Máa Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Tó Ti Pẹ́
Àwọn ìwé ìròyìn tó ti pẹ kò lè ṣe ẹnikẹ́ni láǹfààní tó bá jẹ́ pé ṣe la kàn kó wọn pa mọ́ tàbí tá a kàn dà wọ́n nù, torí náà ó yẹ ká sapá láti fún àwọn èèyàn. Ìwé ìròyìn kan péré ti tó láti mú kẹ́nì kan nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́, ó sì lè mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Jèhófà. (Róòmù 10:13, 14) Àwọn àbá kan rèé nípa àwọn ọ̀nà tó dára tá a lè gbà lo àwọn ìwé ìròyìn tó ti pẹ́.
Nígbà tẹ́ ẹ bá ń wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tẹ́ ò kì í ṣe déédéé, ẹ lè fi ìwé ìròyìn kan há ibì kan tó pa mọ́ díẹ̀ tí onílé ti máa rí i tó bá dé.
Tẹ́ ẹ bá ń wáàsù níbi táwọn èèyàn pọ̀ sí, bóyá ní ibùdókọ̀ tàbí ilé epo, ẹ lè bi àwọn tó wà níbẹ̀ bóyá wọ́n á fẹ́ ka ìwé kan, ẹ fi àwọn ìwé ìròyìn tó ti pẹ́ mélòó kan hàn wọ́n, kí ẹ sì jẹ́ kí wọ́n mú èyí tí wọ́n bá fẹ́.
Tẹ́ ẹ bá lọ sí àwọn ilé ìtajà, ilé ìtọ́jú arúgbó, ilé ìwòsàn tàbí àwọn ibòmíì bẹ́ẹ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín, ẹ lè fi àwọn ìwé ìròyìn mélòó kan tó ti pẹ́ síbi tí àwọn àlejò máa ń jókòó sí. Ohun tó sábà máa ń dára ni pé kẹ́ ẹ gbàyè lọ́dọ̀ ọ̀gá wọn tó bá wà níbẹ̀. Tó o bá rí i pé àwọn ìwé ìròyin wa kan ti wà níbẹ̀, má wulẹ̀ fi ìwé ìròyìn míì síbẹ̀.
Tó o bá ń múra ìpadàbẹ̀wò tó o fẹ́ lọ ṣe sílẹ̀, ronú nípa ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó o fẹ́ lọ bẹ̀wò nífẹ̀ẹ́ sí. Ṣé ẹni náà ní ìdílé? Ṣé ó fẹ́ràn kó máa rìnrìn àjò? Ṣé ó fẹ́ràn láti máa bójú tó ọgbà ọ̀gbìn? Yẹ àwọn ìwé ìròyìn tó ti pẹ́ wò bóyá wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ tí onítọ̀hún lè fẹ́ kà, kó o sì fi hàn án tó o bá pa dà lọ síbẹ̀.
Tó o bá rí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù rẹ, tí o sì pa dà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ léraléra àmọ́ tí o kò bá a nílé, lọ́jọ́ tó o bá ti rí i fún un ní àwọn ìwé ìròyìn tí kò tíì rí gbà látìgbà tẹ́ ẹ ríra kẹ́yìn.