ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/96 ojú ìwé 1
  • Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìgbàgbọ́—Ànímọ́ Tó Ń Sọni Di Alágbára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • ‘Ẹ Dúró Gbọn-in Nínú Ìgbàgbọ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 9/96 ojú ìwé 1

Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́

1 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ń kó àfiyèsí wọn jọ sórí àwọn ohun ìní wọn ti ara, ní fífi ìwà òmùgọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé agbára ìtannijẹ tí ọrọ̀ ní. (Mat. 13:22) Ojú wọn á wá dá wáí nígbà tí wọ́n bá pàdánù ọrọ̀ wọn, tàbí nígbà tí a bá jí wọn kó tàbí nígbà tí wọn kò bá fi bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní. A rọ̀ wá láti lépa ipa ọ̀nà tí ó túbọ̀ fi ọgbọ́n hàn, ní sísakun láti ní àwọn ìṣúra tẹ̀mí. (Mat. 6:19, 20) Èyí ní ‘rírìn nípa ìgbàgbọ́’ nínú.—2 Kọr. 5:7.

2 Ọ̀rọ̀ náà, “ìgbàgbọ́” ni a túmọ̀ láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tí ó gbé èrò ìgbọ́kànlé, ìgbẹ́kẹ̀lé, èrò ìgbàgbọ́ dídánilójú hán-únhán-ún yọ. Láti rìn nípa ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí láti dojú kọ àwọn ipò tí ó ṣòro pẹ̀lú ìgbọ́kànlé nínú Ọlọ́run, ní níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú agbára rẹ̀ láti darí àwọn ìgbésẹ̀ wa àti nínú ìmúratán rẹ̀ láti bójú tó àwọn àìní wa. Jésù fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀; ó kó àfiyèsí jọ sórí àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì ní tòótọ́. (Heb. 12:2) Bákan náà, a ní láti pa ọkàn wa pọ̀ sórí àwọn ohun tẹ̀mí, tí a kò lè rí. (2 Kọr. 4:18) A gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo pé ìwàláàyè wa ìsinsìnyí jẹ́ aláìdánilójú, kí a sì mọ̀ pé a ní láti gbára lé Jèhófà pátápátá.

3 A tún gbọ́dọ̀ ní èrò ìgbàgbọ́ dídánilójú hán-únhán-ún pé Jèhófà ń darí wa nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ tí a lè fojú rí, lábẹ́ ìdarí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú.” (Mat. 24:45-47) A ń fi ìgbàgbọ́ wa hàn nígbà tí a bá “jẹ́ onígbọràn sí àwọn wọnnì tí ń mú ipò iwájú” nínú ìjọ. (Heb. 13:17) Rírìn ní ìrẹ̀lẹ̀ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ètò ìṣàkóso Ọlọ́run ń fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà hàn. (1 Pet. 5:6) Ó yẹ kí a sún wa láti fi gbogbo ọkàn ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tí a fún ètò àjọ náà láti ṣe. Èyí yóò mú wa sún mọ́ àwọn ará wa pẹ́kípẹ́kí, nínú ìdè ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan lílágbára.—1 Kọr. 1:10.

4 Bí A Ṣe Lè Fún Ìgbàgbọ́ Lókun: A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa dúró sójú kan gbagidi. A gbọ́dọ̀ jà fitafita láti mú un pọ̀ sí i. Ṣíṣe déédéé nínú ìkẹ́kọ̀ọ́, àdúrà, àti lílọ sí ìpàdé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fún ìgbàgbọ́ wa lókun, tí ó fi jẹ́ pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, yóò lè kojú ìdánwò èyíkéyìí. (Efe. 6:16) O ha ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ déédéé fún Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ àti mímúra àwọn ìpàdé sílẹ̀ bí? O ha máa ń fi ìgbà gbogbo ṣàṣàrò lórí ohun tí o kọ́ bí, o ha sì ń tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà bí? Ó ha jẹ́ àṣà rẹ láti lọ sí gbogbo ìpàdé, kí o sì kópa nínú wọn bí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀ bí?—Heb. 10:23-25.

5 Àwọn iṣẹ́ rere ń fẹ̀rí ìgbàgbọ́ lílágbára hàn. (Jak. 2:26) Pípolongo ìrètí wa fún àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti fi ìgbàgbọ́ wa hàn. O ha máa ń wá àǹfààní láti ṣàjọpín ìhìn rere náà bí? O ha lè yí àwọn àyíká ipò rẹ padà kí o baà lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ bí? O ha máa ń lo àwọn ìdámọ̀ràn tí a ń rí gbà láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa túbọ̀ níye lórí, kí ó sì gbéṣẹ́ sí i bí? O ha ń gbé àwọn góńgó ti ara ẹni nípa tẹ̀mí kalẹ̀, tí o sì ń lo ara rẹ tokunratokunra láti lé wọn bá bí?

6 Jésù kìlọ̀ nípa fífi àṣejù kó wọnú àwọn àlámọ̀rí ìgbésí ayé ojoojúmọ́ àti jíjẹ́ kí ọkàn-ìfẹ́ fún ọrọ̀ àlùmọ́nì tàbí ọkàn-ìfẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan mú kí ojú ìwòye wa nípa tẹ̀mí di bàìbàì. (Luk. 21:34-36) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ bí a ti ń rìn gidigidi, kí a baà lè yẹra fún rírì ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa. (Efe. 5:15; 1 Tim. 1:19) Gbogbo wa retí pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a óò lè polongo pé ‘a ti ja ìjà àtàtà náà, a ti sáré ìlà ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, a sì ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.’—2 Tim. 4:7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́