Sọ Orúkọ Jèhófà àti Àwọn Ìbálò Rẹ̀ Di Mímọ̀
1 “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, ẹ ké pe orúkọ rẹ̀, ẹ sọ àwọn ìbálò rẹ̀ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn. . . . Kí ọkàn-àyà àwọn tí ń wá Jèhófà máa yọ̀.” (Sm. 105:1, 3) Onísáàmù fúnra rẹ̀ tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sílẹ̀ rí ìdùnnú ńláǹlà nínú sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Jèhófà àti nípa “àwọn ìbálò” rẹ̀. Àwọn ìbálò wo ni? Dájúdájú, wọ́n ní í ṣe pẹ̀lú ipò ọba ológo ti Ọlọ́run, wọ́n sì tún ní í ṣe pẹ̀lú “ìhìn rere ìgbàlà rẹ̀.”—Sm. 96:2, 3; 145:11, 12.
2 Bí a ṣe ń sún mọ́ àkókò Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2001, ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kó mú inú wa dùn nípa bí Jèhófà ṣe ń bá wa lò. Lọ́nà wo? Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ni ayẹyẹ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún fún gbogbo Kristẹni tòótọ́. Kò sí ayẹyẹ mìíràn tó dà bíi rẹ̀ báa bá ní ká sọ ti ìjẹ́pàtàkì rẹ̀, ète rẹ̀, tàbí bí a ṣe ń ṣe é. Àkókò nìyí fún gbogbo wa láti rántí ohun tí Jèhófà àti Jésù ti ṣe láti pèsè ọ̀nà ìgbàlà fún wa. Abájọ tó fi jẹ́ pé ní àkókò Ìṣe Ìrántí, a máa ń retí pé kí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá túbọ̀ pọ̀ gan-an, bí a ti ń sọ “ìhìn rere ìgbàlà” di mímọ̀!
3 Ṣé Wàá Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́? Lóṣù April ọdún tó kọjá, àwọn tó forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, iye wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́rìnlá [22,714]. Lọ́dún yìí, ǹjẹ́ a lè mú kí oṣù March àti April jẹ́ oṣù àkànṣe nípa mímú kí ìgbòkègbodò iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa pọ̀ sí i? Sátidé márùn-ún loṣù March ní, tí oṣù April sì ní Sunday márùn-ún. Nípa wíwéwèé láti ṣe iṣẹ́ ìsìn látàárọ̀ ṣúlẹ̀ ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀, ọ̀pọ̀ akéde tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ ti rí i pé àwọn lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Kí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kan lè ní àádọ́ta wákàtí tí a ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ lóṣù, ó yẹ kí ó ní wákàtí méjìlá lọ́sẹ̀ ní ìpíndọ́gba. Fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìṣètò tí a dábàá nínú àpótí tó wà lójú ìwé 4. Ǹjẹ́ èyíkéyìí lára wọn lè bá ipò rẹ mu? Bí kò bá ní bá a mu, bóyá o lè ṣe ètò tìrẹ kí o lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March àti April tó ń bọ̀ yìí.
4 Kí àwọn alàgbà bẹ̀rẹ̀ báyìí láti mú kí àwọn ará ní ìtara kí wọ́n sì ṣètìlẹyìn fún ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn tí a mú pọ̀ sí i. Lọ́dún tó kọjá, nínú ìjọ kan tí gbogbo alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà níbẹ̀ ti forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, mẹ́rìnlélọ́gọ́ta nínú akéde mọ́kànlélọ́gọ́fà tó wà nínú ìjọ ọ̀hún ló ṣe aṣáájú ọ̀nà lóṣù April! Inú ìjọ náà tún dùn láti rí àwọn akéde mẹ́fà tí wọn kò tíì ṣe ìrìbọmi tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ní oṣù March àti April. Ní tòótọ́, àkókò yìí ló dára jù lọ fún àwọn ọmọ àti àwọn ẹni tuntun láti béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà bóyá àwọ́n tóótun láti bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí ní gbangba.
5 Àfikún Ìsapá Ń Mú Ìbùkún Wá: Àwọn ìjọ tó bá gbé góńgó àkànṣe kalẹ̀ tí wọ́n sì ṣe àfikún ìsapá máa ń rí ọ̀pọ̀ ìbùkún. Àwọn ìjọ kan lè fún kíkárí ìpínlẹ̀ tí wọn kì í sábà ṣe ní àfiyèsí pàtàkì, tàbí kí wọ́n tẹra mọ́ ṣíṣe iṣẹ́ ìjẹ́rìí ní àwọn ọ̀nà mìíràn tó jẹ́ àfidípò, tàbí kí wọ́n tẹra mọ́ fífi tẹlifóònù jẹ́rìí, èyí tó jẹ́ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ fún kíkàn sí àwọn tí a kò bá bá nílé àti àwọn tó ń gbé àwọn ilé tí a kò lè dé.
6 Ǹjẹ́ nínú gbogbo ọ̀ràn ló yẹ kí àìlera tàbí ọjọ́ ogbó ṣèdíwọ́ fún èèyàn láti má ṣe kópa nínú iṣẹ́ ìsìn débi tí agbára rẹ̀ bá dé? Kì í ṣe nínú gbogbo ọ̀ràn. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún tí àrùn jẹjẹrẹ sì ń ṣe kò ka ti ẹsẹ̀ rẹ̀ tó wú sí, ṣùgbọ́n ó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April. Ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù mú kó ṣeé ṣe fún un láti kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn, ó sì mú kí ìyìn rẹ̀ sí Jèhófà pọ̀ sí i. Èyí túbọ̀ ta á jí, ó sì ta ìjọ jí pẹ̀lú.
7 Múra Sílẹ̀ Dáadáa fún Ìṣe Ìrántí: Lọ́dún yìí, April 8 ni Ìṣe Ìrántí bọ́ sí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ ọjọ́ Sunday, ó yẹ kí ó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti wá. Àwọn èèyàn tó máa wá lè pọ̀ ju ti ìgbàkigbà rí lọ bí a bá ṣe ipa tiwa nípa (1) wíwà níbẹ̀ wa fúnra wa àti (2) kíké sí àwọn ẹlòmíràn láti dara pọ̀ mọ́ wa níbi Ìṣe Ìrántí náà. Àwọn wo ló yẹ ká ké sí?
8 Wo àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìsìn pápá tìrẹ láti lè mọ orúkọ àwọn tó ti fi ìfẹ́ hàn sí òtítọ́, kódà bí o kì í bá dé ọ̀dọ̀ wọn déédéé. Ní ọ̀sẹ̀ méjì tàbí mẹ́ta ṣáájú Ìṣe Ìrántí náà, tẹra mọ́ ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí láti fún wọn ní ìwé tí a fi ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìṣe Ìrántí. Bí ipò rẹ bá gbà ọ́ láyè, yọ̀ǹda láti pèsè ohun ìrìnnà fún àwọn tó bá fẹ́ wá.
9 Ní àwọn ìjọ kan, wọn ò lo gbogbo ìwé tí a tẹ̀ láti fi pe àwọn èèyàn wá sí Ìṣe Ìrántí tán. Kí àwọn akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé àwọ́n tètè fún gbogbo àwọn ará ní ìwé ìkésíni náà kí wọ́n lè ní àkókò tó pọ̀ tó láti fi pín wọn. Ẹ lè tẹ àkókò àti ibi tí ẹ ó ti ṣe Ìṣe Ìrántí sí ìsàlẹ̀ ìwé ìkésíni náà, ẹ sì lè fi ọwọ́ kọ ọ́ nigínnigín. Tàbí kẹ̀, ẹ lè fi ìwé ìléwọ́ tó ń fi àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba hàn kún un bó bá jẹ́ pé ibẹ̀ ni ẹ ó ti ṣe Ìṣe Ìrántí. A fẹ́ rán yín létí pé, lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe la gbọ́dọ̀ fúnra wa fún onílé ní ìwé ìkésíni sí Ìṣe Ìrántí.
10 Ẹ Rántí Àwọn Aláìṣiṣẹ́ Mọ́: Ó máa ń mú inú wa dùn nígbà tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà tó sì fi ẹ̀rí ìyẹn hàn nípa ìrìbọmi. Ṣùgbọ́n, lọ́dọọdún, àwọn kan tó wà láàárín wa máa ń jáwọ́ nínú dídara pọ̀ pẹ̀lú wa, wọ́n á sì jáwọ́ nínú sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa orúkọ Jèhófà àti nípa àwọn ìbálò rẹ̀. Ó yẹ gidigidi pé ká ṣàníyàn nípa wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ kò tíì kọ òtítọ́ sílẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìrẹ̀wẹ̀sì, ìṣòro tí wọ́n ní, tàbí àwọn àníyàn mìíràn ní ìgbésí ayé ló mú kí wọ́n ṣíwọ́ wíwàásù. (Mát. 13:20-22) Àwọn tí kò lera nípa tẹ̀mí nílò ìrànwọ́ láti padà sínú ìjọ kó tó di pé ètò Sátánì gbé wọn mì. (1 Pét. 5:8) Ní àkókò Ìṣe Ìrántí yìí, a fẹ́ sapá lákànṣe láti ran gbogbo àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ tí wọ́n tóótun lọ́wọ́ kí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú wíwàásù ìhìn rere náà.
11 Kí akọ̀wé ìjọ jẹ́ kí àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ mọ̀ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwùjọ wọn tó bá jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́. Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ ni yóò mú ipò iwájú ní ṣíṣètò fún ṣíṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ gbogbo àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́. Bí wọ́n bá pinnu pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò jàǹfààní bí a bá bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, alábòójútó iṣẹ́ ìsìn yóò ṣètò bí wọn á ṣe ran ẹni náà lọ́wọ́ lẹ́yìn tó bá ti fikùn lukùn pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà yòókù nínú ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn láti mọ ẹni tó yẹ jù lọ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pọndandan pé kí ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gba sáà gígùn, ẹni tí wọ́n yàn láti máa darí rẹ̀ lè ròyìn wákàtí tó fi ń ṣe é, ó sì lè ròyìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpadàbẹ̀wò, àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
12 Ní oṣù April ọdún tó kọjá, arábìnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ láti ilé dé ilé fi ìwé ìròyìn lọ ọ̀dọ́kùnrin kan ní òpópónà. Ọkùnrin náà sọ pé ìyàwó òun jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí kò ṣiṣẹ́ mọ́. Ó béèrè ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà, ó sì sọ pé kí arábìnrin náà bẹ òun àti ìyàwó òun wò. Ní àbájáde rẹ̀, tọkọtaya yìí wá sí ìpàdé tí wọ́n ṣe lẹ́yìn náà, wọ́n sì gbà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
13 Múra Sílẹ̀ fún Ìgbòkègbodò Tí A Mú Pọ̀ Sí I! Onísáàmù tó polongo pé ká sọ orúkọ Jèhófà àti àwọn ìbálò rẹ̀ di mímọ̀ fi kún un pé: “Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin atunilára sí i, ẹ máa fi gbogbo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ ṣe ìdàníyàn yín. Ẹ máa ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀.” (Sm. 105:2, 3) Ẹ jẹ́ ká máa fi ìdàníyàn wa hàn fún orúkọ ńlá Jèhófà àti fún “àwọn iṣẹ́ àgbàyanu” rẹ̀ nípa títúbọ̀ sapá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí á mú kí àkókò Ìṣe Ìrántí yìí jẹ́ èyí tó tíì ga lọ́lá jù lọ!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Onírúurú Ọ̀nà Tí A Lè Gbà Ṣètò Wákàtí 12 Lọ́sẹ̀ Láti Lè Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́
Ọjọ́ Wákàtí
Monday 1 2 − −
Tuesday 1 − 3 −
Wednesday 1 2 − 5
Thursday 1 − 3 −
Friday 1 2 − −
Saturday 5 4 3 5
Sunday 2 2 3 2
Àròpọ̀: 12 12 12 12
Ǹjẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìṣètò yìí á ṣiṣẹ́ fún ọ? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ló dé tí o kò ṣe ètò tìrẹ?