Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 22
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 22
Orin 22 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 12 ìpínrọ̀ 8 sí 13 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìṣe 22-25 (10 min.)
No. 1: Ìṣe 22:17-30 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Bá A Tiẹ̀ Ń Gbé Nínú Ayé, A Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé—Jòh. 17:15, 16 (5 min.)
No. 3: Ogun Amágẹ́dọ́nì Ni Ọlọ́run Máa Lò Láti Fòpin sí Ìwà Burúkú—td 4A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ka Lúùkù 5:27-32. Kẹ́ ẹ sì jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè wúlò fún wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
20 min: “Ọ̀nà Tuntun Tá A Fẹ́ Máa Gbà Wàásù Láwọn Ibi Tí Èrò Pọ̀ Sí.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ ètò tí ìjọ ṣe nípa bẹ́ ẹ ṣe fẹ́ máa wàásù níbi tí èrò pọ̀ sí àti bẹ́ ẹ ṣe máa lo tábìlì àtàwọn ohun tó ṣeé gbé kiri tẹ́ ẹ lè to ìwé sí lẹ́nu iṣẹ́ náà. Sọ ìrírí tó wúni lórí nípa iṣẹ́ náà.
Orin 95 àti Àdúrà