Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
Ẹ̀yin Ará Wa Ọ̀wọ́n Tá A Jọ Jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà:
Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ la ní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run! Orúkọ yẹn máa wà títí láé, kò lè pa run, kò sì láfiwé. Jèhófà ló ní ká máa jẹ́ orúkọ mọ́ òun, láti ọdún 1931 sì ni àwọn èèyàn ti fi orúkọ yẹn mọ̀ wá. (Aísá. 43:10) Ojú kì í tì wá láti fi ara wa hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Èṣù kò yé gbìyànjú láti pa orúkọ Ọlọ́run rẹ́. Ó ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè máa fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra orúkọ Jèhófà. Bábílónì Ńlá tó jẹ́ ilẹ̀ ọba ẹ̀sìn èké àgbáyé, kórìíra orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì ti yọ ọ́ kúrò nínú ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì. Ohun tí Jésù ṣe yàtọ̀ pátápátá, orúkọ yẹn ló fi sí ipò àkọ́kọ́ nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.’” (Mát. 6:9) Nígbà tó yá, ó sọ nínú àdúrà àtọkànwá kan tó gbà sí Baba rẹ̀ pé: “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn ènìyàn tí ìwọ fi fún mi láti inú ayé.” (Jòh. 17:6) Níwọ̀n bó ti wù wá láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ju ti ìgbàkígbà rí lọ, a ti pinnu láti lo ara wa tokuntokun láti kéde orúkọ Jèhófà kárí ayé.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2009 tó sọ pé, “Jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìnrere,” ti mú ká ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún. (Ìṣe 20:24) Kò sí àní-àní pé Jèhófà bù kún iṣẹ́ ìsìn wa ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá. A jẹ́rìí lọ́nà tó lágbára kárí ayé sí ògo àti ọlá orúkọ Jèhófà. Àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ mílíọ̀nù méje, ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàje àti àádọ́sàn lé mẹ́ta [7,313,173] tí wọ́n pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ló wàásù fún gbogbo èèyàn, tí wọ́n sì kọ́ àwọn olóòótọ́ ọkàn tó ń wá ojútùú sí ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń dojú kọ wọ́n lójoojúmọ́. Bí àwọn tí iye wọn jẹ́ mílíọ̀nù méjìdínlógún, ẹ̀rìnlélọ́gọ́rin, ọ̀ọ́dúnrún àti mẹ́tàlélógún [18,168,323] ṣe wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tá a ṣe kọjá fi hàn pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ṣì lè wá pe orúkọ Jèhófà kí òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí tó dé.
Bí Jèhófà bá fẹ́, a óò máa bá a nìṣó láti máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, nípa lílo gbogbo ọ̀nà tó bá ṣeé ṣe láti wàásù fún àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. (Mát. 24:14; Máàkù 13:10) Yálà à ń wàásù láti ilé dé ilé, lójú pópó, nípasẹ̀ lẹ́tà àti tẹlifóònù tàbí láìjẹ́ bí àṣà, ẹ jẹ́ ká máa sapá láti sọ orúkọ Jèhófà àti ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé di mímọ̀ fún ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó.
Ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro wà pé Jèhófà máa tó sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. (Ìsík. 36:23) Ó máa tó mú ìparun dé bá gbogbo àwọn tó ń bà á lórúkọ jẹ́. Ẹ wo irú ọjọ́ ológo tí ìyẹn máa jẹ́ fún gbogbo àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Jèhófà, tí wọ́n sì ti ṣètìlẹ́yìn fún ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láyé àtọ̀run!
A rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Jèhófà ń bójú tó wa tìfẹ́tìfẹ́ nígbà Àpéjọ Àgbègbè àti Àpéjọ Àgbáyé “Ẹ Máa Ṣọ́nà!” tá a ṣe lọ́pọ̀ ibi kárí ayé lọ́dún 2009. Àwọn àpéjọ wọ̀nyẹn jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé nínú ìtàn àwa èèyàn Jèhófà, ó sì jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ wà lójúfò bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé.—Máàkù 13:37; 1 Tẹs. 5:1, 2, 4.
Kò sí àní-àní pé Jèhófà ti ṣe ohun rere fún wa, ó ń jẹ́ kí ọkàn wa kún fún ayọ̀. Ó mú ká dùbúlẹ̀ ní pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko, ó sì ń darí wa lọ sí àwọn ibi ìsinmi tó lómi dáadáa.—Sm. 23:1, 2; 100:2, 5.
Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé Jèhófà á túbọ̀ máa bù kún yín bẹ́ ẹ ṣe ń jẹ́ kí ọwọ́ yín dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ìjọba rẹ̀ lọ́dún iṣẹ́ ìsìn yìí!
A nífẹ̀ẹ́ gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ ara wa kárí ayé gan-an ni.
Àwa arákùnrin yín,
Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà