Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 31
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 31
Orin 105 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 5 ìpínrọ̀ 1 sí 8 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 1-6 (10 min.)
No. 1: Ẹ́kísódù 2:1-14 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìtàn Nípa Ọlọ́rọ̀ àti Lásárù Kì Í Ṣe Ẹ̀rí Pé Ìdálóró Ayérayé Wà—td 16D (5 min.)
No. 3: Jésù Kọ́ Wa Bí A Ó Ṣe Máa Gbàdúrà—lr orí 12 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: “Máa Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Tó Ti Pẹ́.” Ìjíròrò. Sọ àwọn ìwé tó ti pẹ́ tí ìjọ ṣì ní lọ́wọ́ táwọn ará lè lò lóde ẹ̀rí. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n fún àwọn èèyàn ní àwọn ìwé ìròyìn tó ti pẹ́. Kó o tó parí ọ̀rọ̀ rẹ, ní kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ ibi tí ìjọ pín ìwé ìkésíní síbi Ìrántí Ikú Kristi dé.
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù April. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, fún gbogbo àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n ka àwọn ìwé ìròyìn náà dáadáa, kí wọ́n sì fìtara kópa nínú fífi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Mátíù 28:20 àti 2 Tímótì 4:17. Ẹ jíròrò bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
Orin 135 àti Àdúrà