ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/11 ojú ìwé 7
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 8/11 ojú ìwé 7

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 29, 2011.

  1. Báwo ni inú rere onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ṣe “sàn ju ìyè”? (Sm. 63:3) [w01 10/15 ojú ìwé 15, ìpínrọ̀ 17]

  2. Kí ni Sáàmù 70 jẹ́ ká mọ̀ nípa Dáfídì? [w08 9/15 ojú ìwé 4, ìpínrọ̀ 4]

  3. Kí ni Sáàmù 75:5 kìlọ̀ nípa rẹ̀? [w06 7/15 ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 2]

  4. Ìgbà wo gan-an la lè retí pé kí Jèhófà gbọ́ àwọn àdúrà wa? (Sm. 79:9) [w06 7/15 ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 5]

  5. Kí ni “àwọn nǹkan àṣírí” tí Sáàmù 90:7, 8 sọ nípa rẹ̀? [w01 11/15 ojú ìwé 12 sí 13, ìpínrọ̀ 14 sí 16]

  6. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Sáàmù 92:12-15, ojúṣe pàtàkì wo làwọn àgbàlagbà ní nínú ìjọ? [w04 5/15 ojú ìwé 13 sí 14, ìpínrọ̀ 14 sí 18]

  7. Ṣé ọ̀rọ̀ tó wà ní Sáàmù 102:25-27 fi hàn pé ńṣe ni onísáàmù náà ń sọ pé ayé kò lè wà títí láé gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pinnu? (Jẹ́n. 1:28) [w08 4/1 ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 1]

  8. Ẹ̀kọ́ wo ni Sáàmù 106:7 kọ́ wa nípa jíjẹ́ olóye? [w95 9/1 ojú ìwé 19, ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 20, ìpínrọ̀ 2]

  9. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Sáàmù 110:1, 4, ìbúra wo ni Jèhófà ṣe fún Irú Ọmọ náà tàbí Mèsáyà, báwo sì ni èyí ṣe yọrí sí ìbùkún fún gbogbo aráyé? [cl ojú ìwé 194, ìpínrọ̀ 13]

  10. . Nígbà tí onísáàmù náà ṣàṣàrò lórí àǹfààní tó wà nínú sísin Ọlọ́run, kí ni èyí mú kó ṣe? (Sm. 116:12, 14) [w09 7/15 ojú ìwé 29, ìpínrọ̀ 4 sí 5]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́