ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 6/8 ojú ìwé 10-12
  • Báwo Ni Àṣa Lílo Tẹlifóònù Rẹ Ṣe rí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Àṣa Lílo Tẹlifóònù Rẹ Ṣe rí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwọ àti Tẹlifóònù
  • Ìgbatẹnirò Onírònú fún Àwọn Ẹlòmíràn
  • Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ
  • Jẹ́ Olùfetísílẹ̀ Rere
  • Àwọn Kókó Ìgbẹ̀yìn fún Àgbéyẹ̀wò
  • Ìjẹ́rìí Orí Tẹlifóònù Tó Ń Yọrí sí Rere
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Fífi Fóònù Wàásù Máa Ń Gbéṣẹ́ Gan-an
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Bá A Ṣe Lè Máa Hùwà Tó Bójú Mu Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìwà Rere La Fi Ń Dá Àwọn Èèyàn Tó Ń Fọkàn Sin Ọlọ́run Mọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 6/8 ojú ìwé 10-12

Báwo Ni Àṣa Lílo Tẹlifóònù Rẹ Ṣe rí?

“Pẹ̀lú ìfẹ́ni ìdílé, ìlera, àti ìfẹ́ láti ṣiṣẹ́, ohunkóhun ha tún wà tí ń ṣe bẹbẹ ní ìhà mímú ìgbé ayé gbádùn mọ́ni, mímú iyì ara ẹni padà sípò àti gbígbé e ga, lọ́nà kan náà tí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ onínúure ń gbà ṣe é bí?”

NÍ BÍBÉÈRÈ ìbéèrè yẹn, olóògbé òǹkọ̀wé àti olùkọ́ ọmọ ilẹ̀ America náà, Lucy Elliot Keeler, ń gbé ìníyelórí gíga karí ìgbádùn àti ìtẹ́lọ́rùn ara ẹni tí a lè rí láti inú ìbásọ̀rọ̀pọ̀ ọlọ́rọ̀ ẹnu, agbára ìṣe kan tí a fi tìfẹ́tìfẹ́ fún ènìyàn nígbà tí a ṣẹ̀dá rẹ̀.—Eksodu 4:11, 12.

Ìhùmọ̀ tẹlifóònù láti ọwọ́ Alexander Graham Bell ti kópa gidigidi láti ṣàlékún ọ̀rọ̀ sísọ ẹ̀dá ènìyàn láàárín ẹ̀wádún 12 tí ó kọjá. Lónìí, yálà a ń lò ó fún iṣẹ́ tàbí fún fàájì, tẹlifóònù ń pèsè ìsopọ̀ tí kò ṣeé máà ní fún ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù olùgbé ayé.

Ìwọ àti Tẹlifóònù

Dé ìwọ̀n àyè wo ni ìlò tẹlifóònù ń mú ìgbé ayé rẹ lárinrin? O kì yóò ha gbà pé ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè yẹn sinmi púpọ̀ lórí àwọn ènìyàn tí ó kàn ju lórí ẹ̀rọ náà fúnra rẹ̀ lọ? Dájúdájú, ó bágbà mu láti béèrè ìbéèrè náà, Báwo ni àṣà lílo tẹlifóònù rẹ́ ṣe rí?

Àṣà lílo tẹlifóònù kan àwọn agbègbè bí ẹ̀mí èrò orí, ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, àti agbára ìfiyèsílẹ̀. Ní ìfarapẹ́ èyí pẹ̀lú ni bi a ti í lo tẹlifóònù àti ohun tí ó yẹ láti ṣe nípa ìkésíni tí ń díni lọ́wọ́.

Ìgbatẹnirò Onírònú fún Àwọn Ẹlòmíràn

Bí ó ti rí pẹ̀lú gbogbo àjọṣepọ̀ ẹ̀dá ènìyàn, lílo tẹlifóònù lọ́nà rere ń wá láti inú ìmọ̀lára fún ẹlòmíràn. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ máa fiyè sí ire àwọn ẹlòmíràn, kì í ṣe ti ara yín nìkan.”—Filippi 2:4, The New English Bible.

Nígbà tí a bi í pé, “Kí ni o ti rí bí àpẹẹrẹ lílò tẹlifóònù lọ́nà tí kò dára tí ó wọ́pọ̀ jù lọ?,” onírìírí òṣìṣẹ́ ìpààrọ̀ ìlà ọ̀nà tẹlifóònù kan dáhùn pé, ohun tí ó gbawájú jù lọ tí òún lè sọ ni “òpeni tí ń sọ pé, ‘Màríà ní ń sọ̀rọ̀’ (Màríà mélòó lo mọ̀?) tàbí, burú jù bẹ́ẹ̀ lọ, ‘Èmi ni mò ń sọ̀rọ̀,’ tàbí ‘Méfòó ẹni tí ń sọ̀rọ̀.’” Irú ìsọ̀rọ̀ àìnírònú bẹ́ẹ̀, bóyá láìní èrò búburú kankan lọ́kàn, lè tini lára tàbí tánni ní sùúrù. Òṣìṣẹ́ náà ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “O kò ṣe kúkú bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ lọ́nà dídùn mọ́ni nípa sísọ ẹni tí o jẹ́ gan-an àti ní àfikún, pẹ̀lú ìgbatẹnirò fún ẹni tí o ń ké sí, bíbéèrè bóyá àkókò náà wọ̀ láti jùmọ̀ jíròrò?”

Rántí pé, bí a kò tilẹ̀ lè rí ojú rẹ, ìṣarasíhùwà rẹ yóò ṣe kedere. Báwo? Nípa bí ohùn rẹ́ ṣe ń dún. Ìkánjú, ìkáàárẹ̀, ìbínú, ìdágunlá, òótọ́ inú, ìtúraká, ìwúlò, àti ọyàyà—gbogbo wọn ń hàn. Òtítọ́ ni pé ìrunú lè jẹ́ ìhùwàpadà lọ́nà ti ẹ̀dá nígbà tí ohun kan bá díni lọ́wọ́. Nítorí ìmọ̀wàáhù, gbìyànjú láti séra ró lábẹ́ ipò yìí, kí o sì fi “ìró atunilára” sí ohùn rẹ, kí o tó fèsì. Ó ṣeé ṣe láti kọ nǹkan láìlo ọ̀rọ̀ ìbínú.

Pípa ìgbatẹnirò onírònú pọ̀ mọ́ ohùn atunilára lè yọrí sí àwọn ọ̀rọ̀ “tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní naa bá ṣe wà,” àti fífi “ohun tí ó ṣenilóore fún awọn olùgbọ́.”—Efesu 4:29.

Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ

Dájúdájú, irú ìsọ̀rọ̀ tí a ń lò ṣe pàtàkì. Ǹjẹ́ o fara mọ́ àwọn ìlànà tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí, tí o sì ń ṣe wọ́n? Sọ̀rọ̀ lọ́nà àdánidá, ní kedere, àti ní ketekete. Má ṣe fọ̀rọ̀ ránu. Má ṣe pariwo—àní bí o tilẹ̀ ń ké síni lọ́nà jíjìn. Má ṣe wọ́ ọ̀rọ̀ rẹ lù. Yẹra fún jíjá ọ̀rọ̀ pọ̀ mọ́ra tí ó máa ń gé ìró ègé ọ̀rọ̀ kúrú tàbí kí ó fò ó; yẹra fún lílo àṣà “tí ń fa ọ̀rọ̀ gùn” àti àsọpadàsẹ́yìn, tí ó lè dabarú ọ̀rọ̀, kí ó sì dáni lágara. Yẹra fún ìró ohùn gooro tí ń súni. Ìtẹnumọ́ òye ọ̀rọ̀ àti ìròkèrodò ohùn bí ó ti yẹ máa ń mú kí ọ̀rọ̀ nítumọ̀, kí ó dùn, kí ó sì tura. Fi sọ́kàn pẹ̀lú pé, jíjẹ nǹkan lẹ́nu nígbà tí o ń jíròrò lórí tẹlifóònù kì í mú ànímọ́ ọ̀rọ̀ sunwọ̀n sí i tàbí fi ìmọ̀wàáhù hàn.

Ó tún yẹ láti ṣàyẹ̀wò ṣíṣe àṣàyàn ọ̀rọ̀. Ó ń béèrè ìfòyemọ̀. Lo àwọn ọ̀rọ̀ ṣíṣe kedere, rírọrùn, tí ó lè tètè yéni. Àwọn ọ̀rọ̀ máa ń ní ìtumọ̀ abẹ́nú. Wọ́n lè jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tàbí onírorò, atunilára tàbí alénisá, amúnilọ́kànle tàbí amúnilọ́kànpami. Síwájú sí i, ẹnì kán lè jẹ́ oníyè inú jíjí pépé láìjẹ́ asúni, ó lè jẹ́ aláìlẹ́tàn láìjẹ́ aláìfọ̀ràn rora ẹni tàbí aláìlọ́wọ̀, ó sì lè jẹ́ amẹ̀tọ́mẹ̀yẹ láìjẹ́ olùyẹǹkansílẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ ìbọ̀wọ̀fúnni bíi “jọ̀wọ́” àti “o ṣeun” sábà máa ń ṣètẹ́wọ́gbà. Àwọn ọ̀rọ̀ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, onígbatẹnirò, tí ó sì dùn mọ́ni ni aposteli Paulu ní lọ́kàn nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Nígbà gbogbo ẹ jẹ́ kí gbólóhùn àsọjáde yín máa jẹ́ pẹlu oore-ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹni kọ̀ọ̀kan.”—Kolosse 4:6.

Jẹ́ Olùfetísílẹ̀ Rere

Ìtàn kan sọ nípa ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó béèrè pé kí bàbá òún sọ àṣírí jíjẹ́ olùbánisọ̀rọ̀ rere fún òun. Ìdáhùn náà ni pé: “Fetí sílẹ̀, ọmọ mi.” Ọ̀dọ́ náà dáhùn pé: “Mo ti fetí sílẹ̀. Sọ fún mi sí i.” Bàbá náà dáhùn pé: “Kò ku nǹkan kan mọ́.” Ní tòótọ́, jíjẹ́ olùfetísílẹ̀ tí ń báni kẹ́dùn, tí ó sì lọ́kàn ìfẹ́ nínú ẹni jẹ́ èròjà ṣíṣe kókó nínú ìlànà àṣeyọrí àṣà lílo tẹlifóònù lọ́nà rere.

Ìkùnà láti pa ìlànà rírọrùn kan mọ́ lè mú kí a máa wò ọ́ bí afiǹkansúni. Kí ni? Má ṣe gbìyànjú láti sọ èyí tí ó pọ̀ jù nínú ọ̀rọ̀ ìjíròrò náà. Fún àpẹẹrẹ, má ṣe jẹ́ kí ó wọ̀ ọ́ lára débi sísọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ìjíròrò ráńpẹ́ kan tí o ti ṣe kọjá tàbí kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa àìlera ara ẹni pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Lẹ́ẹ̀kan sí i, a ní ìlànà pàtó kan tí ó ṣeé mú lò nínú Bibeli, nínú ọ̀ràn yìí, ó wá láti ọwọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jakọbu. “Ẹ yára láti fetí sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ lọ́ra láti fọhùn.”—Jakọbu 1:19, Jerusalem Bible.

Àwọn Kókó Ìgbẹ̀yìn fún Àgbéyẹ̀wò

Ẹ jẹ́ kí a wá gbé àwọn ìbéèrè méjì ìkẹyìn wò nípa àṣà lílo tẹlifóònù. Kí ni a lè sọ nípa bi a ti í lo tẹlifóònù? Ìdámọ̀ràn kankan ha wà lórí ohun tí ó yẹ láti ṣe nípa ìkésíni tí ń díni lọ́wọ́?

Ǹjẹ́ ó ti ṣẹlẹ̀ rí pé kí ohùn ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ máa lọ fée lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lórí tẹlifóònù? Èyí gbọdọ̀ máa rán ọ létí láti sọ̀rọ̀ sínú gbohùngbohùn rẹ̀, kí o fi sí nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà méjì sí ètè rẹ. Láfikún, ó ń fi ọ̀wọ̀ hàn bí a bá ṣàkóso ariwo tí ó wà ní àyíká wa. Nígbà tí o bá ń tẹni láago, baralẹ̀ kí o má baà ṣi nọ́ḿbà tẹ̀; bí o bá sì parí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ náà, gbé gbohùngbohùn náà sí àyè rẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́.

Ṣé o ti gba ìkésíni tí ń díni lọ́wọ́ rí? Ó bani nínú jẹ́ pé ó jọ pé irú rẹ̀ ń pọ̀ sí i ni. Ìdáhùn kan ṣoṣo ni ó yẹ fún ọ̀rọ̀ àìbójúmu, amúniròròkurò, tàbí ọ̀rọ̀ àlùfààṣá—mímú ìkésíni náà wá sópin. (Fi wé Efesu 5:3, 4.) Ohun kan náà ni ó bá a mu nígbà tí ẹni náà bá kọ̀ láti dárúkọ ara rẹ̀. Bí o bá nídìí láti fura sí ìkésíni kan, ìtẹ̀jáde náà, How to Write and Speak Better, dámọ̀ràn pé kí o “má ṣe dáhùn, bí àjèjì ohùn kan bá béèrè pé, ‘Ta ní ń sọ̀rọ̀?’” má sì ṣe jíròrò ìwéwèé rẹ pẹ̀lú àjèjì kankan.

Ẹ wo bí ó ti dára tó láti mọ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín pé, lílo tẹlifóònù lọ́nà rere kò béèrè òfin tàbí ìlànà tí a tò rẹrẹẹrẹ! Bí ó ti rí nínú gbogbo àjọṣepọ̀ ẹ̀dá ènìyàn, ìbátan dídùn mọ́ni, tí ó sì ṣàǹfààní ń wá láti inú lílo ohun tí a sábà ń pè ní Òfin Oníwúrà. Jesu Kristi wí pé: “Nitori naa, gbogbo ohun tí ẹ̀yin bá fẹ́ kí awọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ̀yin pẹlu gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Matteu 7:12) Fún Kristian, ìfẹ́ àtọkànwá láti tẹ́ Ẹni tí ó fi ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ jíǹkí ènìyàn lọ́rùn tún wà níbẹ̀. Onipsalmu náà gbàdúrà pé: “Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, àti ìṣàrò ọkàn mi, kí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, Oluwa, agbára mi, àti olùdáǹdè mi.”—Orin Dafidi 19:14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́