ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/01 ojú ìwé 3-4
  • Ìwà Rere La Fi Ń Dá Àwọn Èèyàn Tó Ń Fọkàn Sin Ọlọ́run Mọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwà Rere La Fi Ń Dá Àwọn Èèyàn Tó Ń Fọkàn Sin Ọlọ́run Mọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Máa Hùwà Tó Bójú Mu Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Nje Iwa Omoluwabi Tie Se Pataki?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Jẹ́ Àpẹẹrẹ Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ àti Nínú Ìwà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Fi Àpẹẹrẹ Rere Lélẹ̀ Fáwọn Ọmọ Yín
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 8/01 ojú ìwé 3-4

Ìwà Rere La Fi Ń Dá Àwọn Èèyàn Tó Ń Fọkàn Sin Ọlọ́run Mọ̀

1 Ìwà rere ṣọ̀wọ́n lónìí. Kí ló fà á? Ojú máa ń kán àwọn èèyàn débi tó fi jẹ́ pé agbára káká ni wọ́n fi máa ń ronú nípa ìwà ọmọlúwàbí tó ṣe pàtàkì, irú bíi sísọ pé, “Jọ̀wọ́,” “O ṣeun,” tàbí “Máà bínú.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sàsọtẹ́lẹ̀ pé ìwà àwọn èèyàn yóò burú sí i láwọn ọjọ́ ìkẹyìn nígbà tó sọ pé àwọn èèyàn yóò jẹ́ ‘olùfẹ́ ara wọn, ajọra-ẹni-lójú, onírera, aláìlọ́pẹ́, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, àti olùwarùnkì.’ (2 Tím. 3:1-4) Gbogbo ànímọ́ wọ̀nyí ló jẹ́ ìwà burúkú. Bí àwọn Kristẹni ti jẹ́ ẹni tó ń fọkàn sin Ọlọ́run, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má ṣe dà bíi ti ayé yìí tí kò ní ọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn.

2 Kí Ló Ń Jẹ́ Ìwà Rere? Ìwà rere la lè ṣàpèjúwe pé ó jẹ́ fífarabalẹ̀ kíyè sí bí ọ̀ràn ṣe ń rí lára àwọn ẹlòmíràn ká sì mọ bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn gbé ní àlàáfíà. Àwọn ohun tó ń para pọ̀ jẹ́ ìwà rere ni, ìgbatẹnirò, ìbọ̀wọ̀fúnni, inú rere, ìwà ọmọlúwàbí, lílo ọgbọ́n, àti ṣíṣaájò ẹni. Àwọn ànímọ́ yìí ń wá látinú nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì ẹni. (Lúùkù 10:27) Wọn kì í náni lówó, ṣùgbọ́n wọ́n wúlò gidigidi nínú jíjẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn dán mọ́rán.

3 Jésù Kristi fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀. Ìgbà gbogbo ló fi Òfin Oníwúrà náà sílò pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.” (Lúùkù 6:31) Àbí, ṣé bí Jésù ṣe láájò tí ó sì fìfẹ́ bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò kò yà wá lẹ́nu? (Mát. 11:28-30) Kì í ṣe inú àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ìwà ọmọlúwàbí ló ti lọ kọ́ nípa ìwà rere tó hù. Inú ọkàn títọ́ àti ọkàn ọ̀làwọ́ ni wọ́n ti wá. A gbọ́dọ̀ ṣakitiyan láti fara wé àpẹẹrẹ rere rẹ̀.

4 Ìgbà wo ló yẹ kí àwọn Kristẹni hùwà rere? Ṣe ní àkókò pàtàkì nìkan ni, ìyẹn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fi wu àwọn ẹlòmíràn? Àbí ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ kí ó ní ipa lórí àwọn ẹlòmíràn ló yẹ kí wọ́n hùwà rere? Rárá o! Gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa hùwà rere. Láwọn ọ̀nà wo ní pàtàkì ló yẹ ká gbà máa ṣe èyí báa ti ń bá ara wa kẹ́gbẹ́ nínú ìjọ?

5 Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba: Ibi táa ti ń jọ́sìn ni Gbọ̀ngàn Ìjọba. Jèhófà Ọlọ́run ló ní ká wá síbẹ̀. Ìyẹn túmọ̀ sí pé àlejò la jẹ́ níbẹ̀. (Sm. 15:1) Ṣe àlejò àwòfiṣàpẹẹrẹ la máa ń jẹ́ nígbà táa bá wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba? Ṣe a máa ń fún ìmúra àti ìwọṣọ wa láfiyèsí tó yẹ? Dájúdájú, a gbọ́dọ̀ yẹra fún mímúra lọ́nà yẹpẹrẹ tàbí lọ́nà àṣejù. Ì báà jẹ́ pé àpéjọpọ̀ tàbí àwọn ìpàdé ìjọ wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la lọ, àwọn èèyàn mọ àwa èèyàn Jèhófà pé ìrísí wa máa ń wuyì, ó sì yẹ àwọn tó ń sọ pé àwọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run. (1 Tím. 2:9, 10) Nípa báyìí, a ń fi ọ̀wọ̀ tó yẹ fún Olùgbàlejò wa tí ń bẹ lọ́run àti àwọn àlejò mìíràn tí ó pè.

6 Ọ̀nà mìíràn tí a tún máa ń gbà hùwà rere ní ìpàdé ni, nípa títètè dé. Kà sòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà lèyí máa ń rọrùn. Àwọn kan lè máa gbé níbi tó jìnnà tàbí kí wọ́n ní ìdílé ńlá tí wọ́n ní láti múra fún. Ṣùgbọ́n, a ti kíyè sí i pé láwọn ìjọ kan, o ti di àṣà àwọn akéde tó pọ̀ tó ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún láti máa dé sí ìpàdé lẹ́yìn orin àti àdúrà. Ọ̀ràn ńlá lèyí o. Ó yẹ ká rántí pé ìwà rere ní í ṣe pẹ̀lú fífarabalẹ̀ kíyè sí bí ọ̀ràn ṣe ń rí lára àwọn ẹlòmíràn. Jèhófà, Olùgbàlejò wa olóore ọ̀fẹ́ ló ń ṣètò oúnjẹ tẹ̀mí wọ̀nyí láti ṣe wá láǹfààní. Nípa títètè máa débẹ̀ wa lákòókò la fi lè fi hàn pé a mọrírì ohun tó ṣe àti pé a ń ronú nípa bí ọ̀ràn ṣe ń rí lára rẹ̀. Ní àfikún sí i, pípẹ́ dé ìpàdé máa ń pín ọkàn àwọn ẹlòmíràn níyà, ó sì ń fi hàn pé a kò bọ̀wọ̀ fún àwọn tó ti dé ṣáájú.

7 Nígbà tí a bá péjọ, ǹjẹ́ a máa ń kíyè sí àwọn ẹni tuntun tó wà láàárín wa? Kíkí wọn káàbọ̀ jẹ́ ara ìwà rere. (Mát. 5:47; Róòmù 15:7) Kíkí wọn tayọ̀tayọ̀, bíbọ̀ wọ́n lọ́wọ́ tọ̀yàyàtọ̀yàyà, rírẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn, táa lè rò pé ó jẹ́ nǹkan kékeré, máa ń fi kún ohun tó ń fi wá hàn yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́. (Jòh. 13:35) Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ìgbà àkọ́kọ́, ó sọ pé: “Lọ́jọ́ kan ṣoṣo, mo rí àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, àwọn tí mi ò mọ̀ rí, ju iye tí mo tíì rí rí nínú ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n ti tọ́ mi dàgbà lọ. Ó hàn gbangba gbàǹgbà pé mo ti rí òtítọ́.” Nítorí èyí, ó yí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ padà, nígbà tó sì di oṣù keje lẹ́yìn náà, ó ṣe ìrìbọmi. Àní sẹ́, ìwà rere ń ṣe bẹbẹ!

8 Bí a bá ní láti hùwà rere sí àwọn tí a ò mọ̀ rí tí a bá bá pàdé, ǹjẹ́ kò yẹ ká hùwà rere “ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́”? (Gál. 6:10) Ìlànà yìí wúlò pé: “Kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó.” (Léf. 19:32) Kò yẹ ká gbójú fo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dá ní àwọn àpéjọ wa.

9 Fífiyè Sílẹ̀ Dáadáa: Ní àwọn ìpàdé ìjọ, àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ Ọlọ́run máa ń sọ̀rọ̀ láti fún wa ní àwọn ẹ̀bùn tẹ̀mí kan kí wọ́n lè gbé wa ró. (Róòmù 1:11) Ó dájú pé ìwà tí kò bọ́ sí i rárá ni tó bá lọ jẹ́ pé nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́, a sùn lọ, a ń jẹ ṣingọ́ọ̀mù lọ́nà tó ń dá ariwo sílẹ̀, a ń bá ẹni tó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ wa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ léraléra, a ń dìde lọ sí ilé ìtura láìpọndandan, a ń ka ìwé tí kò bá ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ mu, tàbí tí a ń ṣe àwọn ohun mìíràn. Ó yẹ kí àwọn alàgbà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ lórí èyí. Ìwà rere Kristẹni yóò mú ká fi ọ̀wọ̀ tó yẹ fún olùbánisọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ tí a gbé karí Bíbélì tó ń bá wa sọ nípa fífetí sí i gidigidi láìjẹ́ kí ọkàn wa pínyà.

10 Láfikún sí i, nítorí gbígba ti olùbánisọ̀rọ̀ àti àwùjọ rò, kí á má ṣe jẹ́ kí tẹlifóònù alágbèérìn da ìpàdé wa rú.

11 Ìwà Rere àti Àwọn Ọmọ: Ó yẹ kí àwọn òbí máa kíyè sí ìwà àwọn ọmọ wọn nígbà gbogbo. Bí ọmọdé kan bá bẹ̀rẹ̀ sí sọkún tàbí tó ń ṣe ìjọ̀ngbọ̀n nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́ tí èyí sì ń dí àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, á dára láti gbé ọmọ yẹn jáde kúrò nínú gbọ̀ngàn bó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó láti mú kí ó dákẹ́. Èyí lè ṣòro nígbà mìíràn, ṣùgbọ́n rántí pé èyí ń fi hàn pé o ń ronú nípa bí ọ̀ràn ṣe rí lára àwọn ẹlòmíràn. Àwọn òbí tó ní àwọn ọmọ kékeré tó ṣeé ṣe kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì ṣe ìjọ̀ngbọ̀n sábà máa ń jókòó ní apá ẹ̀yìn nínú gbọ̀ngàn kí wọ́n má bàa dí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ nígbà tó bá pọndandan pé kí wọ́n jáde nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Dájúdájú, àwọn yòókù tó wá sí ìpàdé lè fi ìgbatẹnirò tó yẹ hàn fún irú àwọn ìdílé bẹ́ẹ̀ nípa fífi ìjókòó tó wà lẹ́yìn sílẹ̀ fún wọn láti jókòó síbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.

12 Àwọn òbí tún gbọ́dọ̀ kíyè sí ìwà tí àwọn ọmọ wọn ń hù ṣáájú àti lẹ́yìn ìpàdé. Kò yẹ kí àwọn ọmọ máa sáré kiri inú gbọ̀ngàn nítorí èyí lè fa jàǹbá. Sísáré ní òde Gbọ̀ngàn Ìjọba tún léwu pẹ̀lú, pàápàá ni àṣálẹ́ tí èèyàn kò ní lè rí ara wọn dáadáa mọ́. Kíkígbe sọ̀rọ̀ ní ìta gbọ̀ngàn lè dí àwọn aládùúgbò lọ́wọ́, ó sì lè tàbùkù sí ìjọsìn wa. A ní láti gbóríyìn fún àwọn òbí tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn sapá láti ṣàkóso àwọn ọmọ wọn nínú àti ní ìta Gbọ̀ngàn Ìjọba nítorí èyí ń fi kún adùn wíwà pa pọ̀ wa ní ìṣọ̀kan.—Sm. 133:1.

13 Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ: A mọrírì ẹ̀mí aájò àlejò àwọn ará wa tí wọ́n yọ̀ǹda ilé wọn fún ṣíṣe àwọn ìpàdé ìjọ. Nígbà táa bá lọ ṣe ìpàdé níbẹ̀, ó yẹ ká bọ̀wọ̀ fún àwọn àti ohun ìní wọn, ká sì fi ìgbatẹnirò hàn. Ká tó wọlé, ó yẹ ká gbọn bàtà wa dáadáa ká má bàa dọ̀tí ilẹ̀ tàbí ohun tí wọ́n tẹ́ sórí ilẹ̀. Ó yẹ káwọn òbí bójú tó àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n rí i dájú pé wọn kò kọjá ibi tí wọ́n ń lò fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ nínú ilé náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwùjọ náà lè kéré, tí ipò nǹkan sì lè má dà bíi ti Gbọ̀ngàn Ìjọba, a kò gbọ́dọ̀ kọjá àyè wa ní ilé àwọn ẹlòmíràn. Òbí tó bá ní ọmọ kékeré gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ọmọ rẹ̀ nígbà tó bá fẹ́ lọ sí ilé ìtura. Síwájú sí i, níwọ̀n bí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ti jẹ́ ìpàdé ìjọ, ó yẹ ká múra bí a ṣe máa ń múra nígbà tí a bá ń lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba.

14 Ìwà Rere Ṣe Kókó: Híhu ìwà rere Kristẹni máa ń buyì kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ṣùgbọ́n ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún máa ń mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn dán mọ́rán. (2 Kọ́r. 6:3, 4, 6) Bí a ti jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run aláyọ̀, ó yẹ kó rọrùn fún wa láti rẹ́rìn-ín músẹ́, láti wà ní ìṣọ̀kan, àní láti ṣe àwọn nǹkan kéékèèké tó jẹ́ ti inú rere tó ń mú inú àwọn ẹlòmíràn dùn. Àwọn ànímọ́ rere wọ̀nyí yóò bu ẹwà kún ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń fọkàn sin Ọlọ́run.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́