Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù February: Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbilọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tó ti pẹ́ tí ìjọ bá ní. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A óò sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, a lè fi ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn lọni. Fi ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí o ní in lọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní March 1 tàbí bí ó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ fi tó ìjọ létí lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bó bá ṣòro fún ẹnikẹ́ni lára wọn láti ní iye wákàtí tí a ń béèrè, kí àwọn alàgbà ṣètò láti ràn án lọ́wọ́. Fún ìdámọ̀ràn, ẹ ṣàtúnyẹ̀wò àwọn lẹ́tà ọlọ́dọọdún náà, S-201, tí Society kọ. Ẹ tún wo ìpínrọ̀ 12 sí 20 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1986.
◼ Kí àwọn ìjọ ṣètò tó rọrùn láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́dún yìí ní ọjọ́ Sunday, April 8, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọyé náà lè bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí kiri kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ àyàfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Ẹ wádìí ládùúgbò láti mọ ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀ lágbègbè yín. Níwọ̀n bí a kò ti ní ṣe ìpàdé mìíràn ní ọjọ́ yẹn àyàfi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kí ẹ ṣe ìyípadà tó bá yẹ kí ẹ lè ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ní àkókò mìíràn. Kí àwọn alábòójútó àyíká ṣe ìyípadà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọn fún ìpàdé ní ọ̀sẹ̀ yẹn ní ìbámu pẹ̀lú bí ipò ìjọ bá ti rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dáa kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tirẹ̀, èyí lè má ṣeé ṣe ní gbogbo ìgbà. Níbi tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan ló jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè gba ilé mìíràn láti lò ní àṣálẹ́ yẹn. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, a dábàá pé ó kéré tán, kí àlàfo ogójì ìṣẹ́jú wà láàárín àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ kí gbogbo ìjọ lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ayẹyẹ náà, kí àkókò lè wà láti kí àwọn àlejò, kí a sì lè fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn níṣìírí. Ó yẹ kí a tún ronú nípa ọ̀ràn ọkọ̀ àti ibi tí a óò gbé wọn sí, títí kan jíjá èrò àti gbígbé èrò. Kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà pinnu ètò tí yóò dára jù lọ nínú ìjọ wọn.
◼ Àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn fún sáà Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2001 ni a ó sọ ní ọjọ́ Sunday, April 1. Àkòrí àsọyé náà ni, “Ta Ní Lè Rí Ìgbàlà?” A ó pèsè ìwé àsọyé. Àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn yóò sọ àkànṣe àsọyé yìí ní ọ̀sẹ̀ April 9. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àkànṣe àsọyé yìí ṣáájú April 1, 2001.
◼ Society ń fẹ́ àwọn arákùnrin tó mọ ọkọ̀ kékeré àti ọkọ̀ ńlá wà dáadáa. Kí ẹnikẹ́ni tó bá mọ̀ pé òun tóótun tó sì fẹ́ láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì kọ̀wé sí Society kó sì béèrè fún fọ́ọ̀mù iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, àyàfi tó bá jẹ́ pé ó ti gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì kan ní àpéjọpọ̀ àgbègbè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí yìí. Ẹni tó bá fẹ́ gba fọ́ọ̀mù yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ arákùnrin tí kò ní ìyàwó, tó sì jẹ ẹni ọdún mọ́kàndínlógún sí ọdún márùndínlógójì.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà:
Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní —Ègùn, Ẹ́fíìkì, Faransé, Gẹ̀ẹ́sì, Ìgbò, Yorùbá
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́? —Gẹ̀ẹ́sì
Ìwọ́ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! —Ègùn, Ẹ́fíìkì, Faransé, Gẹ̀ẹ́sì, Haúsá, Ìgbò, Ísókó, Tiv, Yorùbá
◼ Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kíyè si i pé gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣèfilọ̀ rẹ̀ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2001, Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2002 yóò wáyé ní ọjọ́ Thursday, March 28, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀, kì í ṣe ọjọ́ Friday, March 22 tí a fi hàn nínú ìtẹ̀jáde kàlẹ́ńdà wa ti ọdún 2001.