Máa Bá A Nìṣó Láti Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Jèhófà
1. Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà tó o mọrírì gan-an?
1 Kò sẹ́ni tó dà bí Jèhófà, Ọlọ́run wa títóbi! Dáfídì kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa; kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé.” (Sm. 40:5) Lára àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà ni ṣíṣẹ̀dá tó ṣẹ̀dá àgbáyé wa, Ìjọba Mèsáyà, àwọn ohun tó ń ṣe láti fi inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn sí àwọn èèyàn rẹ̀, àti iṣẹ́ ìwàásù jákèjádò ayé. (Sm. 17:7, 8; 139:14; Dán. 2:44; Mát. 24:14) Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà àti ìmọrírì wa fún gbogbo ohun tó ti ṣe ń sún wa láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. (Sm. 145:5-7) Ní oṣù March, April àti May, a óò láǹfààní láti túbọ̀ ṣe èyí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.
2. Báwo ni àwa fúnra wa ṣe ń jàǹfààní nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
2 Ṣíṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́: Ǹjẹ́ o lè ṣètò àwọn ìgbòkègbodò rẹ kó o lè lo àádọ́ta wákàtí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn oṣù àkànṣe ìgbòkègbodò yìí? Ó dájú pé àtúntò tó o bá ṣe nínú ìgbòkègbodò rẹ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Éfé. 5:16) Ọ̀pọ̀ ti rí i pé ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Ara wọn máa ń túbọ̀ balẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà onílé, wọ́n sì túbọ̀ máa ń láǹfààní láti lo Bíbélì. Lílo àkókò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń mú kó rọrùn fún wọn láti lè túbọ̀ ṣèrànwọ́ fáwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n bá rí, àwọn kan tí wọn kò sì tíì rẹ́ni bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ọ̀kan nígbà tí wọ́n ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Nítorí pé iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ máa ń jẹ́ ká lè ṣèrànwọ́ gan-an fáwọn ẹlòmíràn, ó jẹ́ iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀.—Ìṣe 20:35.
3. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún àwọn kan láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kódà nínú àwọn ipò tí kò rọrùn?
3 Má kàn yára parí èrò sí pé ipò rẹ ò lè yọ̀ǹda fún ọ láti ṣe é. Alàgbà kan tó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ́dún tó kọjá ní ọmọ méjì láti bójú tó, bẹ́ẹ̀ ló sì tún ń ṣe iṣẹ́ tó ń gba ọ̀pọ̀ àkókò. Ọgbọ́n wo ni arákùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí yìí dá? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àárín ọ̀sẹ̀ ló máa ń lọ síbi iṣẹ́, ó wéwèé láti máa pẹ́ gan-an lóde ẹ̀rí láwọn òpin ọ̀sẹ̀, ó sì máa ń kọ́kọ́ jẹ́rìí ní òpópónà ní aago méje òwúrọ̀ lọ́jọ́ Sátidé. Ọ̀pọ̀ àwọn akéde ìjọ yẹn tí wọ́n wà ní irú ipò kan náà ṣe aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú, wọ́n ṣètìlẹyìn fún ara wọn, wọ́n sì tún fún ara wọn níṣìírí. Nínú ìjọ mìíràn, arábìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún pinnu láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù May nígbà tí ọmọ rẹ̀ obìnrin sọ pé kó jẹ́ káwọn jọ ṣe é. Àwọn mìíràn nínú ìjọ náà máa ń bá arábìnrin àgbàlagbà yìí ti àga onítáyà rẹ̀ kó lè ṣeé ṣe fún un láti máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé àti láti máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó tún máa ń kópa nínú ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù, ìjẹ́rìí ní òpópónà àti lẹ́tà kíkọ. Ó mọ̀ dájú pé kì í ṣe agbára òun lòun fi lè ṣe èyí, nípasẹ̀ ìrànwọ́ Jèhófà ni.—Aísá. 40:29-31.
4. Àwọn ohun wo la lè gbé yẹ̀ wò nígbà tá a bá ń ṣètò láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
4 Gbìyànjú láti kọ ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tó máa bá ipò rẹ mu jù lọ sílẹ̀. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Ṣé iṣẹ́ tó ń gba ọ̀pọ̀ àkókò lò ń ṣe àbí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ni ọ́? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣíṣètò láti máa lo òpin ọ̀sẹ̀ fún jíjáde òde ẹ̀rí ló máa dára jù fún ọ. Bó o bá ní àìlera tí agbára rẹ ò sì gbé e láti máa pẹ́ púpọ̀ lóde ẹ̀rí, ó lè jẹ́ pé ṣíṣètò láti máa lo àkókò díẹ̀ lójoojúmọ́ ló máa dára fún ọ. Bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ rẹ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ó ṣeé ṣe kí àwọn náà fi ṣe góńgó wọn.
5. Àwọn góńgó wo làwọn ọ̀dọ́ lè máa lépa ní oṣù March, April àti May?
5 Àwọn Ọ̀nà Táwọn Ọ̀dọ́ Lè Gbà Kópa Nínú Iṣẹ́ Yìí: Inú Jèhófà máa ń dùn nígbà táwọn èwe bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀. (Sm. 71:17; Mát. 21:16) Bó o bá jẹ́ ọ̀dọ́ tó o sì ti ṣèrìbọmi, o lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù tó o bá wà ní àkókò ìsinmi ilé ẹ̀kọ́. Bí o kò bá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ǹjẹ́ o lè gbé àwọn góńgó kan pàtó kalẹ̀ láti lè túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, kó o sì mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ túbọ̀ dára sí i nínú àwọn oṣù wọ̀nyí? Bó o bá ti ń bá àwọn òbí rẹ jáde òde ẹ̀rí àmọ́ tó ò tíì di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, ìsinsìnyí ni àkókò tí yóò dára jù fún ọ láti gbìyànjú láti di akéde. Kò yẹ kó o ronú pé ó dìgbà tó o bá mọ àwọn ìbéèrè inú Bíbélì dáhùn dáadáa tàbí pé o gbọ́dọ̀ mọ ọ̀pọ̀ nǹkan bíi tàwọn àgbàlagbà tó ti ṣèrìbọmi kó o tó di akéde. Ǹjẹ́ o lóye àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ inú Bíbélì? Ǹjẹ́ ò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì? Ǹjẹ́ o fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ ọ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí àwọn òbí rẹ mọ̀ nípa èyí. Wọ́n lè ṣètò pé kí ìwọ àtàwọn lọ rí àwọn alàgbà láti mọ̀ bóyá o tóótun.—Wo ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 98 àti 99.
6. Báwo la ṣe lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti di akéde ìhìn rere?
6 Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Wàásù: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú lè tóótun láti dara pọ̀ mọ́ wa gẹ́gẹ́ bí akéde ní àwọn oṣù àkànṣe ìgbòkègbodò tó ń bọ̀ yìí. Bí ẹnì kan tó ò ń bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ń tẹ̀ síwájú dáadáa, sọ fún alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ tàbí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ síwájú sí i. Ọ̀kan lára wọn lè wà pẹ̀lú yín nígbà tẹ́ ẹ bá ń kẹ́kọ̀ọ́ láti mọ bí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú sí. Bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá tóótun tó sì fẹ́ láti di akéde, alábòójútó olùṣalága lè ṣètò pé kí àwọn alàgbà méjì pàdé pọ̀ pẹ̀lú ìwọ àti akẹ́kọ̀ọ́ náà. (Wo Ilé Ìṣọ́nà, November 15, 1988, ojú ìwé 17.) Bí wọ́n bá fọwọ́ sí i pé akẹ́kọ̀ọ́ náà ti tóótun láti di akéde, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lójú ẹsẹ̀.
7. Báwo la ṣe lè ran àwọn aláìṣedéédéé àtàwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́?
7 Ó yẹ kí àwọn alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ pe àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ tàbí aláìṣedéédéé nínú àwùjọ wọn. Ní kí wọ́n bá ọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Bó bá jẹ́ pé ó ti pẹ́ gan-an tí wọ́n ti jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́, á dára pé kí àwọn alàgbà méjì kọ́kọ́ bá wọn sọ̀rọ̀ láti mọ̀ bóyá wọ́n ṣì tóótun. (Wo Àpótí Ìbéèrè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2000.) Ìtara àwọn ará nínú ìjọ láwọn oṣù àkànṣe ìgbòkègbodò wọ̀nyí lè ta wọ́n jí kí wọ́n tún máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lẹ́ẹ̀kan sí i.
8, 9. Kí làwọn alàgbà lè ṣe láti ta àwọn ará jí fún àkànṣe ìgbòkègbodò náà?
8 Múra Sílẹ̀ Nísinsìnyí fún Ìgbòkègbodò Púpọ̀ Sí I: Ẹ̀yin alàgbà, ẹ bẹ̀rẹ̀ láti ìsinsìnyí lọ láti máa sọ ọ̀rọ̀ tí yóò ta àwọn ará jí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ẹ lè ṣe bẹbẹ nípa sísọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró àti nípa àpẹẹrẹ rere yín. (1 Pét. 5:3) Báwo làwọn tó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní ìjọ yín ṣe pọ̀ tó lọ́dún tó kọjá? Ǹjẹ́ a lè kọjá iye yẹn lọ́dún yìí? Ó yẹ kí àwọn alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ àtàwọn olùrànlọ́wọ́ wọn wá ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fún gbogbo àwọn tó wà ní àwùjọ wọn níṣìírí láti mú kí ìgbòkègbodò wọn pọ̀ sí i. Àwọn alábòójútó iṣẹ́ ìsìn lè ṣètò àfikún ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn sí i. Ẹ jẹ́ kí ìjọ mọ̀ ṣáájú àkókò nípa àwọn ètò tẹ́ ẹ ṣe. Ẹ rí i dájú pé àwọn akéde tó tóótun la yàn láti múpò iwájú, àti pé, a bẹ̀rẹ̀ àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn lákòókò a sì parí wọn lákòókò. (Wo Àpótí Ìbéèrè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2001.) Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tún ṣètò láti rí i pé ìpínlẹ̀ tó pọ̀ tó wà, àti pé ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó máa tó láti fi ṣiṣẹ́ wà.
9 Lọ́dún tó kọjá, àwọn alàgbà ìjọ kan ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ tí yóò ta àwọn ará jí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àwọn oṣù àkànṣe ìgbòkègbodò náà, ọ̀pọ̀ lára wọn sì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Wọ́n ṣètò àfikún ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn sí i: ọ̀kan ní aago márùn-ún àbọ̀ ìdájí fún ìjẹ́rìí ní òpópónà, òmíràn ní aago mẹ́ta ọ̀sán fún àwọn tó bá kúrò ní ilé ẹ̀kọ́, àti òmíràn ní aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ fún àwọn tó bá kúrò níbi iṣẹ́. Síwájú sí i, ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn mẹ́ta ni wọ́n ṣètò fún gbogbo ọjọ́ Sátidé. Àbájáde èyí ni pé àwọn akéde ìjọ tó tó mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] ló ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù April!
10. Báwo làwọn ìdílé ṣe lè múra sílẹ̀ láti túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́?
10 Ẹ ò ṣe ya àkókò sọ́tọ̀ nígbà tẹ́ ẹ bá tún ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé láti fi gbé àwọn góńgó tó ṣeé lé bá kalẹ̀ fún àwọn oṣù tó ń bọ̀? Bẹ́ ẹ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ tẹ́ ẹ sì ṣètò àwọn ìgbòkègbodò yín dáadáa, ó ṣeé ṣe kí àwọn kan nínú ìdílé yín tàbí gbogbo yín pàápàá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Bí ìyẹn ò bá ṣeé ṣe, ẹ gbé góńgó kalẹ̀ láti túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ nípa mímú kí àkókò tẹ́ ẹ sábà máa ń lò lóde ẹ̀rí pọ̀ sí i tàbí nípa wíwàásù láwọn ìgbà mìíràn yàtọ̀ sí ìgbà tí ìjọ ṣètò. Kí gbogbo ìdílé fi ọ̀ràn yìí sí àdúrà. Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé Jèhófà yóò bù kún ìsapá yín.—1 Jòh. 3:22.
11. (a) Àwọn nǹkan àgbàyanu wo ni ẹbọ Kristi mú kó ṣeé ṣe? (b) Àkókò wo ni ìjọ tiwa máa ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí, ibo la sì ti máa ṣe é?
11 Iṣẹ́ Ọlọ́run Tó Jẹ́ Àgbàyanu Jù Lọ: Ìfẹ́ gíga jù lọ tí Jèhófà fi hàn sí wa ni ẹ̀bùn Ọmọ rẹ̀ tó fún wa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà. (1 Jòh. 4:9, 10) Ẹbọ ìràpadà yìí ni ọ̀nà tó tọ́ láti ra ìran èèyàn padà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 3:23, 24) Ẹ̀jẹ̀ Jésù tí a ta sílẹ̀ ló fìdí májẹ̀mú tuntun múlẹ̀, ìyẹn ni pé ó mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ẹ̀dá èèyàn aláìpé láti di ẹni tí a gbà ṣọmọ gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run, tí wọ́n sì tún ń fojú sọ́nà láti ṣàkóso nínú Ìjọba ọ̀run. (Jer. 31:31-34; Máàkù 14:24) Ní pàtàkì jù lọ, bí Jésù ṣe ṣègbọràn sí Ọlọ́run ní kíkún ya orúkọ Jèhófà sí mímọ́. (Diu. 32:4; Òwe 27:11) Ní Sunday, April 4, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀, a óò ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Kristi jákèjádò ayé.
12. Báwo ni wíwá sí ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ṣe lè ṣe àwọn olùfìfẹ́hàn láǹfààní?
12 Ṣíṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ń gbé àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà ga. Àwíyé tá a ó sọ níbẹ̀ á jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì ohun tí Jèhófà ti ṣe nípa pípèsè ìràpadà. Àwọn olùfìfẹ́hàn tó bá wá yóò lè kíyè sí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run mìíràn. Á ṣeé ṣe fún wọn láti rí ìṣọ̀kan àti ìfẹ́ àtọkànwá tí Jèhófà ti kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ láti máa fi hàn. (Éfé. 4:16, 22-24; Ják. 3:17, 18) Wíwá sí ayẹyẹ pàtàkì yìí lè ní ipa tí kì í ṣe kékeré lórí ìrònú ẹni, nípa bẹ́ẹ̀ a fẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó wá.—2 Kọ́r. 5:14, 15.
13, 14. Ta ló yẹ ká ké sí wá sí Ìṣe Ìrántí, báwo la ó sì ṣe ṣe èyí?
13 Kíké sí Àwọn Ẹlòmíràn Láti Wá: Ìsinsìnyí ni kó o bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ nípa ṣíṣe àkọsílẹ̀ àwọn tó o fẹ́ ké sí. Lára àwọn tó yẹ kó wà nínú àkọsílẹ̀ rẹ ni àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tí kì í ṣe Kristẹni, àwọn aládùúgbò, àwọn ojúlùmọ̀ níbi iṣẹ́ tàbí nílé ẹ̀kọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ nígbà kan rí àti nísinsìnyí àti gbogbo àwọn ìpadàbẹ̀wò rẹ. Kí àwọn alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ fi àwọn akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ kún àkọsílẹ̀ wọn.
14 Lo ìwé ìkésíni sí Ìṣe Ìrántí tá a tẹ̀, kó o sì fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tẹ àkókò àti ibi tí Ìṣe Ìrántí náà yóò ti wáyé sára ìwé ìkésíni náà tàbí kó o fọwọ́ kọ ọ́ kó hàn ketekete. Yàtọ̀ síyẹn, o lè lo ìkésíni tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ March 15, 2004 tàbí Jí! April 8, 2004,. Bí April 4 ṣe ń sún mọ́lé, máa rán àwọn tí orúkọ wọn wà nínú àkọsílẹ̀ rẹ létí, bóyá nípa lílọ sọ́dọ̀ wọn tàbí nípa lílo tẹlifóònù láti kàn sí wọn.
15. Báwo la ṣe lè ṣaájò àwọn àlejò lọ́jọ́ Ìṣe Ìrántí?
15 Níbi Ìṣe Ìrántí: Gbìyànjú láti tètè dé lọ́jọ́ Ìṣe Ìrántí. Ṣaájò àwọn ẹni tuntun nípa kíkí wọn tọ̀yàyàtọ̀yàyà. (Róòmù 12:13) O ní ojúṣe pàtàkì kan láti ṣe fún àwọn àlejò tó o pè wá. Ṣe àyẹ́sí wọn, kó o sì fi wọ́n han àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ. Bóyá o lè bá wọn wá ìjókòó sítòsí rẹ. Bí èyíkéyìí lára wọn ò bá sì ní Bíbélì tàbí ìwé orin, sọ pé kí wọ́n máa wo tìẹ tàbí kó o sọ pé kí ẹlòmíràn jẹ́ kí wọ́n bá a lo tiẹ̀. Lẹ́yìn ayẹyẹ náà, má jìnnà sí wọn kó o lè dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí tí wọ́n bá ní. Bó bá jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí àwọn kan máa wá, béèrè bóyá wọ́n á fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ sí i nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ète rẹ̀. Sọ pé wàá fẹ́ láti bá wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
16. Kí la lè ṣe láti ran àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí?
16 Máa Bá A Nìṣó Láti Ran Àwọn Tó Wá Lọ́wọ́: Ní àwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé Ìṣe Ìrántí, ó ṣeé ṣe kí àwọn tó wá nílò ìrànwọ́ síwájú sí i. Lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ làwọn tó ti máa ń wá sípàdé nígbà kan rí àmọ́ tó jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ dara pọ̀ mọ́ ìjọ mọ́. Àwọn alàgbà yóò wà lójúfò láti rí i pé a ò fojú pa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ rẹ́. Kí wọ́n gbìyànjú láti mọ ìdí tí wọ́n fi dáwọ́ títẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí dúró. Kí wọ́n tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn pé àkókò tí kò ṣeé fi jáfara là ń gbé yìí. (1 Pét. 4:7) Ran gbogbo àwọn tó wá lọ́wọ́ láti rí àǹfààní tó wà nínú ṣíṣègbọràn sí ìṣílétí Ìwé Mímọ́ pé ká máa péjọ déédéé pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run.—Héb. 10:24, 25.
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bá a nìṣó láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà?
17 Àwọn iṣẹ́ Jèhófà jẹ́ àgbàyanu gidigidi fún wa débi pé a ò lè lóye wọn tán pátápátá, kódà bí a bá wàláàyè títí láé. (Jóòbù 42:2, 3; Oníw. 3:11) Nítorí èyí, kò ní sí ìgbà kan láé tí a kò ní rí àwọn ohun tí a ó fi máa yìn ín. Ní àkókò Ìṣe Ìrántí yìí, a lè fi ìmọrírì wa hàn fún àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà nípa ṣíṣe ìsapá àkànṣe láti túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 5]
Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Tó O Bá Lo Ọ̀kan Lára Àwọn Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Wọ̀nyí?
March Su M* Tu* W* Th F Sa Oṣù Àròpọ̀
Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan 2 1 1 1 1 1 5 51
Ọjọ́ Méjì 0 5 0 5 0 0 0 50
Òpin Ọ̀sẹ̀ Nìkan 5 0 0 0 0 0 8 52
Òpin Ọ̀sẹ̀ àti Ọjọ́
Méjì Láàárín Ọ̀sẹ̀ 2 0 0 2 0 2 6 50
April Su M Tu W Th* F* Sa Oṣù Àròpọ̀
Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan 2 1 1 1 1 1 5 50
Ọjọ́ Méjì 0 0 0 0 5 5 0 50
Òpin Ọ̀sẹ̀ Nìkan 5 0 0 0 0 0 8 52
Òpin Ọ̀sẹ̀ àti Ọjọ́
Méjì Láàárín Ọ̀sẹ̀ 2 0 0 2 0 2 6 50
May Su* M* Tu W Th F Sa* Oṣù Àròpọ̀
Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan 2 1 1 1 1 1 4 51
Ọjọ́ Méjì 0 5 0 0 0 0 5 50
Òpin Ọ̀sẹ̀ Nìkan 3 0 0 0 0 0 7 50
Òpin Ọ̀sẹ̀ àti Ọjọ́
Méjì Láàárín Ọ̀sẹ̀ 2 0 0 2 0 2 5 51
* Márùn-ún láàárín oṣù