“Ẹ Lè Fún Un Ní Àwọn Ìwé Ìròyìn Tí Ọjọ́ Wọn Ti Pẹ́ Tàbí Ìwé Pẹlẹbẹ Èyíkéyìí Tó Sọ̀rọ̀ Nípa Ohun Tí Onílé Nífẹ̀ẹ́ Sí”
Ní àwọn oṣù tá a bá ń lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, tá a sì ń sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́, bí ẹni tá à ń wàásù fún bá ti ní ìwé náà, tí kò sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a fún wa ní ìṣírí pé ká “fún un ní àwọn ìwé ìròyìn tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tàbí ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí onílé nífẹ̀ẹ́ sí.” Kí nìdí?
Àwọn ìwé pẹlẹbẹ àti àwọn ìwé ìròyìn tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ sọ̀rọ̀ nípa onírúurú kókó ẹ̀kọ́ tó bọ́ sákòókò. Ohun kan nínú ìwé náà lè wọ onílé náà lọ́kàn. Torí náà, nígbà tó o bá ń to báàgì tó o máa gbé lọ sóde ẹ̀rí, mú mélòó kan lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ àtàwọn ìwé míì tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ dá ní. Tí o kò bá ní ìwé ìròyìn tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́, o lè gba mélòó kan níbi tẹ́ ẹ ti ń gba ìwé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí onílé bá ti wá ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tí kò sì gbà láti lẹ́kọ̀ọ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o lè fi díẹ̀ lára àwọn ìwé ìròyìn tàbí ìwé pẹlẹbẹ tó o ní lọ́wọ́ hàn án, kó o sì jẹ́ kó mú èyí tó nífẹ̀ẹ́ sí. Kó o wá ṣètò láti pa dà lọ mú kí ìfẹ́ rẹ̀ pọ̀ sí i. Ó sì ṣeé ṣe kó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbẹ̀yìngbẹ́yín.