Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 15
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 15
Orin 77 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 26 ìpínrọ̀ 1 sí 9 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 22-24 (8 min.)
No. 1: 2 Sámúẹ́lì 22:21-32 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àpẹẹrẹ Àwọn Ọ̀rẹ́ Àtàtà Tó Wà Nínú Bíbélì àti Àwọn Ànímọ́ Tó Yẹ Ká Ní (5 min.)
No. 3: A Máa Ń Láyọ̀ Tá A Bá Ní Ìfẹ́ Tá A sì Jẹ́ Onígbọràn—igw ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 4 sí 6 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Rántí àwọn ọjọ́ láéláé.”—Diu. 32:7.
12 min: Ta Lo Fẹ́ràn Jù Lọ Nínú Bíbélì? Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti àsọyé. Kọ́kọ́ fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn ọmọdé méjì tàbí mẹ́ta. Ta ni wọ́n fẹ́ràn jù lọ nínú Bíbélì? Kí ni Bíbélì sọ pé ẹni náà ṣe? Báwo ni wọ́n ṣe máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹni tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí? Lẹ́yìn náà, sọ àsọyé tó dá lórí bí àwọn ọmọdé ṣe lè jàǹfààní nínú lílo káàdì Bíbélì tó wà lórí ìkànnì jw.org/yo. (Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN ỌMỌDÉ.) Káàdì Bíbélì kọ̀ọ̀kan máa ń ní ìsọfúnni ṣókí nípa ẹnì kan nínú Bíbélì, àwòrán rẹ̀, àwòrán ilẹ̀ ibi tó gbé, àtẹ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀, àwọn ìbéèrè mẹ́ta nípa ẹni náà àti ìdáhùn. A ṣe àwọn káàdì yìí lọ́nà tó máa ṣeé tẹ̀ jáde tó sì ṣeé gé. Gba àwọn òbí tó láwọn ọmọdé níyànjú pé kí wọ́n máa fi káàdì Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa “àwọn ọjọ́ láéláé.”—Diu. 32:7.
18 min: “Bí O Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Akéde Tó Nírìírí.” Ìjíròrò. Tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ kejì, ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní lára akéde kan tó nírìírí nígbà tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí.
Orin 4 àti Àdúrà