Wò Kọjá Ohun Tí O rí!
OJÚ ìríran dídára jẹ́ ìbùkún. Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń sọ pé kò sí ohun tí àwọ́n ní tí ó ṣeyebíye bí ojú. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn Kristian, ojú ìríran kan wà tí aposteli Paulu mẹ́nu kàn, tí ó ṣeyebíye ju ojúyòójú pàápàá lọ. Paulu kọ̀wé pé: “Awa kò tẹ ojú wa mọ́ awọn ohun tí a ǹ rí, bíkòṣe awọn ohun tí a kò rí.” (2 Korinti 4:18) Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ àkànṣe ìríran kan ní ti gidi tí ń ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti rí àwọn ohun tí a kò rí! A lè pè é ní ojú ìríran dídá ṣáká tí ó jẹ́ tẹ̀mí.
Èé Ṣe Tí A Fi Nílò Rẹ̀?
Àwọn Kristian ọ̀rúndún kìíní nílò irú ojú ìríran tẹ̀mí yìí ní ti gidi. Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian wọn lábẹ́ ipò líle koko gan-an. Paulu sọ ọ́ báyìí pé: “A há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, ṣugbọn a kò há wa rékọjá yíyíra; ọkàn wa dàrú, ṣugbọn kì í ṣe [láìsí] ọ̀nà àbájáde rárá; a ṣe inúnibíni sí wa, ṣugbọn a kò fi wá sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́; a gbé wa ṣánlẹ̀, ṣugbọn a kò pa wá run.”—2 Korinti 4:8‚ 9.
Láìka àyíká ipò bẹ́ẹ̀ sí, àwọn olùṣòtítọ́, ọmọ ẹ̀yìn náà dúró gbọn-ingbọn-in. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ fífìdí múlẹ̀ nínú Ọlọrun, wọ́n lè sọ bí Paulu ti sọ pé: “Awa kò juwọ́sílẹ̀, ṣugbọn bí ẹni tí a jẹ́ ní òde bá tilẹ̀ ń joro lọ, dájúdájú ẹni tí awa jẹ́ ní inú ni a ń sọdọ̀tun lati ọjọ́ dé ọjọ́.” Ṣùgbọ́n kí ni ó fa ìsọdọ̀tun ojoojúmọ́ yìí? Paulu ń bá a lọ ní sísọ pé: “Nitori bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpọ́njú naa jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ tí ó sì fúyẹ́, fún awa ó ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ògo kan tí ó jẹ́ ti ìwọ̀n títayọ síwájú ati síwájú sí i tí ó sì jẹ́ àìnípẹ̀kun; nígbà tí awa kò tẹ ojú wa mọ́ awọn ohun tí a ǹ rí, bíkòṣe awọn ohun tí a kò rí. Nitori awọn ohun tí a ń rí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ṣugbọn awọn ohun tí a kò rí jẹ́ fún àìnípẹ̀kun.”—2 Korinti 4:16-18.
Paulu ń fún àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí ní ìṣírí láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀ràn ìṣòro, ìnira, àti inúnibíni—ìpọ́njú èyíkéyìí—dí ojú ìwòye wọn nípa èrè ológo tí a gbé síwájú wọn lọ́wọ́. Wọ́n ní láti wò ré kọjá àyíká ipò wọn ti lọ́ọ́lọ́ọ́, ní títẹ ojú wọn mọ́ àbájáde aláyọ̀ tí ipa ọ̀nà Kristian yóò mú wá. Èyí ni ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sọ ìpinnu wọn láti máa bá ìjà náà lọ dọ̀tun lójoojúmọ́. Àwọn Kristian lónìí bákan náà ní láti ní irú ojú ìríran dídára bẹ́ẹ̀.
Ka Àwọn Ìpọ́njú Ti Lọ́ọ́lọ́ọ́ Sí Ohun Ìgbà Díẹ̀!
Bí a fẹ́ bí a kọ̀, a ń rí àwọn ohun kan lójoojúmọ́ tí a kì yóò fẹ́ láti rí. Bí a bá wo jígí, ó dájú pé ohun tí a óò rí ni àwọn àléébù àti àbààwọ́n ti ara ìyára tí a kò fẹ́, tí ń tọ́ka sí àìpé nípa ti ara. Nígbà tí a bá tẹjú mọ́ jígí ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, a óò rí àwọn àléébù àti àbààwọ́n tẹ̀mí, nípa ara wa àti àwọn ẹlòmíràn. (Jakọbu 1:22-25) Nígbà tí a bá sì wo inú àwọn ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ tàbí tẹlifíṣọ̀n, ìròyìn àìṣèdájọ́ òdodo, ìwà ìkà, àti ọ̀ràn ìbànújẹ́ tí ń mú wa kẹ́dùn ni a óò mú wá sí àfiyèsí wa kíákíá.
Satani yóò fẹ́ kí a sọ̀rètí nù nítorí àwọn nǹkan tí a ń rí, tàbí kí a di ẹni tí a pa léte dà, kí ìgbàgbọ́ wa sì bẹ̀rẹ̀ sí í mì. Báwo ni a ṣe lè máà jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀? A gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jesu Kristi fi lélẹ̀, gẹ́gẹ́ bí aposteli Peteru ṣe dábàá nígbà tí ó sọ pé: “Níti tòótọ́, ìlà ipa-ọ̀nà yii ni a pè yín sí, nitori Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀lé awọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Peteru 2:21) Jesu ni àpẹẹrẹ pípé, nínú gbogbo apá ìgbésí ayé Kristian.
Nígbà tí ó ń tọ́ka sí Jesu gẹ́gẹ́ bí àwòkọ́ṣe fún wa, Peteru ní pàtàkì mẹ́nu kàn án pé, Jesu jìyà. Ní tòótọ́, Jesu jìyà lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé. Gẹ́gẹ́ bí “ọ̀gá oníṣẹ́” Jehofa, tí ó wà níbẹ̀ nígbà ìṣẹ̀dá aráyé, ó mọ ohun tí Ọlọrun pète fún ẹ̀dá ènìyàn ní pàtó. (Owe 8:30‚ 31, NW) Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ó rí ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti sọ wọ́n dà ní tààràtà. Lójoojúmọ́ ni ó ń rí àìpé àti àìlera àwọn ènìyàn, tí ó sì ní láti kojú rẹ̀. Ìyẹn ti gbọ́dọ̀ jẹ́ ìpèníjà fún un.—Matteu 9:36; Marku 6:34.
Yàtọ̀ sí ìpọ́njú àwọn ẹlòmíràn, Jesu rí tirẹ̀ pẹ̀lú. (Heberu 5:7‚ 8) Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ojú ìríran tẹ̀mí pípé, ó wò ré kọjá wọn láti rí èrè dídi ẹni tí a gbé ga sí ìwàláàyè àìleèkú nítorí ipa ọ̀nà ìwàtítọ́ rẹ̀. Nígbà náà gẹ́gẹ́ bíi Messia Ọba, yóò ní àǹfààní láti gbé ìran aráyé tí a ti pọ́n lójú ga kúrò nínú ipò ìdibàjẹ́ sí ìjẹ́pípé tí Jehofa pète láti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Títẹ̀ tí ó tẹjú mọ́ àwọn ìfojúsọ́nà ọjọ́ iwájú wọ̀nyí ràn án lọ́wọ́ láti di ayọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọrun mú láìka àwọn ìpọ́njú tí ó ń rí láti ọjọ́ dé ọjọ́ sí. Paulu kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Nitori ìdùnnú-ayọ̀ tí a gbéka iwájú rẹ̀ ó farada òpó igi oró, ó tẹ́ḿbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun.”—Heberu 12:2.
Jesu kò yọ̀ọ̀da kí àwọn àyíká ipò tí ó le koko tí ó sì ń dánni wò náà sún un láti sọ̀rètí nù, láti di ẹni tí a pa léte dà, tàbí láti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ mì. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ọ̀pá ìdiwọ̀n rẹ̀ gíga tímọ́tímọ́.—Matteu 16:24.
Tẹjú Mọ́ Àwọn Nǹkan Àìnípẹ̀kun Tí Kò Ṣeé Fojú Rí!
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó ran Jesu lọ́wọ́ láti fara dà, Paulu tún tọ́ka sí ipa ọ̀nà náà fún wa nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ẹ . . . jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré-ìje tí a gbéka iwájú wa, bí a ti ń fi tọkàntara wo Olórí Aṣojú ati Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, Jesu.” (Heberu 12:1‚ 2) Bẹ́ẹ̀ ni, láti tẹ̀ lé ipa ọ̀nà Kristian pẹ̀lú àṣeyọrí àti ayọ̀, a gbọ́dọ̀ wò ré kọjá àwọn nǹkan tí ó wà níwájú wa nísinsìnyí. Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe ń fi “tọkàntara wo” Jesu, kí sì ni yóò ṣe fún wa?
Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, ní 1914, a gbé Jesu gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọrun, ó sì ń ṣàkóso láti ọ̀run. Dájúdájú, gbogbo èyí ni a kò lè fi ojú ìyójú wa rí. Síbẹ̀, bí a bá fi “tọkàntara wo” Jesu, ojú ìríran wa nípa tẹ̀mí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé ó ti ṣe tán láti gbé ìgbésẹ̀ láti mú òpin dé bá ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí, kí ó sì gbé Satani àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ sínú ìdè àìlèṣiṣẹ́mọ́. Bí a bá tilẹ̀ wò síwájú sí i, agbára ìríran wa nípa tẹ̀mí yóò ṣí ayé tuntun àgbàyanu náà payá, nínú èyí tí “ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 19:11-16; 20:1-3; 21:4.
Nítorí náà, dípò dídi ẹni tí àwọn ìpọ́njú tí yóò wà fún ìgbà díẹ̀ tí à báà dojú kọ lójoojúmọ́ di ẹrù pa, èé ṣe tí a kò tẹjú wa mọ́ àwọn nǹkan tí yóò wà títí láé? Pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́, èé ṣe tí a kò wò ré kọjá àìsàn àti ìwọra tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé tí a ti bàjẹ́ yìí, láti lè rí paradise tí ó kún fún àwọn ènìyàn onílera, aláyọ̀, tí wọ́n sì bìkítà? Èé ṣe tí a kò wò ré kọjá àwọn àbàwọ́n ara wa, nípa tara àti nípa tẹ̀mí, kí a sì rí ara wa ní ẹni tí ó bọ́ lọ́wọ́ wọn títí ayérayé nípasẹ̀ àǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi? Èé ṣe tí o kò wò ré kọjá àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkú tí ogun, ìwà ipá àti ìwà ọ̀daràn fi sílẹ̀, kí o sì rí àwọn ẹni tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ jí dìde tí a ń dá lẹ́kọ̀ọ́ nínú àlàáfíà àti òdodo Jehofa?
Ní àfikún, láti fi “tọkàntara wo” Jesu yóò tún kan títẹ ojú ìríran wa nípa tẹ̀mí mọ́ ohun tí Ìjọba náà ti ṣàṣeparí rẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn Ọlọrun lórí ilẹ̀ ayé: ìṣọ̀kan, àlàáfíà, ìfẹ́, ìfẹ́ni ará, àti aásìkí nípa tẹ̀mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè fojú rí i. Kristian obìnrin kan ní Germany, lẹ́yìn tí ó wo fídíò náà, United by Divine Teaching, kọ̀wé pé: “Fídíò náà yóò ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa fi sọ́kàn pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin jákèjádò ayé ń ṣiṣẹ́ sin Jehofa pẹ̀lú ìdúróṣinṣin ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí—wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìka àtakò gbogbogbòò sí. Ẹ wo bí ìṣọ̀kan ará ti ṣeyebíye tó nínú ayé oníwà ipá àti oníkòórìíra!”
Ìwọ pẹ̀lú ha “rí” Jehofa, Jesu, àti àwọn áńgẹ́lì olùṣòtítọ́, àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ, tí wọ́n dúró sí ẹ̀gbẹ́ rẹ bí? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, o kò ní ṣàníyàn jù nípa “àníyàn ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan yii” tí ó lè mú ọ dúró gbagidi pẹ̀lú ìrẹ̀wẹ̀sì, kí ó sì mú kí o di “aláìléso” nínú iṣẹ́ ìsìn Kristian. (Matteu 13:22) Nítorí náà, fi “tọkàntara wo” Jesu nípa títẹ ojú tẹ̀mí rẹ mọ́ Ìjọba Ọlọrun tí a ti fìdí rẹ̀ kalẹ̀ àti àwọn ìbùkún rẹ̀, nísinsìnyí àti ní ọjọ́ iwájú.
Làkàkà Láti Jèrè Ìyè Ki O Baà Rí Ohun Tí O Kò Lè Rí Nísinsìnyí!
Ní wíwo ìyàtọ̀ gédégbé tí ó wà láàárín ayé tuntun ayérayé ti Ọlọrun àti ayé ògbólógbòó tí ń wó lọ lónìí, ó yẹ kí a sún wa láti hùwà ní ọ̀nà tí a óò fi kà wá yẹ láti wà láàyè láti rí, ní tààràtà, àwọn ohun tí a lè fi kìkì ojú ìgbàgbọ́ rí lónìí. Ògìdìgbó àwọn tí a jí dìde ni ẹnu yóò yà, nígbà tí wọ́n bá jí, tí wọ́n sì rí paradise ododo ilẹ̀ ayé tí ó yàtọ̀ gédégbé sí ayé tí wọ́n rí ṣáájú kí wọ́n tó kú. Finú wòye ayọ̀ wa nígbà tí a bá wà láàyè láti kí wọn, tí a sì ṣàlàyé ohun tí Ọlọrun ti ṣe fún wọn!—Fi wé Joeli 2:21-27.
Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ wo bí ojú ìríran dídára nípa tẹ̀mí ti ṣeyebíye tó, ẹ sì wo bí o ti ṣe pàtàkì tó láti jẹ́ kí ó mọ́lẹ̀ kedere! A lè ṣe èyí nípa ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé, lílọ sí àwọn ìpàdé Kristian, bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tí a gbé karí Bibeli, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, gbígbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá. Èyí yóò jẹ́ kí ìríran wa nípa tẹ̀mí ṣe ṣámúṣámú, kí ó sì mọ́lẹ̀ kedere, ní ríràn wá lọ́wọ́ láti wò kọjá ohun tí a lè rí!