Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Àkíyèsí: Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, a ó ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan nígbà àpéjọ àgbègbè. Kí àwọn ìjọ ṣe àyípadà tó bá yẹ láti fàyè sílẹ̀ fún lílọ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀.” Níbi tó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, kẹ́ ẹ lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tẹ́ ẹ máa ṣe kẹ́yìn kẹ́ ẹ tó lọ sí àpéjọ náà láti tún sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìmọ̀ràn àti ìránnilétí tó kan ìjọ yín nínú àkìbọnú ti oṣù yìí. Lẹ́yìn oṣù kan tàbí méjì tẹ́ ẹ bá ti ṣe àpéjọ àgbègbè yín, kẹ́ ẹ ya ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún ìṣẹ́jú sọ́tọ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn (ẹ sì lè lo apá tó jẹ́ ti àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ) láti fi ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì inú àpéjọ náà. Èyí kì í ṣe àtúnyẹ̀wò gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o tẹnu mọ́ èyí tó sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ní tààràtà. Ní káwọn ará sọ ọ̀nà tí wọ́n ti gbà lo àwọn ìsọfúnni náà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 11
Orin 20
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù September sílẹ̀. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Gba gbogbo àwùjọ níyànjú láti wo fídíò tó sọ nípa báwọn ọ̀dọ́ ṣe lè lọ́rẹ̀ẹ́ gidi, ìyẹn Young People Ask—How Can I Make Real Friends? kí wọ́n lè múra sílẹ̀ fún ìjíròrò tó máa wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ September 25. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ September 15 àti Jí! July-September. Nínú ọ̀kan lára àṣefihàn náà, fi hàn báwọn ara ṣe lè fún ẹni tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn lésì, tó wá sọ pé “Mo ní ìsìn tèmi.”—Wo Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 10.
20 min: Jàǹfààní Látinú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, èyí tó bẹ̀rẹ̀ láti ibi àkọlé kékeré tó wà lójú ìwé 65 sí ojú ìwé 69.
15 min: “Àtúnṣe Lórí Ìlànà Tó Wà fún Lílo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún Ṣíṣe Ìgbéyàwó ní Nàìjíríà.”a Ìpínrọ̀ 1 sí 7. Ka gbogbo ìpínrọ̀. Ní kí arákùnrin tó lè kàwé dáadáa múra sílẹ̀ láti ka àwọn ìpínrọ̀ náà.
Orin 126 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 18
Orin 213
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
10 min: “Àtúnṣe Lórí Ìlànà Tó Wà fún Lílo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún Ṣíṣe Ìgbéyàwó ní Nàìjíríà.”b Ìpínrọ̀ 8 sí 11. Ka gbogbo ìpínrọ̀. Ní kí arákùnrin tó lè kàwé dáadáa múra sílẹ̀ láti ka àwọn ìpínrọ̀ náà.
30 min: “Máa Fojú Sọ́nà fún Jèhófà”c Akọ̀wé ìjọ ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ní kí ìjọ yín lọ. Ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí bí wíwọ báàjì àpéjọ ṣe lè jẹ́ kó rọrùn fún wa láti wàásù ní gbogbo ìgbà tá a bá wà ní ìlú tá a ti ń ṣe àpéjọ. Gba àwùjọ níyànjú láti lo àǹfààní yẹn láti wàásù láìjẹ́-bí-àṣà fún gbogbo ẹni tí wọ́n bá rí, kí wọ́n sì rántí lo fọ́ọ̀mù tó ń rán wa létí láti padà lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tá a bá wàásù fún, ìyẹn Please Follow Up (S-43) láti ròyìn àwọn tó bá fẹ́ mọ̀ sí i tí wọ́n bá bá pàdé.
Orin 191 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 25
Orin 94
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù September sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ October 1 àti Jí! July-September nígbà tá a bá wà lẹ́nu ìwàásù òpópónà.
25 min: “Fídíò Tó Yẹ Kéèyàn Ronú Lé Lórí Dáadáa.”d Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 1, ní kí ìjọ sọ èrò wọn ní ṣókí nípa fídíò tó sọ nípa báwọn ọ̀dọ́ ṣe lè lọ́rẹ̀ẹ́ gidi, ìyẹn Young People Ask—How Can I Make Real Friends? Lẹ́yìn náà kó o wá bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò àwọn ìbéèrè tó wà fún ìpínrọ̀ 2 sí 7 níkọ̀ọ̀kan. Níparí, gba àwọn ìdílé níyànjú pé kí wọ́n máà jẹ́ kó pẹ́ tí wọ́n á tún fi jùmọ̀ wo àwo fídíò tó sọ̀rọ̀ nípa báwọn ọ̀dọ́ ṣe lè lo ìgbésí ayé wọn, ìyẹn Young People Ask—What Will I Do With My Life?
10 min: Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí lẹ́tà tó wà lójú ìwé àkọ́kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí.
Orin 183 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 2
Orin 36
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ̀rọ̀ lórí Àpótí Ìbéèrè.
15 min: “Lo Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa Lọ́nà Tó Bọ́gbọ́n Mu.”e
20 min: “Iṣẹ́ Ìwàásù Láti Ilé dé Ilé.”f Bí àkókò bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
Orin 127 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
f Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.