Ṣó O Máa Ń Ṣalágbàwí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
1 Nínú ayé táwọn èèyàn ò ti gba Bíbélì gbọ́ yìí, ńṣe làwọn Kristẹni tòótọ́ ń fi ìtara ṣalágbàwí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Níwọ̀n bó ti dá wa lójú pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,” a gbà pé òótọ́ ni gbólóhùn tí Jésù Kristi sọ nígbà tó ń gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (2 Tím. 3:16; Jòh. 17:17) Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè ṣalágbàwí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́?
2 Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́: Kò síyè méjì pé Jésù fi ara rẹ̀ fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí ló mú kó ṣeé ṣe fún un láti máa kọ́ àwọn èèyàn látinú Ìwé Mímọ́ jálẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Lúùkù 4:16-21; 24:44-46) Báwo la ṣe lè mọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a nílò sórí? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa kíka Bíbélì lójoojúmọ́ àti nípa ṣíṣàṣàrò lórí ẹsẹ kan tá a bá rí i pé ó máa dáa gan-an láti fi gbani níyànjú tàbí tó máa wúlò gan-an lóde ẹ̀rí. Bá a bá ń múra ìpàdé sílẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá wà níbẹ̀ tààràtà látinú Bíbélì, ká sì múra sílẹ̀ láti fa kókó inú rẹ̀ yọ. Bá a bá wà nípàdé, ẹ jẹ́ ká máa fojú bá ibi tí olùbánisọ̀rọ̀ ń kà lọ nínú Bíbélì wa. Bá a bá ṣe ń jẹ́ kí ẹsẹ Bíbélì tá a mọ̀ pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe máa ṣeé ṣe fún wa tó láti ‘fi ọwọ́ tó tọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.’—2 Tím. 2:15.
3 Máa Lo Bíbélì Rẹ: Bá a bá wà lóde ẹ̀rí, a gbọ́dọ̀ máa lo Bíbélì wa. Bí àpẹẹrẹ, níbi tó bá ti ṣeé ṣe, a gbọ́dọ̀ sapá láti ka ẹsẹ Bíbélì kan, ká sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú onílé. Bó bá béèrè ìbéèrè tàbí bó bá sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ tí kò jẹ́ kó gba ohun tá a sọ gbọ́, ohun tó dáa jù ni pé ká lo Bíbélì láti fi yanjú ọ̀ràn náà. Bí onílé bá sọ pé ọwọ́ òun dí, a ṣì lè fa kókó kan yọ látinú Bíbélì nípa sísọ pé, “Kí n tó lọ, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣoṣo yìí.” Nígbàkigbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà jáde látinú Bíbélì ní tààràtà, bó o sì ṣe ń kà á, jẹ́ kí onílé máa fojú bá ohun tó ò ń kà lọ.
4 Nígbà tí wọ́n fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ pé kò sí ohun tó ń jẹ́ Mẹ́talọ́kan nínú Bíbélì han ọkùnrin kan, ńṣe ló pariwo pé: “Látọjọ́ tí mo ti n lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, mi ò mọ̀ pé irú ohun tó jọ èyí wà nínú Bíbélì!” Lọ́gán ló gbà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Jésù sọ pé àwọn àgùntàn òun á fetí sí ohùn òun. (Jòh. 10:16, 27) Ọ̀nà tó dáa jù lọ fáwọn olóòótọ́ ọkàn láti gbà dá òtítọ́ mọ̀ ni pé kí wọ́n fojú ara wọn rí i nínú Ìwé Mímọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣalágbàwí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!