Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 12
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 12
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 19-22
No. 1: 1 Sámúẹ́lì 21:1-9
No. 2: Ojú Wo Ló Yẹ Ká Máa Fi Wo Àwọn Ohun Tí Jèhófà Kórìíra? (Òwe 6:16-19)
No. 3: Ṣó Yẹ Kí Kristẹni Máa Jọ́sìn Àgbélébùú? (td 2B)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn Nípa Mímú Kí Àwọn Olùgbọ́ Rẹ Ronú. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 58, ìpínrọ̀ 3, sí ìparí ìsọ̀rí tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 59.
20 min: “Jẹ́ Kí Ẹ̀kọ́ Rẹ Máa Yíni Lérò Pa Dà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 4, ní kí aṣáájú-ọ̀nà kan lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.