15 min: “Máa Fògo fún Jèhófà Nípa Ṣíṣe Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà.”a Fi àlàyé kún un látinú ìwé Proclaimers, ojú ìwé 187, ìpínrọ̀ 2 àti 3.

20 min: “Bí A Ṣe Lè Yí Àwọn Ẹlòmíràn Lérò Padà.” Ìjíròrò láàárín olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan àti aṣáájú ọ̀nà tàbí ògbóṣáṣá akéde kan. A gbé ìjíròrò yìí karí àpilẹ̀kọ yìí àti àwọn kókó tí a yàn látinú Ilé Ìṣọ́ May 15, 1998, ojú ìwé 21 sí 23. Ṣàlàyé àpótí tó wà lójú ìwé 23 tó ní àkọlé náà, “Dídé Inú Ọkàn-Àyà Ẹni Tí O Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́.” Lẹ́yìn yíyan ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn èké kan tó wọ́pọ̀ ní ìpínlẹ̀ yín, jíròrò bí a ṣe lè mú kí ohun tí Bíbélì sọ nípa kókó náà dá ẹnì kan lójú.

Orin 208 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 19

Orin 221

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.

13 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ. Jíròrò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe.”

22 min: “Sọ Orúkọ Jèhófà àti Àwọn Ìbálò Rẹ̀ Di Mímọ̀.”b Kí alàgbà kan ṣàyẹ̀wò àwọn ìwéwèé àkànṣe tí ẹ ti ṣe nínú ìjọ láti mú kí ìgbòkègbodò pọ̀ sí i ní oṣù March àti April, títí kan ìsapá tí ẹ ń ṣe láti fún ọ̀pọ̀ akéde bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó níṣìírí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Jẹ́ kí àwọn kan tí wọ́n ṣe aṣáájú ọ̀nà lóṣù April ọdún tó kọjá sọ nípa ìdùnnú tí ìyẹn fún wọn. Pe àfiyèsí sí ríran gbogbo akéde tí kò ṣiṣẹ́ mọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n tóótun lọ́wọ́ láti tún dara pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ ìsìn àti ríran àwọn ọmọ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mìíràn lọ́wọ́ láti tóótun gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.—Wo Àpótí Ìbéèrè inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2000.

Orin 27 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 26

Orin 48

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù February sílẹ̀.

12 min: Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tí A Dábàá Nípa Bí A Ṣe Lè Fi Ìwé Ìmọ̀ Lọni. Ǹjẹ́ o ní ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan lọ́kàn nípa bí o ṣe lè fi ìwé Ìmọ̀ lọni lóṣù March? Bí o bá wo ojú ìwé tó kẹ́yìn nínú àwọn ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, wàá rí àwọn àbá nípa ohun tí o lè sọ nígbà ìbẹ̀wò àkọ́kọ́, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì ní ohun tí o tún lè sọ nígbà ìpadàbẹ̀wò. Ṣàtúnyẹ̀wò méjì tàbí mẹ́ta lára àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a dábàá wọ̀nyí. (December 1995; March, June, November 1996; June 1997; March 1998) Jẹ́ kí á ṣàṣefihàn àbá méjì tó wà nínú ìtẹ̀jáde ti November 1996 nípa bí a ṣe lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni ní tààràtà. Fún gbogbo akéde níṣìírí pé kí wọ́n sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun.

25 min: “Mímú Kí Àwọn Èèyàn Mọrírì Fídíò The Bible—Mankind’s Oldest Modern Book.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ nípa lílo àwọn ìbéèrè tó wà lójú ìwé 7. Tẹnu mọ́ ọn pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iye Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a ti tẹ̀ jáde ju ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù lọ, tí ó sì wà ní èdè tí ó tó mẹ́tàdínlógójì lápá kan tàbí lódindi, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Bíbélì tí a tíì pín kiri jù lọ. Ní oṣù April, a óò ṣàyẹ̀wò fídíò kẹta nínú ọ̀wọ́ yìí, tí ó ní àkọlé náà, The Bible—Its Power in Your Life. Ní àfidípò, jíròrò “Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Olùfúnni Ọlọ́yàyà.” Kí alàgbà sọ àsọyé yìí tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́ November 1, 1998, ojú ìwé 24 sí 28.

Orin 64 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 5

Orin 81

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

18 min: “Jèhófà Ń Fi Agbára Fúnni.”c Sọ pé kí àwùjọ ṣàlàyé bí a ṣe lè fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn sílò níhìn-ín.

22 min: “Ìjẹ́rìí Orí Tẹlifóònù Tó Ń Yọrí sí Rere.”d Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bójú tó o. Fi ìṣírí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ December 15, 1999, ojú ìwé 23, ìpínrọ̀ 17 kún un. Bí ìrírí èyíkéyìí bá wà, jẹ́ kí á sọ wọ́n ní ṣókí, àwọn tó ní í ṣe pẹ̀lú bí iṣẹ́ yìí ti ń yọrí sí rere ní ìpínlẹ̀ yín. Ní àfidípò, jíròrò “O Ha Ní ‘Ọkàn-Àyà Ìgbọràn’ Bí?” Alàgbà ni kó sọ àsọyé tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́ July 15, 1998, ojú ìwé 25 sí 27 yìí.

Orin 108 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́