Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I —Bó O Ṣe Lè Fi Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ẹnu Ọ̀nà
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Ká tó lè sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, a ní láti jẹ́ olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Mát. 28:19, 20) Gbogbo wa la lè kọ́ni lọ́nà tó múná dóko nípa lílo àwọn ìtẹ̀jáde tí ètò Ọlọ́run fún wa. A dìídì ṣe ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! ká lè fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Kódà, a lè fi ìwé yìí bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹni tá a wàásù fún nígbà tá a kọ́kọ́ bá a sọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà rẹ̀.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ kó máa wù ọ́ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tún bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kó o ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wàá máa darí, kó sì jẹ́ kó o di olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ dáadáa.—Fílí. 2:13.
Nígbà ìjọsìn ìdílé yín tàbí tó o bá ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ, múra ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ sílẹ̀ dáadáa. Èyí á jẹ́ kó o lè fi ìdánilójú sọ̀rọ̀, tí wàá sì lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnu ọ̀nà lóde ẹ̀rí.