Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 14
Orin 205
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù May sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ May 15 àti Jí! April-June. (Lo àbá kẹta lójú ìwé 8 fún Jí! April-June.)
20 min: Bá A Ṣe Ń Ṣètìlẹ́yìn fún Iṣẹ́ Ìwàásù ní Àwọn Ìjọ àti Káàkiri Àgbáyé. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 12.
15 min: “Ó Ń Fi Agbára fún Ẹni Tí Ó Ti Rẹ̀.”a Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ.
Orin 1 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 21
Orin 41
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò Àpótí Ìbéèrè.
15 min: “Àǹfààní Wà Nínú Kéèyàn Yọ̀ǹda Ara Ẹ̀ Láti Ran Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́.”b Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n sábà máa ń fínnú fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn. Àwọn ọ̀nà wo ni wọ́n ti gbà yọ̀ǹda ara wọn? Àwọn nǹkan wo ni wọ́n pa tì kí wọ́n bàa lè yọ̀ǹda ara wọn, kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Àǹfààní wo ni wọ́n sì ní nítorí pé wọ́n yọ̀ǹda ara wọn?
20 min: “Ṣó O Máa Ń Ṣalágbàwí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?”c Fi àlàyé kún un látinú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, àwọn àpótí tó wà lójú ìwé 143 àti 144.
Orin 202 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 28
Orin 46
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù May sílẹ̀. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ June 1 àti Jí! April-June. (Lo àbá kẹrin lójú ìwé 8 fún Jí! April-June.)
20 min: Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé la ó lò lóṣù June. Mẹ́nu ba àwọn nǹkan kan tó fani mọ́ra nípa ìwé náà, kó o sì jíròrò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 1999. Lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó máa bá ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé náà. Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ nípa báwọn ojúlùmọ̀ tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí wọ́n fún níwèé yìí ṣe mọrírì rẹ̀ tó.
15 min: Ìrírí Táwọn Ará Ní Lóde Ẹ̀rí. Ní káwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ àtàwọn akéde mìíràn tí wọ́n ṣiṣẹ́ kára láti fi kún àkókò tí wọ́n ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá lóṣù March, April àti May sọ ìrírí tí wọ́n ní. Kó o sì tún jẹ́ kí àwọn tó padà lọ torí àtilè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn tó gbàwé ìròyìn lọ́wọ́ wọn sọ ìrírí tiwọn náà. O lè ní kí ẹnì kan tàbí méjì ṣe àṣefihàn bí ìrírí náà ṣe wáyé gan-an.
Orin 21 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 4
Orin 99
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Ṣó O Ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tara Ẹ?”d Fi àlàyé ṣókí kún un látẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn nípa ibi tí ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín gbòòrò dé, nípa bẹ́ ẹ ṣe máa ń ṣe é lemọ́lemọ́ tó, kó sì sọ bí ìpínlẹ̀ ìwàásù táwọn ará lè gbà bá wà nílẹ̀.
20 min: “Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Yin Jèhófà.”e Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, fi àlàyé kún un látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 2005, ojú ìwé 3.
Orin 169 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.