Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 24
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 24
Orin 104 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 4 ìpínrọ̀ 19 sí 23, àpótí tó wà lójú ìwé 45 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 47-50 (10 min.)
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 48:17–49:7 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Iná Ṣàpẹẹrẹ Ìparun Yán-án Yán-án—td 16B (5 min.)
No. 3: Ìrànlọ́wọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Áńgẹ́lì Ọlọ́run—lr orí 11 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Nehemáyà. Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí àpẹẹrẹ Nehemáyà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere.
10 min: Máa Fi Ìbéèrè Kọ́ni Lọ́nà Tó Wọni Lọ́kàn—Apá 1. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwéJàǹfààní, ojú ìwé 236, sí ojú ìwé 237, ìpínrọ̀ 2. Ó kéré tán, fi ọ̀kan lára àwọn kókó tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà ṣe àṣefihàn ṣókí kan.
10 min: Jèhófà Máa Ń Gbọ́ Ẹ̀bẹ̀ Àwọn Olódodo. (1 Pét. 3:12) Ìjíròrò tá a gbé ka Ìwé Ọdọọdún 2013, ojú ìwé 66, ìpínrọ̀ 1 sí 3; àti ojú ìwé 104 sí 105. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
Orin 6 àti Àdúrà