Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Eto-ajọ ti Ó Wà Lẹhin Orukọ Naa
NI OCTOBER 6, 1990, awujọ eniyan ti o fẹrẹẹ tó 5,000 ti wọn pejọpọ sinu Gbọngan Apejọ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Jersey City, New Jersey, U.S.A., fun ipade ọdọọdun ti Watch Tower Bible and Tract Society maa tó rí ohun iyalẹnu kan laipẹ. Alaga, John E. Barr, sọ fun awujọ naa nipa imujade fidio oniṣẹẹju 55 kan ti àkọlé rẹ̀ jẹ́ Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name [Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa—Eto-ajọ ti Ó Wà Lẹhin Orukọ Naa]. Eyi ni fidio akọkọ ti Society tii ṣe jade rí, o si daju pe kò níí jẹ́ ikẹhin.
Fidio naa fihàn bi a ṣe ṣeto awọn eniyan Jehofa lati jẹrii si orukọ atọrunwa naa ki wọn sì pokiki “ihinrere ijọba naa.” (Matteu 24:14) Orile-iṣẹ ni Brooklyn, New York, ati awọn ohun-eelo ni Oko Watchtower ni a pe afiyesi si. Iye ti o ju 500,000 ẹ̀dà ní èdè Gẹẹsi ni a ti ṣe jade, ó sì wà larọọwọto ni bayii (tabi pe o maa tó wà) ni èdè 26 miiran.a
Ki Ni Idahunpada naa Ti Jẹ́?
Bawo ni awọn eniyan ti wọn kìí ṣe Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe dahunpada si fidio naa? Ọkunrin oniṣowo kan kọwe pe:
“Mo ri teepu naa gẹgẹ bi eyi ti iniyelori rẹ̀ tayọ. Ìmọ́rekete ati akojọ awọn aworan rẹ̀ ti a ṣe lọna ìmọṣẹ́dunjú wú mi lori ni pataki. Mo ni ìtẹ̀sí naa lati gbagbe pe o jẹ́ teepu ti mo sì ń ronu nipa rẹ̀ siwaju sii bi aworan sinima kan. Teepu yii gbọdọ wulo lọna ara-ọtọ ni ṣiṣalaye ète orile-iṣẹ yin ni New York. Mo ba yin yọ̀ fun imujade ti o dara gan-an yii.”—J. J.
Awọn ti wọn ń kẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti janfaani nipa wíwo fidio naa. Awọn ọ̀rọ̀ ti ó tẹle e yii ṣalaye idi rẹ̀:
“Mo ń kẹkọọ Bibeli pẹlu ọdọmọkunrin kan ti o jẹ́ ẹni 20 ọdun ti o sì ń lọ si ile-ẹkọ yunifasiti adugbo. Oun ti ń ṣaniyan nipa ipo ayé ti ń buru sii. Ṣugbọn lẹhin ìgbà ti o wo teepu naa ti o sì rí gbogbo awọn ọ̀dọ́ Beteli daradara wọnyẹn pẹlu ète gidi kan ninu igbesi-aye, ihuwasi rẹ̀ lapapọ ti yipada. Ó wá si Ọjọ Apejọpọ Akanṣe wa ó sì beere fun kikẹkọọ Bibeli ni ẹẹmeji lọ́sẹ̀. Akẹkọọ Bibeli miiran, olukọ kan ni ile-ẹkọ giga, yá fidio naa lati fi han awọn ibatan rẹ̀. Wọn lérò pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wulẹ jẹ́ eto-ajọ kekere, alaigbajumọ kan, ti kò kúnjú ìwọ̀n ni. Wíwà ti iṣẹ wa wà jakejado ayé ati aṣeyọri ti a ń ní yà wọn lẹnu gidigidi, ọpẹ́ ni fun Jehofa.”—J. B.
“Ọ̀rọ̀ kò lè ṣalaye ayọ ti mo ni nigba ti obinrin kan ti mo ń bá kẹkọọ Bibeli bú si ẹkún ayọ ati imọriri lẹhin ti o wo fidio yii. Ó fi omije sọ pe: ‘Bawo ni ẹnikẹni kò ṣe lè rii pe eyi ni eto-ajọ Ọlọrun tootọ naa, Jehofa? Emi kò mọ̀ rí pe iru awọn eniyan bawọnyi wà.’ Ó sì wa sọ lẹhin naa pe: ‘Mo fẹ́ lati ṣe iribọmi.’”—C. D.
“Awa ti ni ọpọ aṣeyọri ni lilo fidio naa pẹlu awọn akẹkọọ Bibeli. Ni alẹ́ àná ọkọ ọ̀kan lara awọn akẹkọọ Bibeli iyawo mi ṣebẹwo sile wa. Oun ti jẹ́ alatako gan-an. Ó wo fidio naa. Lẹhin naa o beere awọn ibeere ó sì fi ibí silẹ pẹlu Bibeli kan ati iwe ikẹkọọ Bibeli naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Ṣaaju akoko yii ó ti sun gbogbo awọn iwe ikẹkọọ Bibeli iyawo rẹ̀!”—D. H.
Awọn ọ̀dọ́ pẹlu ti ri fidio naa gẹgẹ bi eyi ti ń gba ọkàn-ìfẹ́, gẹgẹ bi awọn ọ̀rọ̀ ti o tẹle e wọnyi ti fihàn:
“Mo jẹ́ ọmọ ọdun mẹfa ati aabọ. Mo fẹran apa ibi ti o niiṣe pẹlu awọn Bibeli ati nigba ti awọn paali naa ń yára lọ kánmọ́-kánmọ́-kánmọ́.”—K. W.
“Awọn ọmọ wa kekere sọ pe o dara ju itolẹsẹẹsẹ eyikeyii ti wọn tii rí lori tẹlifiṣọn lọ.”—R. C.
“Lẹhin wiwo fidio naa fun ìgbà keji, ọmọkunrin wa ọlọdun marun-un, ẹni ti o fiyesi i daradara jalẹjalẹ, beere pe, ‘Ǹjẹ́ a lè maa wo eyi ni ojoojumọ bi?’ Ọmọbinrin wa ọlọdun mẹta sọ pẹlu rẹ̀ pe, ‘Mo fẹ lọ si Beteli ki n sì ṣe awọn iwe!’”—M. E.
“Awọn ọmọ mi, Robin ati Shannan, ti ọjọ-ori wọn jẹ́ 12 ati 9, ń gbé teepu yii sii ṣáá ni lati ìgbà dé ìgbà. Ọmọbinrin mi ti o kere ju lẹhin ti o ti wo teepu naa wi pe, ‘Mo fẹran jijade lọ sinu isẹ-isin pápá. Ó jẹ ohun amoriya gan-an ni.’ A nimọlara pe fidio yii ti ni ipa taarata kan lori igbesi-aye idile wa. Ẹ wo bi o ti ń tunilara tó lati ṣi itolẹsẹẹsẹ ori telifiṣọn kan ti oluwarẹ nimọlara aabo lati wò!”—N. B.
“Mo jẹ́ ọmọ ọdun 131/2. Fidio titun naa mu mi mọ bi mo ti fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mu awọn ipese agbayanu lati ọ̀dọ̀ Jehofa tó. O jẹ anfaani lati jẹ́ ọ̀kan lara awọn eniyan Ọlọrun.”—K. W.
“Mo jẹ́ ọmọ ọdun 16, fidio yii sì ti ṣeranwọ lati tẹ̀ ẹ́ mọ mi lọkan ṣinṣin pe iṣẹ́ kan ti a ń ṣe jakejado-aye ni eyi jẹ́.”—A. M.
“Awọn ọmọ wa sọrọ akiyesi pe awọn itolẹsẹẹsẹ deedee ti ori tẹlifiṣọn ti di ohun ti kò fi bẹẹ fa awọn mọra mọ́ gẹgẹ bi abajade rírí bi ohun idanilaraya ti iṣakoso atọrunwa gidi ṣe lè jẹ. O tun ti fun ìfẹ́-ọkàn wọn lokun lati kowọnu iṣẹ-isin alakooko kikun.”—L. M.
Àní awọn ti wọn ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa fun ọpọ ọdun paapaa ni ohun ti wọn rí ti wú lori.
“Bi fidio naa bá ní iru ipa alagbara bẹẹ lori wa gẹgẹ bi eniyan Jehofa, meloo meloo ni yoo ti nipa lori awọn ẹlomiran tó? Nigba ti eto-igbekalẹ yii bá dabi eyi ti o lekoko ju lati koju, emi yoo lo wakati kan ninu akoko mi lati ṣebẹwo si Beteli ninu idẹra iyàrá mi!”—K. B.
“Lẹhin ti mo ti ri iṣọra ati ìṣewẹ́kú ti a lò ninu gbogbo abala iṣẹ́ kọọkan, mo nimọlara bi ẹni pe ki ń lọ sinu iyàrá mi ki n sì dìmọ́ awọn iwe ikẹkọọ Bibeli mi.”—L. P.
A rọ ẹyin naa, pẹlu, lati lo akoko lati wo fidio naa Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name. Yoo fun yin ni oju-iwoye ti o yatọ nipa igbesi-aye yoo sì ràn yin lọwọ lati ní igbẹkẹle ninu ọjọ-ọla alaabo kan.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Èdè alápèjúwe ti America, Arabic, Basque, Cantonese, Catalan, Croatian, Czech (Bohemian), Danish, Dutch, Finnish, French, German, Greek, Hungarian, Italian, Japanese, Korean, Mandarin, Norwegian, Polish, Portuguese (Brazil), Portuguese (Europe), Romanian, Slovak, Spanish, Swedish.