Bá A Ṣe Lè Jẹ́rìí Nípa Lílo Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Pàtẹ Àwọn Ìwé Wa
Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé lílo àwọn ohun tó ṣeé tì kiri tàbí tábìlì láti pàtẹ àwọn ìwé wa jẹ́ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ gan-an láti jẹ́rìí, torí pé ó ń mú kí àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Jòh. 6:44) Torí náà, a gba àwọn alàgbà níyànjú láti ṣètò iṣẹ́ ìwàásù ní àwọn ibi tí èrò pọ̀ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wọn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ohun tá a fi ń pàtẹ àwọn ìwé wa yìí ṣeé tì kiri, kì í sábà pọn dandan pé ká lọ tọrọ àyè lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ. Àwọn wo ló kúnjú ìwọ̀n láti kópa? Àwọn akéde tó ní ìjìnlẹ̀ òye, tí ìmúra wọn máa ń buyì kúnni àtàwọn akéde tó mọ bí èèyàn ṣe ń fọ̀rọ̀wérọ̀ dáadáa. Àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí á ran àwọn tó bá máa lọ́wọ́ nínú irú ìjẹ́rìí yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ ṣàṣeyọrí.