Jẹ́ Àpẹẹrẹ Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ àti Nínú Ìwà
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú láti jẹ́ àpẹẹrẹ nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti nínú ìwà. (1 Tim. 4:12) Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ṣàfihàn àwòfiṣàpẹẹrẹ ọ̀rọ̀ sísọ àti ìwà, ní pàtàkì nígbà tí a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, nítorí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè pinnu bóyá a ń dé inú ọkàn àwọn tí a ń bá pàdé tàbí a kò dé inú ọkàn wọn.
2 A ní láti fi gbogbo ọ̀nà ìmọ̀wàáhù hàn, títí kan ọ̀wọ̀, ìgbatẹnirò, inú rere, ìwà ọmọlúwàbí, àti òye. Nígbà tí a bá ń fi àwọn ànímọ́ wọ̀nyí hàn, a ń fi hàn pé a mọ bí ìwà wa ṣe ń nípa lórí ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn. Mímọ̀wàáhù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni a lè fi wé àwọn èròjà, tí a ń lò láti ṣàlékún adùn àti ìtasánsán oúnjẹ. Láìsí wọn, oúnjẹ gbígbámúṣé lè tẹ́ lẹ́nu, kí ó sì má wuni í jẹ. Ṣíṣàìmọ̀wàáhù nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn lè ní àbájáde kan náà.—Kol. 4:6.
3 Jẹ́ Àpẹẹrẹ Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ẹ̀rín músẹ́ tí ó fani mọ́ra àti ìkíni ọlọ́yàyà ṣe kókó nínú bí a ṣe ń gbé ìhìn rere kalẹ̀. Nígbà tí a bá fi ọ̀yàyà àti òtítọ́ inú dun ìgbékalẹ̀ wa, a ń jẹ́ kí onílé mọ̀ pé a ní ojúlówó ìfẹ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń sọ̀rọ̀, fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀, kí o sì bọ̀wọ̀ fún èrò rẹ̀ bí ó ti yẹ. Nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀, sọ ọ́ pẹ̀lú òye àti oore ọ̀fẹ́.—Fi wé Ìṣe 6:8.
4 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń bá àwọn alátakò pàdé, tí wọ́n jẹ́ aríjàgbá pàápàá. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a hùwà padà? Pétérù rọ̀ wá láti sọ̀rọ̀ lọ́nà kan tí ń fi “inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” hàn. (1 Pet. 3:15; Rom. 12:17, 18) Jésù sọ pé bí onílé kan bá fi àìlọ́wọ̀ kọ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, a wulẹ̀ ní láti ‘gbọn ekuru ẹsẹ̀ wa dànù’ ni. (Mat. 10:14) Bí a ṣe ń fi ìwà tí ó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ hàn lábẹ́ irú àwọn àyíká ipò bẹ́ẹ̀ lè pẹ̀tù sọ́kàn alátakò náà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
5 Jẹ́ Àpẹẹrẹ Nínú Ìwà: Wíwàásù ìhìn rere ní àwọn òpópónà tí ó kún fọ́fọ́ àti ní àwọn ibi tí èrò ń pọ̀ sí, ń béèrè pé kí a gba ti àwọn ẹlòmíràn rò, kí á má máa pariwo tàbí rin kinkin, kí a má sì ṣe dí àwọn tí ń kọjá lọ lọ́nà. Nígbà tí a bá wà nílé àwọn olùfìfẹ́hàn, ó yẹ kí a pa ìwà ẹ̀yẹ mọ́, kí a sì hùwà gẹ́gẹ́ bí àlejò tí ó mẹ̀yẹ, ní fífi ìmọrírì hàn fún ẹ̀mí àlejò ṣíṣe wọn. Ọmọ èyíkéyìí tí ó bá bá wa lọ gbọ́dọ̀ fi ọ̀wọ̀ hàn fún onílé àti ohun ìní rẹ̀, ó sì gbọ́dọ̀ hùwà dáradára, kí ó sì tẹ́tí sílẹ̀ nígbà tí a bá ń jíròrò. Bí àwọn ọmọ bá jẹ́ abẹbẹlúbẹ, èyí yóò fa èrò tí kò bára dé.—Òwe 29:15.
6 Ìrísí wa gbọ́dọ̀ mú un ṣe kedere sí àwọn ẹlòmíràn pé òjíṣẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wá. Nínú ìwọṣọ àti ìmúra wa, a kò gbọdọ̀ dọ̀tí tàbí rí wúruwùru, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò gbọdọ̀ ṣe ṣekárími tàbí ṣàṣerégèé. Nígbà gbogbo, ìrísí wa gbọ́dọ̀ máa yẹ ìhìn rere. (Fi wé Fílípì 1:27.) Nípa fífún ìrísí wa àti àwọn irin iṣẹ́ wa ní àfiyèsí dáradára, a kì yóò jẹ́ okùnfà fún ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ sì ni a kì yóò jẹ́ kí wọ́n rí àlèébù pẹ̀lú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (2 Kọr. 6:3, 4) Ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìwà wa tí ó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ń fi ànímọ́ fífani mọ́ra kún ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, ní bíbọlá fún Jèhófà.—1 Pet. 2:12.