Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún September
ÀKÍYÈSÍ: Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yóò ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan lákòókò àpéjọpọ̀. Àwọn ìjọ lè ṣàtúnṣe tí ó yẹ láti yọ̀ǹda fún lílọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run,” àti fún ṣíṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún 30 ìṣẹ́jú ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. A ní láti yan àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àpéjọpọ̀ àgbègbè náà fún àwọn arákùnrin títóótun méjì tàbí mẹ́ta, tí yóò kó àfiyèsí jọ sórí àwọn kókó pàtàkì jù lọ, ṣáájú àkókò. Àtúnyẹ̀wò tí a múra sílẹ̀ dáradára yìí, yóò ran ìjọ lọ́wọ́ láti rántí àwọn kókó pàtàkì tí wọn yóò lè fi sílò, tí wọn yóò sì lò nínú pápá. Àwọn àlàyé láti ọ̀dọ̀ àwùjọ àti àwọn ìrírí tí a sọ ní láti ṣe ṣókí, kí ó sì sọ ojú abẹ níkòó.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 2
Orin 98
12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rọ gbogbo àwùjọ, àti ní pàtàkì jù lọ, àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, láti ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Kikẹkọọ Iwe Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí,” nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 1992. Tẹnu mọ́ àwọn kókó inú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà.
15 min: “Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
18 min: “Gbígbé Ìhìn Rere Kalẹ̀ Pẹ̀lú Ẹ̀mí Ìfojúsọ́nà-fún-Rere.” Gbé ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ karí ìpínrọ̀ 1. Lẹ́yìn náà, kárí ìpínrọ̀ 2 sí 5 nìkan, nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà. Ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ tí a ti múra sílẹ̀ dáradára, tí ń ṣàfihàn bí a ṣe lè fi ìwe Walaaye Titilae lọni, ṣe ìpadàbẹ̀wò, kí o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀.
Orin 48 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 9
Orin 18
5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
12 min: “Bíbójú Tó Àìní Tẹ̀mí Àwọn Adití.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Bí kò bá sí adití nínú ìjọ, tẹnu mọ́ ṣíṣàìgbójú fo àwọn adití tí a ń rí nínú ìpínlẹ̀ wa. Mẹ́nu kan ìfilọ̀ lórí àwọn atúmọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí.
13 min: Ṣàtúnyẹ̀wò Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Ọdún 1996 ti Ìjọ. Ọ̀rọ̀ àsọyé tí ń gbéni ró, tí ó kún fún ìtara, láti ẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn. (Wo ìwe Iṣetojọ, ojú ìwe 100 sí 102.) Mẹ́nu ba ibi tí ìjọ ti ṣe dáradára, kí o sì gbóríyìn fún wọn. Fi bí ìgbòkègbodò àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé àti ti olùrànlọ́wọ́ ti ṣe púpọ̀ láti ṣèrànwọ́ nínú mímú iṣẹ́ náà gbòòrò sí i ní àdúgbò. Mẹ́nu kan iye àwọn ènìyàn tí ń wá sí ìpàdé, ní títẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì wíwá sí ìpàdé déédéé. Ṣètòlẹ́sẹẹsẹ àwọn góńgó tí ó ṣeé lé bá, tí ìjọ lè gbìyànjú láti lé bá ní ọdún tí ń bọ̀.
15 min: “Gbígbé Ìhìn Rere Kalẹ̀ Pẹ̀lú Ẹ̀mí Ìfojúsọ́nà-fún-Rere.” Ṣàtúnyẹ̀wò ìpínrọ̀ 6 sí 8 nìkan, kí o sì ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ láti ìsọ̀-dé-ìsọ̀ fún ìkésíni àkọ́kọ́ àti ìpadàbẹ̀wò. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti tètè ṣe ìpadàbẹ̀wò.
Orin 123 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 16
Orin 10
13 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
17 min: “Jẹ́ Àpẹẹrẹ Nínú Ọ̀rọ̀ Sísọ àti Nínú Ìwà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
15 min: Ìwa Kristẹni ní Ilé Ẹ̀kọ́. Bàbá ń bá ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀, láti mú àwọn ọ̀fìn burúkú ní àyíká ilé ẹ̀kọ́ wá sí ojútáyé; ó tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàki ṣíṣọ́ra fún ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ àti láti yẹra fún àwọn ìgbòkègbodò tí ó lè gbé ìbéèrè dìde. Ó ṣàtúnyẹ̀wò àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 24, nínú ìwé pẹlẹbẹ Education, ó sì ṣàlàyé ìjẹ́pàtàki fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí. Bàbá mẹ́nu kan àwọn ìdánwò tí ó dìde, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú lílo oògùn líle, dídá ọjọ́ àjọròde, ríre ibi fàájì, tàbí kíkópa nínú eré ìdíje; wọ́n jíròrò bí a ṣe lè yẹra fún ìṣòro. Bàbá gba èwe náà níyànjú pé kí ó má bẹ̀rù láti fọkàn tán òun, nígbà tí ó bá dojú kọ ìṣòro—òun yóò fẹ́ láti mọ̀ nípa rẹ̀, kí òun sì ràn án lọ́wọ́.
Orin 32 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 23
Orin 21
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Mẹ́nu kan àwọn àbájáde àtàtà tí a ti rí ní lílo fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name, láti darí àwọn ẹni tuntun wá sínú ètò àjọ náà. Ní ṣókí, sọ ìrírí kan tàbí méjì láti inú Ilé-Ìṣọ́nà February 15, 1993, ojú ìwé 30 sí 31.
15 min: Àwọn àìní àdúgbò. Tàbí ọ̀rọ̀ àsọyé tí a gbé karí “Wò Kọjá Ohun Tí O Rí!” nínú Ilé-Ìṣọ́nà February 15, 1996, ojú ìwé 27 sí 29.
20 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run’ ti 1996.” Kárí ìpínrọ̀ 1 sí 18 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 10, 11, 15.
Orin 193 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní September 30
Orin 28
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
20 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run’ ti 1996.” Kárí ìpínrọ̀ 19 sí 25 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàtúnyẹ̀wò “Àwọn Ìránnilétí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè,” kí o sì ka ìpínrọ̀ tí ń sọ̀rọ̀ lórí “Ìbatisí.”
15 min: Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tí A Óò Fi Lọni ní October. A óò gbé àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! jáde lọ́nà àkànṣe. Jíròrò onírúurú kókó, bíi: (1) Ète tí a fi ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn náà jáde, bí a ti ṣàlàye rẹ̀ ní ojú ìwé kejì. (2) A ń mú wọn jáde ní onírúurú èdè, ní mímú kí ìmọ̀ Bíbélì wà lárọ̀ọ́wọ́tó kárí ayé. (3) A pète Ilé Ìṣọ́ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ara ẹni, ti ìdílé, àti ti àwùjọ. (4) Àwọn ènìyàn tí ń dara pọ̀ mọ́ onírúurú ìsìn ń kà wọ́n. (5) A óò fọwọ́ ara wa mú àwọn ẹ̀dà tí ó dé kẹ́yìn wá fún ẹnikẹ́ni tí ń fẹ́ láti kà wọ́n ní tòótọ́. (6) A ṣe wọ́n ní pàtàkì fún àwọn tí ọwọ́ wọ́n dí. (7) Láti ọdún 1879 ni a ti ń tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde; Jí! láti ọdún 1919. Mú ọ̀rọ̀ rẹ wá sópin nípa sísọ ohun tí òǹkàwé onímọrírì kan sọ.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà August 1, 1989, ojú ìwé 32.
Orin 3 àti àdúrà ìparí.