Ìjẹ́rìí Orí Tẹlifóònù Tó Ń Yọrí sí Rere
1 Ète tí a ní gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe kìkì láti kópa nínú wíwàásù ìhìn rere, ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti mú ìhìn Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo ẹni tó bá ṣeé ṣe pẹ̀lú. (Ìṣe 10:42; 20:24) Nígbà tó jẹ́ pé iṣẹ́ ilé dé ilé ni olórí ọ̀nà tí a ń gbà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn, a mọ̀ pé a kò lè dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn nípasẹ̀ ọ̀nà tí a ń fètò ṣe yìí pàápàá. Nítorí náà, láti lè ‘ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún,’ a ń lo àwọn ọ̀nà mìíràn pẹ̀lú—títí kan ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù ní àgbègbè tó bá ti ṣeé ṣe—láti wá àwọn ẹni bí àgùntàn rí.—2 Tím. 4:5.
2 Ní àwọn ìlú ńlá kan, àwọn èèyàn máa ń gbé ilé tí wọ́n dáàbò bò gidigidi, àwọn ilé ńlá tí àwọn tó ń gbé ibẹ̀ pọ̀, tàbí àwọn àdúgbò tó ní ẹnubodè níbi tó ti ṣòro láti ṣe iṣẹ́ ilé dé ilé tí a ń ṣe láti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn. Kódà ní àwọn ìpínlẹ̀ tí a ti lè ṣe iṣẹ́ ilé dé ilé, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í sí nílé. Níbi tí tẹlifóònù wà, ọ̀pọ̀ akéde ló ń ṣàṣeyọrí gidigidi nínú lílò ó láti kàn sí àwọn tó ń gbé díẹ̀ nínú irú àwọn ibi táa sọ wọ̀nyí.
3 Ǹjẹ́ o ní fóònù? Ǹjẹ́ o máa ń lọ́ tìkọ̀ láti fi ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? Arákùnrin kan sọ pé: “Mi ò kì í fẹ́ kéèyàn máa fóònù mi nílé pé òun fẹ́ ta nǹkan fún mi, nítorí náà, mo ti ronú pé àwọn èèyàn á tako irú ọ̀nà ìjẹ́rìí yìí.” Àmọ́, nígbà tó fóònù lẹ́ẹ̀mejì péré, ó sọ pé: “Ó ti wá wù mí gan-an ni! Mi ò ronú rí pé ọ̀ràn á wá rí báyìí, àní ó ti wá gbádùn mọ́ mi! Àwọn èèyàn máa ń fara balẹ̀ lórí fóònù, gbogbo nǹkan tóo sì ń fẹ́ ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó ẹ. Èyí mà gbéṣẹ́ o!” Arábìnrin kan náà sọ ohun tó jọ èyí, ó ní: “Ní ti gidi, ara kò yá mi láti jẹ́rìí lórí tẹlifóònù. Ní tòdodo, mi ò fẹ́ ṣe é. Ṣùgbọ́n mo gbìyànjú ẹ̀ wò, mo sì rí i pé ó ń ṣàṣeyọrí. Ìpadàbẹ̀wò mẹ́tàdínlógójì ni mo ní nípa jíjẹ́rìí lórí tẹlifóònù, mo sì ní ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ tó kọjá ohun tí mo lè ṣe pàápàá!” Bí o bá múra tán láti gbìyànjú ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù, ìwọ pẹ̀lú lè ṣàṣeyọrí.
4 Àwọn alàgbà lè fìfẹ́ hàn gidigidi nínú iṣẹ́ yìí nípa ṣíṣètò pé kí àwọn tó nírìírí lẹ́nu iṣẹ́ ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù kọ́ àwọn ẹlòmíràn, bóyá nípa lílo ètò Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́. Látìgbàdégbà—nínú àwọn ìjọ tí èyí yóò bá ti bá a mu—wọ́n lè fi apá tó jẹ́ ti àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn sọ̀rọ̀ lórí bí a ṣe lè túbọ̀ mú kí irú ọ̀nà ìjẹ́rìí yìí yọrí sí rere.
5 Àbá Nípa Bí A Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí: Nígbà tí Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ láti wàásù, ó “rán wọn jáde ní méjìméjì.” (Lúùkù 10:1) Èé ṣe? Ó mọ̀ pé bí wọ́n bá jọ ṣiṣẹ́, wọ́n á lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ ara wọn, wọ́n á sì fún ara wọn níṣìírí. Bọ́ràn jíjẹ́rìí lórí tẹlifóònù ṣe rí nìyẹn pẹ̀lú. Bí ẹ̀yin méjì bá jọ ṣiṣẹ́, ẹ lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lọ́dọ̀ ara yín, ẹ ó lè jíròrò àbájáde tí ẹ bá ní, ẹ ó sì lè dábàá ohun tó yẹ láti ṣe nígbà ìjíròrò tó kàn. Àní nígbà tí ẹ bá ń sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, ẹ lè ran ara yín lọ́wọ́ láti ṣàwárí ìsọfúnni tó yẹ.
6 Láti mú kí o lè ronú jinlẹ̀, kí o sì pọkàn pọ̀, jókòó síbi tí wàá ti lè to àwọn ohun èlò ìjẹ́rìí rẹ síwájú rẹ, àwọn bíi Bíbélì, ìwé Reasoning, ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, àwọn ìwé ìròyìn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan, kí o sì fi wọ́n síbi tí o ti lè rí wọn. Múra sílẹ̀ láti tọ́jú àkọsílẹ̀ tó péye tó sì kún rẹ́rẹ́, títí kan ọjọ́ àti àkókò kí o lè mọ ìgbà tó yẹ láti tún kàn sí ẹni tó fìfẹ́ hàn.
7 Àwọn èèyàn sábà máa ń ṣọ́ra nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ohùn ẹni tí wọn ò mọ̀ rí lórí fóònù. Nítorí náà, sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀yàyà, pẹ̀lú ara yíyá gágá, kí o sì lo ọgbọ́n. Ohùn rẹ nìkan ni onílé lè gbọ́ láti mọ bí ìwà rẹ ṣe rí àti bóyá òótọ́ lo ń sọ. Fara balẹ̀ kí o sì sọ̀rọ̀ látọkànwá. Má ṣe sáré sọ̀rọ̀, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí o ń sọ ṣe ketekete, kí o sì gbóhùn sókè débi tí onítọ̀hún á fi lè gbọ́ ohun tí ò ń sọ. Fún onílé láǹfààní láti sọ̀rọ̀. Sọ orúkọ rẹ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, kí o sì sọ pé ìlú náà tàbí àdúgbò náà lò ń gbé. Dípò tí wàá fi sọ pé gbogbo àwọn tó ń gbé nínú ilé kan lò ń kàn sí, sọ pé ẹni yẹn gan-an lo dìídì fóònù.
8 Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Lórí Tẹlifóònù: Ọ̀pọ̀ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé kékeré Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó ni a lè gbé kalẹ̀ lọ́nà mìíràn láti fi ṣe ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù. O lè sọ pé: “Mo ń kàn sí ọ lórí tẹlifóònù nítorí pé kò ṣeé ṣe fún mi láti fúnra mi wá sọ́dọ̀ rẹ. Ìdí tí mo fi ń kàn sí ọ ni pé mo fẹ́ béèrè èrò rẹ nípa ìbéèrè pàtàkì kan.” Lẹ́yìn náà, béèrè ìbéèrè náà.
9 A lè lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ àkọ́kọ́ lábẹ́ àkòrí náà, “Ìwà-Ọ̀daràn/Ààbò,” nípa sísọ pé: “Ẹ ǹlẹ́ o. Orúkọ mi ni_____. Ìlú yìí ni mo ń gbé. Mo ń kàn sí ọ nítorí àníyàn mi nípa ọ̀ràn ààbò ti ara ẹni. Ìwà ọ̀daràn púpọ̀ ni ó yí wa ká, ó sì ń nípa lórí ìgbésí ayé wa. Ǹjẹ́ o rò pé ìgbà kan yóò dé tí àwọn èèyàn bí ìwọ àti èmi yóò lè rìn ní òpópónà lálẹ́ láìséwu? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jẹ́ kí n ka ohun tí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun yóò ṣe.”
10 Lílo ọ̀nà ìyọsíni tààràtà láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni lórí fóònù ti yọrí sí rere. Láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan, a lè ṣàṣefihàn bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́. Sọ pé o máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni náà nílé láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ, tàbí bí ẹni náà kò bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, sọ pé wàá máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nìṣó lórí fóònù lọ́jọ́ mìíràn.
11 Nígbà tóo bá parí ìjíròrò kan, ní ohun kan lọ́kàn tí yóò jẹ́ kí o lè ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni náà nílé rẹ̀ tàbí tí yóò jẹ́ kí o lè fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí i. Bí ẹni náà kò bá fẹ́ fún ọ ní àdírẹ́sì rẹ̀, sọ pé wàá tún fóònù rẹ̀ nígbà mìíràn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o máa fóònù rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà kí ọkàn rẹ̀ tó balẹ̀ débi tí yóò fi sọ pé kí o wá sí ilé òun.
12 Lo Ìdánúṣe: Arábìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lówùúrọ̀ ọjọ́ kan nípa fífóònù ẹnì kan. Ó bá obìnrin kan sọ̀rọ̀, obìnrin náà sì gbà láti gba ìwé Ìmọ̀. Nígbà tí arábìnrin yìí lọ fún obìnrin yẹn ní ìwé náà nílé, obìnrin yìí fẹ́ mọ bí arábìnrin ọ̀dọ́ yìí ṣe mọ nọ́ńbà fóònù òun nítorí pé kò sí lákọọ́lẹ̀. Ńṣe ni arábìnrin yẹn mà ṣèèṣì fóònù rẹ̀ o! Obìnrin yìí tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́, ó sì ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi báyìí.
13 Lẹ́yìn tí arábìnrin kan ti gba àwọn nọ́ńbà fóònù mélòó kan, ó lọ́tìkọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́rìí lórí tẹlifóònù fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan nítorí ẹ̀rù ń bà á. Kí ló wá fún un ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀? Ńṣe ló rántí àpilẹ̀kọ inú Jí! January 22, 1997, tó ní àkọlé náà, “Nígbà Tí Èmi Bá Jẹ́ Aláìlera, Nígbà Náà Ni Mo Di Alágbára.” Ọ̀rọ̀ nípa Ẹlẹ́rìí kan tó máa ń jẹ́rìí lórí tẹlifóònù bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìlera dín àwọn ohun tó lè ṣe kù ló sọ. Arábìnrin náà sọ pé: “Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún mi lókun. Mo sọ pé kó jẹ́ kí n mọ ohun tó yẹ kí n sọ láti gbé ọ̀rọ̀ mi kalẹ̀.” Kí làbájáde ọjọ́ àkọ́kọ́ tó jẹ́rìí lórí tẹlifóònù? Ó ròyìn pé: “Jèhófà gbọ́ àdúrà mi. Àwọn èèyàn fetí sí mi, mo sì ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò.” Nígbà tó yá, ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù tó ń ṣe mú kó ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan látibẹ̀. Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Jèhófà tún kọ́ mi lọ́tẹ̀ yìí pé kí n gbẹ́kẹ̀ lé òun, kí n má sì gbẹ́kẹ̀ lé ara mi.”—Òwe 3:5.
14 Sísọ òtítọ́ náà fún àwọn èèyàn látorí tẹlifóònù ti jẹ́ ọ̀nà kan tó ń mú àṣeyọrí sí rere wá nínú wíwàásù ìhìn rere náà. Múra sílẹ̀ dáadáa, kí o sì fi tọkàntara kópa nínú rẹ̀. Má ṣe rẹ̀wẹ̀sì bó bá lọ jẹ́ pé o kò rẹ́ni fetí sí ọ ní àwọn ìgbà mélòó kan tí o kọ́kọ́ fóònù. Gbàdúrà pé kí Jèhófà ṣamọ̀nà rẹ, kí o sì fi ìrírí àwọn ẹlòmíràn tí àwọn náà ń lo ọ̀nà alárinrin yìí láti wàásù ṣàríkọ́gbọ́n. Bí a ti ń nífẹ̀ẹ́ láti má ṣe yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ wa, ǹjẹ́ kí a ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kúnnákúnná pẹ̀lú ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú.—Róòmù 10:13, 14.